Gani Fawehinmi: Agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọniyàn ni Nàìjíríà ti ọ̀rọ̀ tálákà jẹ lógún!

Ijoba ipinle Eko mo ere Gani fwehinmi

Oríṣun àwòrán, Lagos state

Gani Fawehinmi tó kú ni ẹni ọdun mọ́kànlélaadọrin jẹ́ ọ̀kan pàtàkì àti olókìkí ní Nàìjíríà.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló sábà maa ń pè é ni "agbéjọ́rò àwọn ènìyàn" àti "Agbẹjórò àgbà fún mẹ̀kúnnù" ó lo gbogbo nǹkan to ni láti jà fún àwọn ènìyàn Nàìjíríà.

Gani Fawehinmi pèlú àwọn bi i Wole Soyinka, di ohun to gbò òrò fún àwọn ènìyàn mílíọ̀nù àádọ́jọ.

Wo diẹ ninu irinajo Gani Fawehinmi:

O jẹ́ ọkùnrin tí kí fẹ̀ ki ènìyàn máa jìyà nínú ìdákẹ́jẹ́, kò sí bí ènìyàn ṣe le tóbí tó tí kò ṣe e pèníjà lọ́dọ̀ Gani Fawehinmi.

Fún bi ọgbọ̀n ọdún ó farada àtìmọ́lé, ìfìyàjẹ́ni, àti oníruuru ìgbìyànjú ìgbénipa lọ́wọ́ àwọn ìjọba ológun.

Fawehinmi kìí faramọ ìjọba to ba fẹ́ tẹ ojú òfin mọ́lẹ̀, ní ọ̀pọ̀ ìgbà sì ló máa n kede àìda ìjọba fún gbogbo ayé tó fi mọ́ àwọn ìjọba ilẹ̀ òkèrè.

Èèmèjìlélọ́gbọ̀n lo ti lọ ẹwọn bọ́ tí ẹmẹẹtàdínlógún nínú rẹ̀ sì jẹ́ labẹ ààrẹ ológun Ibrahim Babangida.

Alejo ti kìí kànlẹ̀kùn kó tó wọle ni Fawehinmi lọ́gbà ẹ̀wọn Ikoyi, Kaduna àti Gashua, wọ́n mọ̀ ọ́ ni Alagbọn, agọ́ ọlọ́pàá ni Panti àhamọ́ àwọn DSS.

Kini a le sọ nipa ijajangbara Ganiyu?

Bákan náà ló mú ọ̀rọ̀ àwọn ará ìlú tó n lu owó ìlú ni pónpó níjọba tó si n fi ìwà ìbàjẹ́ wọ́n hàn, ó tún máa n jẹ́ kí ara ìlú mọ̀ àwọn ìgbé ayé àìtọ́ tí wọn ń gbé tí wọ́n bá pinnu láti díje gba ìpò nílùú.

Kìí ṣe bákan náà ló rí lójú gbogbo ènìyàn, ìhà tó bá fi bá olúkúlùkù ṣe ni wọ́n mọ̀ sí, èyí kò ṣẹ̀yìn apọn tó ni láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìlú tó n ṣe pẹ̀lú gbogbo okùn àti agbára rẹ̀.

Fawehinmi jẹ́ ẹni ti kìí mú ìgbákan bọkan nínú, ó fẹ́ràn gbogbo ènìyàn àti ìdájọ́ tó yè kooro fún fún ará ìlú, ó jẹ́ ẹni tó ń máa'n dábò bo ẹ̀ta.

Ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ìjà tó jà ni ọ̀nà tí wọ́n gbà pa gbajúgbaà akọ̀ròyìn Dele Giwa ni pẹlú lẹta tó ni adó olóró nínú lọdún 1986.

Aimoye igba ni o maa n lọ sẹwọn

Oríṣun àwòrán, Daily Advent

Fawehinmi polongo ìjọba ológun àsìkò náà síta ni gbangba, Ajagun fẹ̀yìnti, Ibrahim Babangida tó jẹ́ olórí orílè-ède lasìkò náà, pé èjò rl lori lilọ́wọ́ ikú tó gba ẹ̀mí àkọ̀ròyìn náà.

Fawehinmi gbe ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ sùgbọ́n ó pàdánù ẹjọ́ náà , nítórí ìdí èyí, ìjọba fi ṣẹsin ni gbangba.

Nígbà tí wọ́n bi Babangida idi tí o fi ti agbẹ́jọrò náà mọ́lé, ó sọ fún ìwé ìròyìn kan pé kò ni tọ̀nà tí òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ nítórí àwọn ìjọba tó wà sáájú òun náà ti ṣe bẹ́ẹ̀ sẹ́yìn.

Bákàn náà ló ṣe lábẹ́ ìjọba ológun Sanni Abacha ni ìbẹ̀rẹ̀ 90's.

Kini ijajangbara ti gba lọwọ Gani Fawehinmi?

Fawehinmi ló sáájú ìwọ́de ti wọ́n se wọ́gile àbájáde ìdìbò ààrẹ June 12, 1993 kí o tó pada ju olóyè Moshood Abiola sẹ́wọn lẹ́yìn tó jáwé olúborí.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n gba ìwé ìrìnnà lọ ilẹ̀ òkeèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, tí wọn si lọ maa n tu, ilé àti ọ̀fíísì rẹ̀ láìmọye ìgbà.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti lùú tí wọ́n sì ti le kúrò láti àpá ibikan ni Nàìjíríà sí ìbòmíràn kí àwọn ará ìlú máa ba le ba sọ̀rọ̀.

Ọ̀pọ̀ ìwé tó kọ nípa àwọn ìjọba ológun ni wọ́n fòfinde, tí ọ̀kan nínú àwọn ilé rẹ̀ níbi tó kó àwọn ìwé agbẹ́jọ́rò rẹ̀ sí ni wọ́n fẹ́ dána sun nígbà ti ọwọ́ àwọn aládugbò tẹ àwọn oníṣẹ́ ibi tó fẹ́ dáná sún ibẹ̀.

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?

Tani Ganiyu Fawehinmi gangan?

Titi to fi di ọjọ́ ikú rẹ̀, kò sinmi láti maa pe àwọn tó ti rọ́wọ́ fi họri láwùjọ ti wọ́n sì n fi ọwọ́ ọlá gbá àwọn mẹ́kunnu lójú lọ́jọ́ ni gbangba, ó ń pè wọ́n lẹ́jọ́.

Ganiyu Oyesola Fawehinmi ni a bi ni ni inu oṣù kẹrin, ọdun 1938 sí ìdílé kan ni ìlú Ondo.

Baba rẹ̀ ni Saheed Tugbobo Fawehinmi tó jẹ́ gbájúgbajà ẹlẹsìn ìbílẹ̀ àti Islamu, gbajúgbajà onísòwò igi ni lásìkò náà,

O jẹ́ ẹlẹyinjú àànú tó n ṣe oore fún mẹ̀kúnnù bákan náà lo maa n sọ̀rọ̀ lòdi si owó orí tó bá ti pọ̀ jù bí o ti yẹ lọ.

Bàbá bàbá rl jẹ́ olóyè Lisa Alujanu Fawehinmi náà kojú àwọn oyìnbó gẹ̀ẹ́sì ní ṣẹntuiri kọkandinlógún àti sẹntuiri ogun.

Àkọlé fídíò, Iganmu shanty demolition: Oníṣẹ́ ibi pọ̀ tó ń ṣọṣẹ́ lábẹ́ afárá Iganmu yìí ti pẹ́ ṣùgbọ́n.

Wo die nipa eto ẹ̀kọ́ Gani Fawehinmi:

Nígbà ti Ganiyu wa ni ile ìwá girama ni olùkọ́ rẹ̀ kọ ìwé ránṣẹ́ sí bàbá rẹ̀ pé ọmọ náà yóò jẹ́ agbẹ́jọrò tó yanranti lọ́jọ́ ìwájú.

Lẹ́yìn tó pari ilé ẹ̀ka girama ló lọ si ilẹ́ gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1961 láti ka ẹ̀kọ́ òfin ni Holborn College Fasiti London.

Kí o tó ṣe ọdún méjì nílé ẹ̀kọ́ náà ni baba rẹ̀ kú, èyí sì ló mú kí owó láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ gbẹ.

Gani sísẹ́ gẹ́gẹ́ bi a fọlẹ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ láti tọ́ ara rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́.

Ó kàwé já tí ó sì di agbẹ́jọrò to dántọ́ lọ́dún 1965.

Leyin naa lo si bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tírẹ̀ ni ìlú Eko.

Kía ni iṣẹ́ rẹ̀ dí gbajugba ja tí ó sì di àwòkọ́ṣe fún àwọn ọjẹ̀wẹ́wẹ́ agbẹjọ́rò mííràn.

Awọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ rẹ̀ mííràn ni Fela Kuti ati ajijgbara to jẹ́ ẹgbọ̀n rẹ̀ Beko Ransome Kuti.

Awọn to ti ran ni ile iwe

Oríṣun àwòrán, Premiumtimes

Kini o ṣẹlẹ laarin Buhari ati Fawehinmi?

Fawehinmi faramọ́ ìṣẹ̀jọba ààrẹ Muhammadu Buhari lọdun 2003 àti 2007 fún ìdìbò ààrẹ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, Fawehinmi ti bá Buhari ja fún títẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọniyan lọju mọ́lẹ̀ lásìkò tó jẹ ààrẹ lọ́dún 80's

Lọ́dun 1993, Fawehinmi ni wọ́n fun ni àmiẹyẹ "Bruno Kreisky' oyè tí wọn máá n fún àwọn ti gbogbo àgbáyé bá ti mọ̀ fún jíjà fún ẹ̀tọ́ ọmọniyan.

Ní ọdún 1998 ó gba amiẹyẹ ẹgbẹ́ awọn agbẹjọrò ti ilẹ̀ òkèerè (IBA) Bernard Simmons award fún àwọn iṣẹ́ ribiribi tọ ti ṣe nípa jíjà fún ẹ̀tọ́ ọmọniyan.

Àkọlé fídíò, India, Coronavirus: Ìtọ́jú aláìsàn ló jẹ́ mi lógún nítorí ètò ìlera wa mẹ́hẹ- Nọ́ọ̀sì Kama

Lọ́dun 1994 òun pẹ̀lú àwọn ilú mọ̀ọ̀ká ọmọ Nàìjíríà mííràn náà dá ẹgbọ́ òṣèlú National Conscience Party (NCP) sílẹ̀ tí ó si dúrò díje dupò àsàrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà lọ́dun 2003.

Kìí ṣe àjàfẹ́tọ ọmọniyan nikan ni Fawehinmi, ó tún jẹ́ ẹlẹyinju àànú náà, ati ẹni to dántọ nínú iṣẹ́ agbẹjọ́rò.

Ó rán ọ̀pọ̀ ni ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ pàápàá jùlọ àwọn tí ẹbi wọn tòsì.

Bákan náà ló mú àyípada bá bí wọ́n ṣe ń ròyìn nǹkan tó n ṣelẹ̀ nílé ẹjọ́ pẹ̀lú ìdásílẹ̀ àtẹ̀jáde ìwé ìròyìn ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni ọdún 80's, èyí si jẹ́ irin iṣẹ́ pàtàkì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin àti àwọn agbẹ́jọrò ni Nàìjíríà.

Gani Fawehinmi: Agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọniyàn ni Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Litcaf

Ọdún 2001 ló gba oyè agbẹjọ́rò àgbà ni Nàìjíríà (SAN),

Ipò yii tó ga jùlọ fún àwọn agbẹ́jọ́rò ni Nàìjíríà,

Lọ́dun 2008 ó kọ oye tó ga jùlọ tí ìjọba orílẹ̀-èdè yìí máa n fún ènìyàn (OFR) láti fẹ̀hónú hàn lóri bi wọ́n ṣe n ṣe ìjọba lọ́nà àìtọ́ láti gba ti àti gba òmìnira ni Nàìjíríà.

Fawehimi fẹ́ ìyàwọ ni ẹ̀ẹ̀mèjì, ó bí ọmọ púpọ̀, ó sì kú ni ọjọ́ kaarun, oṣù kẹsàn an, ọdún 2009 lẹ́yìn tó ní ààrùn jẹjẹrẹ.

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi