Maj Gen Faruk Yahaya: Ìdí rèé tí ọ̀gágun 30 fi gbọdọ̀ kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí ìyànsípò olórí ọmogun tuntun

Faruk Yahaya

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian army

Yoruba bọ, wọn ni iadlu ni iṣelu. Iroyin to gbalẹ lori ayelujara ni pe ọgagun ọgbọn ninu iṣẹ ologun lo gbọdọ kọwe fipo silẹ nitori olori ọmogun tuntun, Maj. Gen. Frauk Yahaya.

Lẹyin ti olori ọmogun oriilẹ tẹlẹ, Ibrahim Attairu ku ninu iṣẹlẹ baalu ologun to ja niluu Kadana ni Aarẹ Muhammadu Buhari yan Ọgagun Yahaya sipo lati rọpo rẹ.

Lati igba naa ni a ti n gbọ pe awọn ọgagun to ṣaaju Yahaya wọ iṣẹ ologun ni lati yẹba fun un ni bayii to ti di olori ileeṣẹ ọmogun tuntun.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

Ṣugbọn kinni idi ti awọn ọgagun bi ọgbọn fi gbọdọ kuro ninu iṣẹ ologun nitori olori ọmogun ti Buhari ṣẹṣẹ yan sipo?

Ajagun fẹyinti , Rtd Col. Ayo Olaniyan ṣalaye fun BBC Yoruba pe eleyii ki ṣe nkan tuntun ninu iṣẹ ologun.

Ọgagun Olaniyan ni agbẹdọ ni fun awọn ọgagun to ṣaaju Yahaya wọ iṣẹ ologun, wọn ko le gbaṣẹ lọwọ rẹ laelae.

''Idi niyii ti wọn maa fi kuro ninu iṣẹ ologun ti iru nkan bayii ba ti ṣẹlẹ.

Yahaya to jẹ olori ọmogun tuntun ko lẹtọ lati paṣẹ fun awọn ọgagun ti wọn ṣaaju rẹ wọ iṣẹ ologun.

Faruk Yahaya

Oríṣun àwòrán, Twitter/Faruk Yahaya

Ṣugbọn nigba mii, ti wọn awọn ọgagun to ṣaaju olori ileeṣẹ ologun ba pọ, ijọbab le gbe wọn lọ si ibo miran ti wọn ko ti ni gbaṣẹ lọwọ olori ileeṣẹ ọmogun.

Ohun to yẹ ki ijọba ṣe ni pe ki wọn gbe awọn ọgagun bẹẹ lọ si ẹka mii ti wọn tun ti le wulo ileeṣẹ ọmogun.

Ijọba ti nawo ribi ribi le wọn lori pẹlu oriṣiiriṣii ileewe ti wọn ti lọ nile ati loke okun.

Idi niyii ti ijọba fi gbọdọ tun ero rẹ pa lori ki awọn ọgagun ninu iṣẹ ologun maa fipo silẹ nigba ti wọn ba yan ẹni to kẹyin wọn wọ iṣẹ ologun sipo,'' Ọgagun Olaniyan ṣalaye.

Ẹwẹ, ọgagun fẹyinti Olaniyan sọ pe ko si bi awọn to ba fẹyinti lẹnu iṣẹ ologun ṣe fẹ ditẹ gbajọba.

''Awọn ọgagun to ti fẹyinti ko le ronu lọ si ibi wi pe ki ditẹ gbajọba nitori wọn ko si lẹnu iṣẹ ologun mọ.

Awọn nkan ti wọn nilo lati lati ditẹ gbajọba ko si ni ikawọ wọn mọ nitori wọn kuro lẹnu iṣẹ,'' Ọgagun Olaniyan lo ṣalaye bẹẹ.