Iya Rainbow: Olùtọ̀jú aláìsàn ni kó tó di òsèré

Oríṣun àwòrán, @mamarainbowofficial
Gbaju-gbaja oṣere tiata, Idowu Philips, ti gbogbo eniyan mọ si Mama Rainbow wa lati ilu Ijẹbu Ode, nipinlẹ Ogun.
Mama Rainbow lọ si ileewe alakọbẹrẹ ni ipinlẹ Ogun, lẹyin naa lo kẹkọ gboye ni ileewe ẹkọṣẹ awọn nọọsi. O si ṣiṣẹ nọọsi fun ogún ọdun.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1942 ni wọn bi Iya Rainbow.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
A gbọ pe lati igba ti Iya Rainbow ti n ṣiṣẹ nọọsi lo ti nifẹ si ere ori itage ṣiṣe, o si bẹrẹ rẹ diẹdiẹ ninu ẹgbẹ oṣere Oṣumare ti ọkọ rẹ, Ayanfẹmi Oroniyi Phillips da silẹ.
Ọdun 1984 si ni Ayanfẹmi, ti gbogbo eeyan mọ si ‘Baba Rainbow’ jade laye. Osere ori itage ni Baba Rainbow naa, ko to di olukọ ni fasiti Eko, UNILAG.
Ẹyin iku ọkọ rẹ, si ni Mama Rainbow bẹrẹ ere siṣe ni ẹkunrẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, @mamarainbowofficial
Orukọ rẹ 'Iya Rainbow' jẹyọ lati ara orukọ ẹgbẹ oṣere ọkọ rẹ, Oṣumare, eyi to tumọ si 'Rainbow' ni ede oyinbo.
Iya Rainbow ti kopa ninu ọpọlọpọ sinima lati igba to ti bẹrẹ si ni ṣere. Lara wọn ni ere:
- Apaadi
- Asọ funfun
- Ajẹ Mẹta
- Apadi
- Si gbogbo Obinrin
- Ọba Adegbọrọ
- Ẹni akọkọ
- Iyawo onise
- Asiri Ọla
- Ọmọ iya alakara
- Egun
- T'Oluwa lasẹ
- Ayọ ọjọkan
- Asẹ Ntedumare
















