Farmers Herders Crisis: Rẹ́rẹ́ rún, ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò lágbègbè Ariwa Yewa

Àkọlé fídíò, Farmers Herders Crisis: Rẹ́rẹ́ rún, ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò lágbègbè Ariwa Yewa

Yoruba ni iroyin ko to afojuba, ẹni to ba de ibẹ nikan lo le sọ, iroyin okeere si ree, bi ko ba dinkan, yoo le ọkan.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba balẹ sagbegbe Ariwa Yewa nipinlẹ Ogun to paala ilẹ pẹlu orilẹede Benin.

Lẹnu lọọlọ yii ni ẹnu n kun agbegbe naa nipa ọsẹ nla tawọn ọdaran Fulani n se fun wọn eyi to ti sọ agbegbe naa di ahoro, tawọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn.

Lasiko abẹwo wa naa silu Igborọ, Iselu, asa ati bẹẹ bẹẹ lọ, ẹnu ko gba iroyin nipa ọpọ ile, mọto, dukia ati ire oko to bajẹ lasiko awọn ikọlu naa.

Ikọ BBC Yoruba ba awọn olugbe agbegbe naa sọrọ, to fi mọ asoju Fulani, ta si tun kan si ijọba ipinlẹ Ogun lati mọ aayan to n se lati pinwọ ikọlu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: