Ibadan killing, Linus Onwuamana: Àwọn jàndùkú agbébọn yìnbọn pa ọkùnrin oníṣòwò kan nílùú Ibadan

Oríṣun àwòrán, other
Ọrọ eto abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria ti n burẹkẹ si, lẹyin tawọn janduku agbebọn tun ṣekupa ọkunrin oniṣowo kan niluu Ibadan.
L'ọjọ Aiku ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fi idi ọrọ naa mulẹ lori ipapoda Arakunrin Linus Owuamanam, oniṣowo ti awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko damọ yinbọn pa.
Iroyin sọ wi pe ni nnkan bi i aago mẹjọ alẹ ọjọ Abamẹta ni awọn olubi ẹda naa gbẹmi Onwuamana.
- Àwọn ọlọ́pàá rọ̀jò ìbọn lórí àwọn jàndùkú tó ṣekúpa Ahmed Gulak, wọ́n tún gba ìbọn wọn
- Ó ń rúgbó bọ̀ o! Àwọn ajìjàgbara Yorùbá Nation fipá ṣí bọ́dà Idiroko, àmọ́...
- Sunday Igboho bẹ̀bẹ̀ lórí ìkùnsínú tó ń wáyé nípa ìwọ́de l‘Ekiti
- Àwọn jàndùkú agbébọn ṣekúpa Ahmed Gulak, olùdàmọ́ràn Goodluck Jonathan
- Ọwọ́ EFCC tẹ ọmọ Yahoo tó fẹ́ ra ọkọ̀ SUV tí iye rẹ̀ tó 44 mílíọ́nù pẹ̀lú Bitcoin
- Kí ló bí ìsinmi tí àwọn ajìjàngbara Biafra kéde fáwọn Ibo láti ṣ'àyájọ́ Biafra
Oniṣowo naa ni wọn sọ wi pe o n wa ọkọ akẹru kan lọ lopopona Mọkọla si Sango nilu Ibadan lasiko ti o se kongẹ iku ojiji.
Lẹyin ti wọn yinbọn fun un tan, awọn agbebọn naa tun fi nnkan gun un ni aya lati riidaju ko ru ikọlu naa la.
Bẹẹ si ni ko si ẹnikẹni ti o mọ ibi ti ẹnikeji to n ba oloogbe rin irinajo lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ wa bayii.
Ẹni kan ti o n kọja lọ ti o si ri oloogbe naa ninu agbara ẹjẹ lo fi iṣẹlẹ naa to awọn oṣiṣẹ rẹ leti.
- Mọ̀ síi nípa Agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọniyàn ni Nàìjíríà tó lọ sí ẹ̀wọ̀n nígbà 32
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Greenfield tí wọ́n jí gbé ní Kaduna gba òmìnira lẹ́yìn tí àwọn òbí wọn san "180 mílíọ́nù naira"
- Èmi kò pe Arinola Oloko ní 'Thug' o, ìbéèrè ni mó bèèrè lọ́wọ́ ẹ- Remi Tinubu
- Ariwo ẹkún sọ lẹ́yìn tí wọ́n ṣàwárí òkú akẹ́kọ̀ọ́ 215 nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ yìí
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Ẹnu yóò ya àwọn alátakò lórí ǹkan tí mo ti gbé ṣe ní ìpínlẹ̀ Oyo










