Igangan Attacks: Ohun márùn-ún tí àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ bá Makinde sọ rèé

Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti ni oun gba pe oun jẹbi ikọlu to waye ni ilu Igangan pẹlu ileri pe iru rẹ ko ni waye mọ.
Ero awọn eeyan kan ni pe gomina Makinde ti gba asise rẹ, ti wọn si n gbosuba fun.
Sugbọn inu awọn araalu kan, paapa awọn ọdọ Igangan ko dunnu si Gomina nitori awọn isẹlẹ kan to waye lasiko abẹwo rẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gbogbo ọ̀daràn ta lé ní Igangan, Eruwa àti Igboora ní wọn wà, kò sí ìfẹ́ ní Ibarapa - Sunday Igboho
- Ọ̀gbìn igbó kìí ṣe irúgbìn èṣù, ẹ pa èrò àtijọ́ tì, oríṣun ọrọ̀ ajé ni - Akeredolu
- Kò sí oúnjẹ fún gúúṣù Nàíjíríà mọ́ títí ìparí June àyàfi... Ẹgbẹ́ oníṣòwò oúnjẹ l‘Ariwa dúnkookò
- Èèmọ̀ dé! Àwọn ọkọ sálọ, agbébọn jí ọgọ́ta ìyàwó, ọmọ àtàwọn baálẹ̀ abúlé
- Wo ìlànà tuntun tó tẹ̀lé láti gba ‘Passport’ ní Nàíjíríà
- Èmi ní mo lẹ́bi ikọlù tó wáyé ní Igangan, irú rẹ̀ kò ní wáyé mọ́ - Seyi Makinde
- Sunday Igboho ṣàbẹ̀wò sí Igangan lẹ́yìn ìkọlù, àmọ́...
- Ọdẹ Asọ̀lúdẹ̀rọ́ àti OPC mórílé Igangan láti fòpin sí ìpànìyàn
Idi si ni wi pe, wọn ni Seyi Makinde ko farabalẹ gbọ ẹdun ọkan awọn lasiko abẹwo rẹ si ilu Igangan lẹyin ikọlu to mu ẹmi eeyan mọkanla lọ.
Lara awọn to ba BBC Yoruba sọrọ lori aidunnu wọn si Gomina ni Monsuru Aderoju, to jẹ ọmọ ilu ati awọn aṣoju ọdọ mii bi Oladiran Oladokun.
Monsuru ni tiẹ sọ pe lootọ ni inu awọn dun si pe Gomina wa lati wa ṣabẹwo sawọn ṣugbọn ko gbọ gbogbo ẹdun ọkan awọn.
Ninu nkan to sọ pe awọn fẹ ni ki gomina ṣe idasilẹ bareke ibudo ọmọ ologun eleyi ti ko ni si awọn ẹya Hausa nibẹ.
Bakan naa lo ni awọn fẹ ki Gomina fi agbara fun awọn ọdẹ fijilante ilu nipa ipese ohun ija lati fi koju awọn to n doju ija kọ wọn.
Ọrọ naa ko fi taratara yatọ si ti alakoso ẹgbẹ idagbasoke ilu Igangan, Igangan Development Advocates tii ṣe Oladiran Oladokun.
Oladiran sọ pe iyalẹnu lo jẹ fawọn pe lẹyin to sọrọ tiẹ tan, Gomina Makinde ko faaye silẹ kawọn tiẹ sọ ohun to n dun wọn lẹmi.
O ni ṣaaju asiko yii lawọn ti n ke gbajare pe awọn ti n gbọ fin fin fin pe awọn agbebọn fẹ ṣe ikọlu si Igangan.
''Ka ni pe ọna wa fun wa lati kan si Gomina ni, iru nkan to waye yii ki ba maa ṣẹlẹ.''
''Gomina jinna si wa paapa awa ọdọ, to ṣe pe awa la jẹ bi eti ọba nile ati loko''
Oladokun ṣalaye fun BBC pe, nigba ti Gomina ko duro gbọ ọrọ awọn, awọn yoo fi iwe apilẹkọ ransẹ soju opo Facebook rẹ, boya yoo le de etigbọ rẹ.
Awọn koko ọrọ pọ ninu iwe naa ṣugbọn diẹ to ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo fun BBC Yoruba ree:
- Ki ijọba fofin mu Seriki Fulani, Abdulkadri ati ọmọ rẹ Ibrahim nitori ileri ti wọn ṣe lati dana sun Igangan
- Ki ijọba pese iranwọ fawọn to farakasa ninu ikọlu ati awọn mọlẹbi to padanu eeyan ninu iṣẹlẹ naa
- Mimu imugbooro ba agọ ọlọpaa to wa ni Igangan lati le di olu ileeṣẹ ọlọpaa lagbegbe naa ti yoo si ni oṣiṣẹ to peye
- Ipese ẹkọ ọfẹ fawọn ọmọ ti obi wọn ba iṣẹlẹ naa lọ
- Ṣiṣẹ amuṣẹ ofin to tako kawọn awọn eeyan maa da ẹran kaakiri eyi to jẹ ọna kan gbogi tawọn darandaran fi n kogun ja awọn araalu
Oladokun tubọ kesi Gomina pe ko maṣe fọrọ falẹ lori lilo awọn ọdẹ ibilẹ ati ẹgbẹ fijilante lati koju awọn olubi.
O ṣalaye pe ko si ẹni ti o mọ tibu toro ayika Ibarapa bii awọn ọdẹ yii tori naa, ki wọn ṣatilẹyin fun wọn lati le doju ija kọ awọn to n kogun ja araalu.






















