Zamfara Abduction: Agbébọn jí ọ̀pọ̀ èèyàn gbé, tó fi mọ́ ọ̀gọ́ta obìnrin àtàwọn ọmọ wẹ́wẹ́

Awọn abule ti agbebọn sọ ina si

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Awọn gende agbebọn ti ya bo ijọba ibilẹ Ruwan Tofa nipinlẹ Zamfara, ti wọn si ji ọpọlapọ eeyan gbe nibẹ.

Ọpọ awọn eeyan ti wọn ji gbe yii lo jẹ obinrin ati ọmọ wẹwẹ ni ọpọ abule ti wọn ya bo lọjọ Isẹgun.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC, asoju-sofin kan lati ipinlẹ Zamfara sọ pe wọn ji awọn obinrin gbe ni abule Manawa.

O ni wsn pa eeyan mẹrin ni abule Malele ati Randa, ti wọn wa nijọba ibilẹ Maru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni asofin Shehu S. Fulani sọ fun BBC pe awọn agbebọn naa tun sọ ina si ọpọ abule.

O fikun pe se ni awọn ọkunrin juba ehoro nigba ti wọn foju gan ni awọn agbebọn naa, ti awọn janduku yii si ko awọn aya atawọn ọmọ wọn.

Àkọlé fídíò, Funmi Aragbaiye: Ọlọ́run ní ohun táwọn olórí wa fẹ́ jẹ ni wọn ń wá

Bi o tilẹ jẹ pe ko si ẹni to le sọ pato iye eeyan tawọn agbebọn naa mu nigbekun, amọ akọsilẹ fihan pe obinrin to to ọgọta ni wọn ko ri lawọn abule naa.

Iroyin naa fikun pe awọn agbebọn naa n yinbọn soke lakọ-lakọ nigba ti wọn de sibẹ, ti wsn si n sọ ina sawọn ile gbogbo.

Eyi lo mu ki ọpọ eeyan maa sa asala fun ẹmi wọn, amọ awọn obinrin ati ọmọde ti ko le sare daada ni ọwọ agbebọn ba.

Koda, ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ ni iyawo oun mẹrẹẹrin ni wọn ji gbe lọ ati awọn ọmọ, ọmọ rẹ, tii se ọmọ ọdun meje nikan ni wọn fi silẹ.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Koda, ọrọ ọhun ko yọ baalẹ awọn abule naa silẹ, to fi mọ awọn idile wọn.