BBNaija season 6: Oṣù tó ń bọ̀ ni ìdíje "BBNaija lockdown reunion" yóò bẹ̀rẹ̀

BBNaija

Oríṣun àwòrán, @BBNaija

Ileeṣẹ Multichoice to n ṣe agbatẹru idije BBNaija ti kede pe idije naa yoo bẹrẹ ninu oṣu kẹfa ọdun yii.

Eto to kọkọ maa n ṣaju idije naa ti wọn n pe ni "BBNaija reunion" ni yoo waye ṣaaju.

Lori BBNaija ọhun ni awọn ololufẹ eto naa yoo ti ni anfaani lati dibo fun ẹni ti wọn fẹran lati jaweolubori.

Gẹgẹ bii Multichoice ṣe sọ, Ebuka Obi-Uchendu ni yoo tukọ eto ọhun fun saa yii gẹgẹ bii awọn ololufẹ eto naa ṣe n fẹ

BBNaija

Oríṣun àwòrán, @BBNaija

Ṣaaju ni awọn eeyan kan ti kọkọ sọ pe ki wọn gba ẹlomira laye lati tukọ naa dipo Ebuka.

Lara awọn ti awọn eeyan naa ni o yẹ ko tukọ eto ọhun ni saa yii ni Frank Edoho to ti n tukọ eto "Who wants to be a millionaire" fun ọpọ ọdun.

Olamilekan Moshood Agbeleshe, ti ọpọ eeyan mọ si Laycon lo gbegba oroke ninu idije naa lọdun to kọja.

Aṣeyọri Laycon ti mu ko di olowo gọbọi ati gbajumọ laarin awọn ọdọ, awọn ololufẹ eto naa atawọn ololufẹ orin takasufe.