Igangan Attacks: Ọdẹ Asọ̀lúdẹ̀rọ́ àti OPC ní ààbò Yorùbá di ojúṣe àwọn bí ààbò ìjọba ṣe kùnà,

Awọn ọdẹ ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Zenger

Yoruba ni ailasọ lọrun paaka, o to apero fun gbogbo ọmọ eriwo, iku to si n pa ojugba ẹni, owe nla lo n pa fun ni.

Awọn isẹlẹ isekupani to n waye lemọ lemọ lẹnu lọọlọ yii ti di irawọ ọsan, to n bawọn agba lẹrun bayii.

Laarin ọjọ mẹta, awọn agbebọn ti kọlu ilu Igangan nibiti ti ọpọ ẹmi ti bọ, ti dukia si bajẹ, bẹẹ naa ni wsn pa ọpọ eeyan ni agbegbe Imeko-Afọn nipinlẹ Ogun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ka ma sẹsẹ sọ awọn eeyan ti ọpọ adigunjale, ajinigbe atawọn afinise etutu ọla ti pa, ti awọn iwa ọdaran yii si n tẹsiwaju.

O si dabi ẹni pe apa awọn agbofinro ko fẹ ka awẹn apaniyan yii nitori wọn kii saba ri wọn mu lẹyin ọsẹ ti wọn ba se.

Àkọlé fídíò, Ayelala Idol: Onímọlẹ̀ ní olúwẹri obìnrin ni òrìṣà náà ló ṣe ń pọn omi sínú ẹlẹ́ṣẹ̀

Idi ree ti ọpọ eeyan fi n lọgun pe nibo ni awọn ọdẹ ibilẹ atawọn eeyan to n pese aabo fun ilẹ Yoruba wa lati pese eto aabo to peye fun wa?

Yoruba sa ni ki agbado to dele aye, nnkan sa ni adiẹ n jẹ, bi a ko ba si ri adan, a le fi oobẹ se ẹbọ.

Ọna lati wa idahun sawọn ibeere araalu yii lo mu BBC Yoruba kan sawọn ọdẹ ibilẹ, ẹgbẹ OPC, Agbekoya atawọn fijilante.

Ohun ta si bi wọn ni pe ki ni wọn n se lati pese eto aabo to gbopọn fun ilẹ Yoruba, ti yoo fi di aiwọ fun awsn ọdaran?

Yoruba sa ni a kii ni ọkọ nilẹ, ka tun maa fi ọwọ ko imi.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Ijọba ti sugba wa ati pese aabo to peye yika ilẹ Yoruba - Ẹgbẹ ọdẹ Asọludẹrọ

Nigba to n dahun ibeere yii, awọn ogboju ọdẹ asọludẹrọ ti sọ pe awọn ti ṣetan lati yanju gbogbo rogbodiyan iṣekupani to n waye lagbegbe Ibarapa ati to eto abo to mẹhẹ kaakiri ilẹ Yoruba.

Alaga ẹgbẹ Ọdẹ Asọludẹro, Alhaji Ajijola Anọbi lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba.

O ni ijọba ipinlẹ Oyo ti gba lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn lati lọ pẹtu si wahala naa, koda o ni irọlẹ oni gangan ni awọn n lọ ilu Igangan.

Ajijola Anobi ni "Ara oun ti a n ba ijọba sọ tẹlẹ naa niyẹn ti wọn ko fẹ gbọ, ṣugbọn bayii wọn ti mọ pataki pe ọdẹ lo ni inu igbo."

"Ọdẹ lo n sun ninu igbo, ọdẹ lo ni igbo, a maa n pade awọn anjọnu ati oriṣiri ẹranko ninu igbo ko si si nnkan ti wọn yoo fi wa ṣe."

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Alaga naa ṣalaye siwaju si pe "O soro lati ko ọlọpaa ti ko wọ inu igbo ri, lati wọ inu igbo, awa ọdẹ ni a mọ gbogbo kọrọkọndu inu igbo."

O fikun pe kii ṣe ilu Igangan nikan ni awọn yoo ti ṣiṣẹ lasiko yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ọdẹ asọludẹrọ ti ṣe ipade pẹlu awọn akẹgbẹ wọn kaakiri ilẹ Yoruba, awọn si ti ṣetan lati da alaafia pada si agbegbe Igangan ati gbogbo ilẹ Yoruba lapapọ.

Ni ti awọn irinṣẹ ti wọn yoo lo lati fi koju awọn ọdaran darandaran to n da alaafia ilẹ Yoruba laamu, Ajijola Anobi sọ pe yatọ si awọn nnkan abalayeti wọn n lo, ibọn ibilẹ naa wa lọwọ wọn, ibọn naa si tẹ awọn lọrun ju awọn ibọn nla nla ti awọn agbofinron ijọba n gbe kiri.

O pari ọrọ rẹ pe awọn ti ba ibọn atawọn nnkan ija miran to jẹ ti abalaye mulẹ, awọn si gbagbọ pe awọn yoo bori ija naa.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Aayan wa ni ko jẹ ki isẹlẹ Igangan ju bo se wa lọ - OPC

Ẹwẹ, BBC Yoruba kan si Sina Akinpelu to jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ OPC New Era, o ni awọn naa ti bẹrẹ eto lati yanju eto abo to mẹhẹ lagbegbe Ibarapa.

Gẹgẹ bi ohun to sọ fun BBC, nnkan ti wọn kọkọ n ṣe ni lati ṣe iwadii awọn to wa nidii iṣẹlẹ naa nitori o ṣeeṣe ki ejo lọwọ ninu.

Akinpelu fi kun pe, ajọṣepọ to dan mọran lo wa laarin awọn ati ẹgbẹ ọdẹ Asọludẹrọ, ikọ Amotekun atawọn ẹṣọ alaabo miran to jẹ ti ilẹ Yoruba.

O fi kun pe ifọwọsowọpọ to wa laarin awọn ẹgbẹ naa ni ko jẹ ki iṣẹlẹ to waye ni Igangan ju bo ṣe waye lọ.

Àkọlé fídíò, Magaret Jimoh: Èrè díẹ̀ ti tó mi níbi oúnjẹ ti mò ń tà- Maggie Rice

Bo tilẹ jẹ pe o ni awọn ijọba nilẹ Yoruba ko tii fọwọsowọopọ pẹlu awọn bo ṣe yẹ ko ri, ṣugbọn o ni igbagbọ awọn ni pe ijọba yoo kin awọn lẹyin laipẹ.

Akinpẹlu pari ọrọ rẹ pe, awọn ko ni gba ki awọn Fulani ko ilẹ Yoruba lẹru, bi wọn ṣe ko awọn ẹya kan lẹru lọpọ ọdun sẹyin.