Igangan Attacks: Sunday Igboho ní àwọn ọba ní gómìnà Makinde ló ní kí áwọn sálọ nígbà tí òun dé Ibarapa

Sunday

Ajijagbara ati ajafẹtọ ọmọ Yoruba atata, Oloye Sunday Igboho tun ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ nigba to ṣabẹwo si ilu Igangan lẹyin iṣẹlẹ ipaniyan to waye nibẹ laipẹ yii.

Nigba ti o n sọrọ ni aafin Onidio ilu Idio, Igboho beere lọwọ Kabiyesi lati fun oun ni iyọnda lati ṣe igbaradi fawọn ọdọ ki wọn le daabo bo ilu lọwọ awọn janduku agbebọn.

Igboho ṣeleri fun Ọba alaye naa pe iṣẹlẹ ipaniyan to waye laipẹ yii lagbegbe naa, ni yoo ikẹyin iru rẹ lagbegbe naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Nigba ti mo pada wa si Igangan fun igba keji, gbogbo awọn ọba wa lo sa lọ.

Wọn ni gomina lo paṣẹ fawọn pe ki awọn sa lọ, ṣugbọn asiko ti to bayii lati dira fawọn ọdọ ki wọn le maa daabo bo ilu titi ti alaafia yoo fi jọba.

Àkọlé fídíò, Igangan Attacks: Àkójọpọ̀ àbọ̀ BBC Yorùbá rèé nípa ìṣẹ̀lẹ̀ òfò ẹ̀mí àti dúkìá tó wáyé

Lẹyin ti a ṣẹgun Seriki Saliu tan, awọn Fulani ti a le kuro ni Igangan ati agbegbe rẹ ṣipo pada lọ si ilu Igbo Ora ati Eruwa, awọn eeyan si gba a laaye.

Lati ibẹ ni wọn ti gbimọ pọ lati kogun ja Igangan lẹẹkeji, eleyii ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

Njẹ o yẹ ki awọn eeyan ilu Igbo Ora ati Eruwa tun gba awọn Fulani ti a le kuro ni Igangan si aarin wọn?

O yẹ ki wọn le wọn danu tefe tefe nitori ẹbi ati ara yin wa laarin awọn eeyan Igangan ti wọn n pa ni ipa kupa.

Wọn pa Ọmọwe, Aborode, wọn ji olori ati ọmọba Igbo Ora lọ, bẹẹ kabiyesi ko tun sọrọ.

Àkọlé fídíò, Teachers retirement age and years of service: Ìrírí àwọn àgbà olùkọ́ ṣì wúlò fún àwa ọ̀dọ́

Awọn Fulani payan ni Igangan, ko si sọja to wa sibẹ, ṣugbọn nigba ti wọn gbọ pe mo n bọ, awọn sọja yabo ilu Igangan,'' Igboho ṣalaye.

Igboho ni awọn sọja wa ni ibode Igangan nigba tawọn Fulani lọ payan nibẹ, wọn ko si lọ sibẹ lati dawọn duro.

Ṣugbọn o ni nigba toun atawọn iṣọmọgbe lọ si Igangan, awọn sọja wa lati dawọn lọwọ kọ.

Amin iyasọtọ kan

Gbogbo ọ̀daràn ta lé ní Igangan, Eruwa àti Igboora ní wọn wà, kò sí ìfẹ́ ní Ibarapa - Sunday Igboho

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1

Ajijagbara fun ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho ti sọrọ lori ikọlu lemọ-lemọ to n waye ni agbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo.

Igboho ni aisi ifẹ ati isọkan laarin awọn ara abule ati awọn oriade to wa lagbegbe Ibarapa, lo mu ki awọn afurasi darandaran maa se aseyọri lati kọlu agbegbe naa loore koore.

Sunday Igboho woye bẹẹ lasiko abẹwo rẹ si aafin Onidio ti Idio, lasiko to lọ si agbegbe Ibarapa lọ wo ọsẹ tawọn afurasi darandaran se si ilu Igangan lọjọ Aiku.

Ninu fọnran aworan kan to bọ sori ayelujara nipa abẹwo Igboho si aafin Onidio naa, lo ti woye pe airin lọwọọwọ nii jẹ ọmọ ejo niya lọrọ awọn eeyan agbegbe Ibarapa, eyi to mu ki ogun naa ja wọn.

O fidi rẹ mulẹ pe abẹwo oun ti sisọ loju rẹ pe ati awọn ara abule, atawọn ọba to wa lawọn abule to n bẹ lagbegbe Ibarapa ni wọn n sa asala fun ẹmi wọn tori ikọlu awọn apaniyan yii.

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

"Mo gbadura pe eyi ni yoo jẹ opin iru isẹlẹ bayii nitori awọn afurasi darandaran yii lo anfaani pe a gba wọn sile ni, lati maa kọlu wa.

Bakan naa ni wọn ri pe ẹnu awọn ara abule atawọn ọba wa lagbegbe yii ko se ọkan, lo jẹ ki iku ita maa pa wọn, ti agbegbe naa si si silẹ fun ikọlu."

Igboho tun sisọ loju rẹ pe ọpọ awọn afurasi apaniyan darandaran ti wọn le kuro nilu Igangan, ni wọn fi ara pamọ silu Igboora ati Eruwa.

O fikun pe lati awọn agbegbe yii si ni awọn apaniyan yii ti n ko ara wọn jọ lati ya wọlu Igangan lati sisẹ ibi, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

"Ni ibẹrẹ pẹpẹ, n ko kọkọ fẹ da si laasigbo to n waye nilu Igangan nitori awọn oriade wọn nibẹ ko setan lati fọwọsowọpọ.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Amọ bi mo se lọ si agbegbe Ibarapa yii lọjọ Aje lo mu ki awọn osisẹ agbofinro tubọ se afikun aayan wọn nilu Igangan.

Wọn ro pe mo tun wa pada fẹ gbẹsan ikọlu ti awọn afurasi darandaran naa se lọjọ Aiku ni."

Sunday Igboho wa koro oju patapata si iwa ipaniyan ati biba dukia jẹ ti awọn onisẹ ibi naa se nilu Igangan.

Bakan naa lo ke si awọn oriade lagbegbe Ibarapa lati fun awọn ọdọ ni idanilẹkọ lori awọn ọna ti wọn fi le daabo awọn abule wọn, ti wọn yoo si maa fi oju sọri bii alakan.

Àkọlé fídíò, Funmi Aragbaiye: Ọlọ́run ní ohun táwọn olórí wa fẹ́ jẹ ni wọn ń wá