Ladipo market fire: Ọjà olówó iyebíye jóná nínú ọjà Ladipo nílùú Eko

Ladipo

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ọpọ ọja olowo iyebiye ti sọnu ninu ijamba ina to dede ṣẹyọ ninu ọja Ladipo, to wa lagbegbe Oshodi niluu Eko.

Inu ibanujẹ ni ọpọ awọn oniṣowo inu ọja naa wa lasiko ti BBC ṣabẹwo sinu ọja ọhun.

Ọja naa jẹ eyii ti wọn ti n ta awọn ẹya ara ọkọ.

Adari ajọ to n ri iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu sọ fun awọn akọroyin ninu atẹjade kan pe ina ọhun ti ba nnkan jẹ ki awọn oṣiṣẹ awọn to de agbegbe naa.

Ladipo

Oríṣun àwòrán, LASEMA

O ni "Lasiko ti a de agbegbe ọhjun, awọn oṣiṣẹ wa ri ile alaja kan ti wọn ti n ta ẹya ara ọkọ, ti ina ti jo."

Ladipo

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Oke-Osanyintolu sọ ṣalaye pe awọnj ko mọ ohun to ṣokunfa ina ọhun ṣugbọn iowadii ti bẹrẹ.

O ni "Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ pajawiri atawọn panapana ti gunlẹ si agbegbe naa ki ina ọhun ma ba tan de awọn ile miran to yi ọja ọhun ka, a ko tii le sọ ohun to ṣokunfa ina naa."

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?