Imeko-Afon Attacks: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ogun ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà jọ ti ìdigunjalè

Awọn eeyan to n sa kuro ni Imeko-Afon

Kaka ki ewe agbọn dẹ lori iwa isekupani ọlọgọọrọ to n lọ nilẹ Yoruba, ko ko ko lo tun n le si.

Bi awọn agbofinro si se n ge awọn asekupani yii lọwọ, naa ni wọn tun n bọ oruka, ti wọn si n gba ẹmi alaisẹ laibikita.

Ni oru mọju ọjọ Aiku ni iroyin gbalẹ kan pe awọn afurasi darandaran tun ya bo ilu Igangan lagbagbe Ibarapa nipinlẹ Oyo, ti wọn si sekupa eeyan to le ni mọkanla, gẹgẹ bi ọlọpaa ti sọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni idaji ọjọ Aje ana tun ni iroyin miran gbalẹ kan pe awọn ẹni bii yii tun ti morile ilu Imeko-Afon nipinlẹ Ogun, ti wọn si tun gba ẹmi eeyan mẹta.

Isẹlẹ naa ni iroyin sọ pe o waye ni oru mọju ọjọ Aje bakan naa, ti ọrọ si di boo lọ, ko yago fun mi.

Àkọlé fídíò, Farmers Herders Crisis: Rẹ́rẹ́ rún, ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò lágbègbè Ariwa Yewa

Gẹgẹ bi awọn eeyan kan ti sọ, wọn ni awọn agbebọn to se ọsẹ nilu Igangan, naa ni wọn tun morile ilu Imeko Afon, ti ko jinna si Igangan, lati paniyan.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, osisẹ kan lara ikọ alaabo alajumọse ni agbegbe Imeko Afon, amọ ti ko fẹ ka darukọ oun ni lootọ ni isekupani naa waye.

Osisẹ agbofinro naa ni awọn arọko ti ọpọ eeyan ti n sisẹ agbẹ bii Gbondoko, Ladugba ati Afon, ti wsn wa nijọba ibilẹ Imeko Afon, ni ikslu naa ti waye.

O fikun pe awọn ko sun mọju lati ri daju pe ohun gbogbo pada bọ sipo lawọn agbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Ayelala Idol: Onímọlẹ̀ ní olúwẹri obìnrin ni òrìṣà náà ló ṣe ń pọn omi sínú ẹlẹ́ṣẹ̀

O si fidi rẹ mulẹ pe ẹmi mẹta lo ba ikọlu naa lọ lawọn abule naa.

"Ẹ wo, gbogbo awọn agbẹ to n sisẹ oko lagbagbe yii ni wọn ti n ko ẹru wọn lati sa kuro nitori ikọlu gbogbo igba to maa n waye nibẹ.

Gbogbo agbegbe naa si lo kan gogo bayii, koda, a ko sun mọju."

Ọlọpaa Ogun ni isẹlẹ naa jọ iwa idigunjale:

Nigba toun naa n fidi isẹlẹ yii mulẹ, osiẹ alarina fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ni lootọ lo waye amọ kii se ikslu afurasi darandaran.

Oyeyemi ni isẹlẹ naa lo jẹ ti awọn adigunjale, nitori wọn ja ọkada gba, ti wọn si ji gbe lọ.

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

"Awọn ti wọn kọlu yii jẹ agbẹ lati orilẹede Benini to maa n wa sisẹ oko lorilẹede Naijiria.

Wọn n gun ọkada lọ, ti wọn si bọ sọwọ awọn eeyan to sẹburu wọn, wsn pa wọn, ti wọn si tun gbe awọn ọkada wọn salọ.

A ko mọ boya darandaran ni wọn amọ ikọlu naa fara pẹ isẹlẹ idigunjale nitori wọn ji ọkada gbe lọ.

Kii se igba akọkọ ree ti iru isẹlẹ bayii yoo waye ni agbegbe Imeko-Afon, eyi to n mu ẹmi ọpọ eeyan lọ.