Adebayo Muritala David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Àkọlé fídíò, Adebayo Murital David: Gbogbo iṣẹ́ tó ń múni là láyé wá láti ọpọlọ ni kìí ṣe agbára

Adebayo Muritala Akanbi David, ẹni to ni ipenija oju sugbọn to n fi ọpọlọ ati ọwọ rẹ dara Adirẹ to rẹwa pupọ.

African Child, Oba Mushin ati awọn orukọ miran ni ọpọ n pe Adebayo Muritala David to jẹ ẹni to ni ipenija oju lọdun 2012.

David

David ṣalaye fun BBC bi ọrọ oju naa ṣe bẹrẹ ko to wa gba ẹbọ lọwọ oun.

Bakan naa lo tun mẹnuba bi oun ṣe bẹrẹ iṣẹ ona Adire ṣiṣe, feere fifọn, ilu lilu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

David

Muritala David ni nitori pe eeyan ko riran ko sọ pe ko di alagbe.

Bẹẹ naa ni o sọ nipa bi o ṣe gbe igbesẹ akin lẹyin ti oju rẹ fọ to si gba Blind School lọ lai maa sunkun kiri.

David

African Child sọ nipa bi o ṣe n ṣe iṣẹ ọna rẹ.

wo awọn iṣẹ ona adire to jẹ oju ni gbese lati ọwọ ẹni to ni ipenija oju.

David

Muritala David gba awọn to ni ipenija ara nimọran pe atẹlẹwọ ẹni kii tan ẹni jẹ.

Ati pe ki onikaluku lo ẹbun ti Olorun fun un..

O sọ awọn ibi ti iṣẹ yii ti gbe e de ni Naijiria ati ni oke okun.

Muritala sọ nipa ile ẹkọ to ti da silẹ fun awọn mii to ni ipenija oju.

David

Bakan naa ni David so nipa ipenija ti awon akanda ẹda n ri lawujọ.

Olanikẹ Ajayi ati Olawumi Adeola ati awọn mii ti wọn ti di eeyan nipa iṣẹ ọna yii naa ba BBC sọrọ ni kikun.