Ahmed Gulak: Ọlọ́pàá ti sọ̀rọ̀ ní kíkún lórí ikú Gulak tó jẹ́ eèkàn tó kúrò ní PDP lọ sí APC

Oríṣun àwòrán, Other
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti ṣalaye sii lori iku Gulak Ahmad to doloogbe lana ọjọ Aiku nipinlẹ Imo ni Ila oorun guusu Naijiria.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ni pe awọn Indigenous People of Biafra [IPOB] ati awọn Eastern Security Network [ESN] ni wọn ṣiṣẹ ibi naa.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Imo, Bala Elkana fi sita lo ti sọ ọrọ yii.

Oríṣun àwòrán, @NPF
Bala ni ọlọpaa ti pa eeyan mẹfa to ṣiṣẹ ibi naa ni Imo.
O tun ni awọn pa oniṣẹ ibi mẹrin miran ninu ikọlu to waye ni ijoba ibile Aboh-Mbaise nipinlẹ Imo.
- Wo àsìkò tí ìdíje "BBNaija lockdown reunion" yóò bẹ̀rẹ̀
- Amotekun yóò máa ṣọ́ ibodè àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá láti máwọn ọ̀daràn àti ajínigbé
- Ọjà olówó iyebíye jóná nínú ọjà Ladipo nílùú Eko
- Àwọn jàndùkú agbébọn yìnbọn pa ọkùnrin oníṣòwò kan nílùú Ibadan
- Èmi kò pe Arinola Oloko ní 'Thug' o, ìbéèrè ni mó bèèrè lọ́wọ́ ẹ- Remi Tinubu
Bala Elkana tun ṣalaye pe awọn oniṣẹ ibi naa n pin alubọsa ni awọn agbofinro pada wọn ti wọn si gbena woju ara wọn.
O ni awakọ Golak lo sọ bi wọn se rin lẹyin iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, @NPF
Awakọ naa ni oun n gbe Gulak lọ si papakọ ofurufu ni iṣẹlẹ naa waye ni orita Obiangwu ni ijoba ibilẹ Ngorokpala
wọn ti sin Oloogbe Gulak Ahmad nilan ẹsin Musulumi.
Àwọn ọlọ́pàá rọ̀jò ìbọn lórí àwọn jàndùkú tó ṣekúpa Ahmed Gulak, wọ́n tún gba ìbọn wọn
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti mú àwọn jàndùkú tó pa èèkàn ẹgbẹ́ APC
Kọmiṣọnna ọlọpaa Imo, CP Abutu Yaro gboṣuba rabandẹ fawọn ọlọpaa fun iṣẹ takun takun ti wọn ṣe lati ṣawari awọn asekupani naa.
O dabi ẹni pe idajọ kiakia lawọn janduku to ṣekupa Ahmed Gulak tii ṣe oluranlọwọ aarẹ ana orilẹ-ede Naijiria, Goodluck Jonathan gba lẹyin tawọn ọlọpaa ti ran awọn naa lọ si ọrun alakeji.

Oríṣun àwòrán, Gulak
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku pe awọn agbofinro ti ṣawari awọn agbebọn to pa Gulak loju ilu Owerri si Abuja.
Koda awọn ọlọpaa tun gba ibọ AK 47 mẹta, ibọn kekere kan ati ọta ibọn mejilelaadọrun lọwọ wọn.
- Ó ń rúgbó bọ̀ o! Àwọn ajìjàgbara Yorùbá Nation fipá ṣí bọ́dà Idiroko, àmọ́...
- Sunday Igboho bẹ̀bẹ̀ lórí ìkùnsínú tó ń wáyé nípa ìwọ́de l‘Ekiti
- Àwọn jàndùkú agbébọn ṣekúpa Ahmed Gulak, olùdàmọ́ràn Goodluck Jonathan
- Ọwọ́ EFCC tẹ ọmọ Yahoo tó fẹ́ ra ọkọ̀ SUV tí iye rẹ̀ tó 44 mílíọ́nù pẹ̀lú Bitcoin
- Ẹ̀mí àìrí lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jáde ni ilé ẹ̀kọ́ St Claire's ní Offa
- Mọ̀ síi nípa Agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọniyàn ni Nàìjíríà tó lọ sí ẹ̀wọ̀n nígbà 32
Bakan naa lawọn ọlọpaa tun gba awọn ọkọ ti wọn fi ṣiṣẹ ibi naa lọwọ wọn.
''Gẹgẹ bi dẹrẹba Gulak to n gbe lọ si papkọ ofurufu nigba ti wọn pa ṣe sọ, awọn agbebọn naa lo ọkọ Toyota Camry 2005, Toyota Sienna 1998, Toyota Hilux ati Lexus RX 330 lati ṣiṣẹ laabi wọn.
O tun sọ fun wa ọna ti awọn janduku ọhun gba lọ lẹyin ti wọn pa Gulak tan.
Gbogbo nkan ti a lo niyii lati wa wọn ri de ibi ti wọn wa gan an.
Orita Afor Enyiogugu ni ijọba ibilẹ Aboh-Mbaise ni a ti gba wọn mu, koda wọn n pin alubọsa lati inu ọkọ nla to n bọ lati oke Ọya fawọn eeyan ni a de bẹ.
Bi wọn ṣe ri wọn ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn mọ wa, ṣugbọn wọn ba awa ọlọpaa naa nile.
Awọn janduku mẹfẹẹfa to pa Gulak atawọn akẹgbẹ wọn mẹrin mii lo farapa yanayana,'' ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye.
Kọmiṣọnna ọlọpaa Imo, CP Abutu Yaro gboṣuba rabandẹ fawọn ọlọpaa fun iṣẹ takun takun ti wọn ṣe lati ṣawari awọn asekupani naa.
- Ọjà olówó iyebíye jóná nínú ọjà Ladipo nílùú Eko
- Kí ló bí ìsinmi tí àwọn ajìjàngbara Biafra kéde fáwọn Ibo láti ṣ'àyájọ́ Biafra
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Greenfield tí wọ́n jí gbé ní Kaduna gba òmìnira lẹ́yìn tí àwọn òbí wọn san "180 mílíọ́nù naira"
- Wo ìdí tó fi rọrùn fún Chelsea láti bu ìfọ́jú lu Manchester City lẹ́ẹ̀mẹẹ̀ta léra wọn
Awọn janduku agbebọn ti ṣekupa Ahmed Gulak tii ṣe oluranlọwọ aarẹ ana orilẹ-ede Naijiria, Goodluck Jonathan.
Ilu Owerri nipinlẹ Imo ni wọn ti sọ pe wọn yinbọn pa Gulak.
Gulak n rinrin ajo lati Abuja si Owerri lalẹ ọjọ Abamẹta ki o to ṣagbako iku ojiji lọna.
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Greenfield tí wọ́n jí gbé ní Kaduna gba òmìnira lẹ́yìn tí àwọn òbí wọn san "180 mílíọ́nù naira"
- Wo ìdí tó fi rọrùn fún Chelsea láti bu ìfọ́jú lu Manchester City lẹ́ẹ̀mẹẹ̀ta léra wọn
- Arúmọjẹ lásán ni lọkọ-láya tí èmi àti Cute Abiola jọ́ ń ṣe tẹ́lẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ti dé- Adeherself
- Èmi kò pe Arinola Oloko ní 'Thug' o, ìbéèrè ni mó bèèrè lọ́wọ́ ẹ- Remi Tinubu
- Ariwo ẹkún sọ lẹ́yìn tí wọ́n ṣàwárí òkú akẹ́kọ̀ọ́ 215 nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ yìí
- Bí Ààrẹ Buhari bá parí sáà rẹ̀ tán ni ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria yóò mọ rírì iṣẹ́ tó ń ṣe - Ìjọba àpapọ̀















