Ronke Oshodi Oke: Àjẹbí ni àwọ̀ pupa mi, omi UK ló mú kí ọmọ ìka mi dúdú

Ronke Oshodi Oke

Oríṣun àwòrán, ronkeoshodioke/Instagram

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Ronke Oshodi Oke ti pariwo sita pe oun ko bora gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n sọ, ti wọn si n tabuku ara oun.

Ronke fìdí ọrọ yii mulẹ ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ ni aarọ ọjọbọ.

Ronke ni awọn eeyan kan lara awọn ololufẹ oun lo beere pe ki lode ti oun fi n bora nigba to fi aworan ara rẹ kan sita.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá

Ilumọọka oṣere naa ni ẹsun tawon eeyan kan fi kan oun pe oun bora nitori ika oun to dudu, ku diẹ kaato nitori ọrọ ko ri bẹ́ẹ̀ rara.

Ronke salaye pe oun sẹsẹ ti ilu Ọba UK de ni, gbogbo eeyan lo si mọ pe omi wọn lagbara pupọ, eyi to yi awọ pupa oun yipada.

Ronke Oshodi Oke

Oríṣun àwòrán, ronkeoshodioke/Instagram

Bakan naa lo fikun pe ọmọ ika oun dudu nitori oun n fi omi gbigbona wẹ ni awọn akoko kan, eyi ti ko ba ọmọ pupa lara mu.

"Gbogbo eeyan to mọ mi mọ pe ajẹbi ni awọ pupa ti mo ni nitori awọn obi mi pupa.

Nitori naa lo jẹ ki n ṣe fidio yii lai kun atike tabi tọ nkan kan sí ojú mi, ki ẹ le mọ pe eeyan pupa ni Eledua da mi.

Ṣe ẹ ri ọwọ mi yii to dudu tẹ fi ro pe o da bi ẹni pe mo n bora, omi wọn ni UK ti ko ba mi lara mu lo jẹ ko ri bẹẹ," Ronke ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Ó dára kí obìnrin níṣẹ́ lọ́wọ́ - Toyin Lawani

Ẹwẹ, awọn akẹgbẹ Ronke kan ti sọ fun un pe ko kọ eti ikun sọrọ tawon eeyan kan n sọ nipa rẹ.

Wọn ni ko fi ọrọ naa ṣe ipakọ o gbọ suti, ori ẹlẹgan lo daru, ati pe iwọfa lẹnu, ohun to ba wu ẹlẹnu ni o le fi ẹnu rẹ sọ.