Biafra Day Celebration, May 30: Àwọn ajìjàngbara Biafra kéde ìsìnmi fáwọn Ibo láti ṣ'àyájọ́ Biafra

Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oni ọgbọnjọ, oṣu karun un, ọdun 2021 lo pe ọdun mẹrinlelaadọta ti oloogbe ọgagun Lt Col. Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu kede pe orilẹ-ede Biafra awọn Ibo ti ya kuro lara Naijiria.

Ikede Ojukwu yii lo jẹ ki ogun abẹle bẹ silẹ lọdun 1967, ọdun mẹta gbako ṣi ni wọn fi ja ogun naa.

Eeyan to le lẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ni ebi ati iṣẹ pa ku ninu ẹya Ibo ninu eyi ti awọn ọmọde ti pọju lọ.

Lati ọdun naa ni ọgbọnjọ, oṣu karun un ti di pataki ninu itan orilẹ-ede Naijiria papaa julọ fawọn ẹya Ibo.

Awọn Ibo naa ko kọkọ ka ọjọ yii kun tẹlẹ, amọ awọn to n pe ifun iyapa Ibo lara Naijiria ti jẹ ki wọn kaa kun bayii.

Lọdọọdun ni awọn ajijigbara fun idaduro ẹya Ibo lara Naijiria maa n sọ fawọn pe ki wọn joko sile lọgbọnjọ oṣu karun lati le fi ṣe ayajọ Biafra.

Àkọlé fídíò, India, Coronavirus: Ìtọ́jú aláìsàn ló jẹ́ mi lógún nítorí ètò ìlera wa mẹ́hẹ- Nọ́ọ̀sì Kama

Ojukwu gan an ni olori Biafra nitori oun lo kede iyapa Ibo lara Naijiria.

Ilu Nnewi ni Ojukwu ti wa nipinlẹ Anambra ṣugbọn ilu Zungeru nipinlẹ Niger ni wọn bi i si lọdun 1933.

Ọmọ onile ọlọna ni Ojukwu i ṣe, awọn obi rẹ ran an nile iwe debi pe o tun kawe ni fasiti niluu London.

Chukwuemeka Odumegwu Ojukwu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin ti o kawe gboye ni fasiti niluu London lo darapọ mọ ileeṣẹ ologun Naijiria.

Ojukwu di gomina ologun apa ila -oorun Naijiria lẹyin tawọn ologun ditẹ gbajọba alagbada lọdun 1966 bo tilẹ jẹ pe ko lọwọ ninu iditẹgbajọba ọhun.

Ko gba pe ọga ni Yakubu Gowon to jẹ aarẹ ologun jẹ fun oun, ati pe o ni Gowon n yan awọn ẹya Ibo jẹ.

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Lẹyin naa lo kede orilẹ-ede Biafra pe ẹya Ibo ṣetan lati yapa kuro ni Naijiria eyi to jẹ ki ogun bẹ silẹ.

Ojukwu lọ ṣatipo lorilẹede Ivory Coast lọdun 1970 lẹyin ti ogun abẹle pari ki ijọba Naijiria to darijin in lọdun 1982.

Ijọba Naijiria gbe Ojukwu lọdun 1983 lẹyin iṣẹlẹ iditẹgbajọba kan, ṣugbọn wọn pada fi i silẹ lọdun 1984.

Ojukwu ko saaba dasi ọrọ oṣelu mọ lati igba naa titi to fi ku lọdun 2011.

Àkọlé fídíò, Simple tricks to identify designer shoes: Ṣe ìwọ lè wọ bàtà #2 mílíọ̀nú