Yoruba Nation: Sunday Igboho ní káwọn ajìjàgbara fọwọ́ wọ́nú, kí ọ̀tá máṣe yọ àwọn

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday_Igboho1/Instagram

Gbajugbaja ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti kede pe wọn ti sun iwọde fun idasilẹ Yoruba Nation nipinlẹ Ekiti wa sẹyin.

Ọjọ kejila osu Kefa, eyiun June 12 ni Sunday Igboho ati awọn ajijagbara miran to n polongo idasilẹ́ orilẹede Yoruba yẹ ko ya wọ Ado Ekiti fun iwọ̀de naa tẹlẹ, ko to di pe wọn sun siwaju.

Amọ ni bayii, ọjọ Satide, ọjọ Karun osu Kefa ni wọn yoo se iwọde naa, eyi to fi ọsẹ kan din si ọjọ to yẹ ki wọn se iwọde naa tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

Sunday Igboho, ẹni to kede isunsẹyin iwọde naa loju opo Facebook agbẹnusọ feto iroyin rẹ, Olayomi Koiki, salaye pe o nidi ti igbesẹ naa se waye.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: 'Ǹkan tÍ Sunday Igboho Ṣe ní Ibarapa tún ti ṣelẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun'

Igboho, ti wọn fi fọnran ohun rẹ ti wọn gba silẹ sita loju opo ikansiraẹni naa, wa rawọ ẹbẹ sawọn eeyan to n binu nitori ọjọ ti wọn yipada naa.

"Ohun to jẹ ka yi ọjọ naa pada si June 5 ni pe iwọde June 12 maa wa ti gbogbo wa maa ti lọ kopa, eyi ti yoo waye nilu Abeokuta.

Idi niyi ti mo fi ni ka ma mu June 12 nitori iwọde n bọ, to dẹ maa ni agbara gan, mo wa fi gbogbo awọn alalẹ bẹ yin kẹ dari jin mi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Emi ni mo yi ọjọ naa pada si June 5, ẹ ma binu sira wa, ẹ jẹ ka se ara wa lọkan, ori idọbal,ẹ ni mo wa, mo fi Ọlọrun bẹ yin, ka dijọ de ilẹ ileri.

Esu ko ni de si aarin wa, ẹ ma jẹ ki aye yọ wa pe awọn to fẹ gba orilẹede Yoruba, lo n ba ara wọn ja yẹn."

Àkọlé fídíò, Ifọrọwerọ pẹlu Gani Adams lori ọrọ Sunday Igboho

O ni igbesẹ naa lo wa lati pana iporuru ọkan to n su yọ nitori iwọde Ekiti, to si parọwa si awọn ajijagbara naa pe ki wọn se ara wọn ni ọkan.

Igboho fikun pe kii se eeyan kan lo n sisẹ ni ipinlẹ kọọkan, gbogbo wọn lo si se pataki.Ipinlẹ Ekiti kun fun awọn gbajumọ ati ọmọwe, ibẹ si ni Baba wa, Banji Akitoye ti wa.

O ni oun dupẹ pe awọn agbaagba tete pa ina rogbodiyan to fẹ suyọ nipa iwọde naa ni Ekiti, ti Ọlọrun si ti gba akoso ohun gbogbo.

Àkọlé fídíò, Kò sí ìgbà kankan tí Yorùbá jókòó pé ki Igboho lọ kéde ìyapa kúrò ní Nàíjíríà

Bakan naa lo ni ko si ẹnikẹni to n ba ara wọn ja, gbogbo wa la n sisẹ papọ fun aseyori iwọde ti yoo waye ni Ekiti lọjọ Karun osu Kẹfa ọdun 2021.