Seyi Makinde: Ìfàsìkò ṣòfò ni bí àwọn ilé ìgbìmọ̀ ṣe ń pè fún àtúnkọ òfin

Democracy Day: Ìfàsìkò sòfò ni bí àwọn ile ìgbìmọ̀ ṣe ń pé fún àtúnkọ òfin- Makinde

Oríṣun àwòrán, @Seyimakinde

Gómìnà ìpińlẹ̀ Oyo onímọ̀ẹ̀rọ Seyi Makinde ni ẹnu yóò ya ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó n bèrè pé kíní àwọn nǹkan ti òun ti gbé ṣe ní ìpínlẹ̀ Oyo.

O ni òun yóò jọ wọn lójú pẹ̀lú ònírúúrú iṣẹ́ àkànṣe tí oùn ti ṣe láàrín ọdún méjì láti àsìkò yìí títí di inú oṣù kejìlá.

Mákinde sọ èyí lásìkò tó ń ṣí ilé ìwòsàn tó wà ni sẹkitéríàtì nípìnlẹ̀ Oyo, ó ni ṣíṣí rẹ̀ wáyé láti fún àwọn òṣìṣẹ̀ ní ìtójú tó yè kooro nítóri ìlera ni òògùn ọrọ̀.

Makinde ni òun mọ̀ nípa àwọn alátako tí wọ́n ti dúró sórí ayélujára láti yọ sùùtì lórí pé kíní àṣeyọrí òun fún ọdún méjì.

Bákan náà ni Makinde fi kun un pé ìpè tí àwọn ilé ìgbìmọ̀ àṣòfin ń pè fún àtúngbéyẹ̀wò òfin, kò ní ìtumọ̀ nítorí wọn kàn ń fi àsìkò sòfò ni.

Democracy Day: Ìfàsìkò sòfò ni bí àwọn ile ìgbìms ṣe ń pé fún àtúnkọ òfin- Makinde

Oríṣun àwòrán, @SeyiMakinde

Ó ní nǹkàn tí gbogbo ènìyàn ń jà fún ni ìlọsíwájú àti ìdàgbàssókè orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, kí àwọn ìpínlẹ̀ le maa pàṣẹ fún ara wọn.

Kìí ṣe ọ̀rọ̀ pé a fẹ́ ni ààrẹ ọmọ Yorùbá ni kókó bí kò ṣe àtúntò ohun gbogbo ni Nàìjíríà lápapọ̀. A nilò orílẹ̀ -èdè tí olúkúlùkò yóò tí lé mú ìràn rẹ̀ ṣẹ.

Ìjọba nílò ìfọ́wọ́sowọ́pọ̀ àwọn ènìyàn, nítorí bi ọ̀rs ààbò ṣe rí, kò yani lẹ́nu bi ọ̀pọ̀ ṣe n pè fún ọlọ́pàá agbègbè ti wọn.

"A nílò ayípade tó lààmìláaka báyìí lórílẹ̀-èdè yìí, a kò le tẹ̀síwájú láti máa dẹ̀bi ru àwọn ológun wa, ọdún 2019 ni ìjọba ìpińlẹ̀ Oyo ti tọwọ́ bọ̀wé pe kò sí ààyè fún àwọn darandaran láti má kó ẹ̀ràn jẹ̀ ni ìta gbangba sùgbọ́n títí dí àsìkò yìí ìjọba àpapọ kò kọ kọbioara si pàápàá jùlọ àwọn àjọ tó yẹ kí ó maa mójútó ṣíṣe rẹ̀.

Gómìnà tún fi àwọn nọ̀mbà ìpè yìí síta fún àwọn tó bá fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ láti pè sí:

Democracy Day: Ìfàsìkò sòfò ni bí àwọn ile ìgbìmọ̀ ṣe ń pé fún àtúnkọ òfin- Makinde

Oríṣun àwòrán, @Seyimakinde

Lórí ètò ààbò nípìnlẹ̀ Oyo, Gómìnà Seyi Makinde ni ọṣẹ̀ ọṣẹ̀ ni ìgbìmọ̀ lórí ètò ààbò ń pade fun ọ̀nà àbáyọ lórí gbogbo ìpèníjà ààbò tó bá yọjú.

Lánàá òdé yìí ni igbákeju àsojú ilẹ̀ Amerika ṣe abẹwò sí ilé agbára tí wọn ti n mójúto gbogbo ọ̀rọ̀ aabò ni ìpínlẹ̀ Oyo tó wa ni onireke, tó sí sọ pe ìgbésẹ̀ ìjọba ìpińlẹ̀ Oyo wu ni lórí gidi gan àti pé o jẹ́ èyí tí ó dara jùlọ ti oun ti ri ni àgbáyé, nítórina nkọ ìpińlẹ̀ Oyo n ṣiṣẹ́ takuntakun lori ọ̀rọ̀ àbò.

" Kódà mó gbọ́ pé tí àwọn ènìyàn bá ti wá fún ìsinmi òpin ọ̀sẹ̀ ni ìlú Ibadan, wọn kìí pada lọ́jọ́ ajé, kò sí nǹkan mííràn jú pé Ibadan fi wọn lọ́kàn balẹ̀ lọ".