Boko Haram: Oúnjẹ́ tí wọn kó pamọ́ sínú iléẹ̀kọ́ ló mú kí wọn ṣe ìkọlù síbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Premium Times
Ikọ agbesunmọmi Boko Haram tun ti ko ibẹru bojo ba awọn eeyan ariwa Naijria, nigba ti wọn se ikọlu si abule Katarko ni ijọba ibilẹ Gujba ni ipinlẹ Yobe.
Ninu ikọlu yii ni wọn tun ti dana sun ibudo awọn ọmọ ogun Naijiria, ileewe kan ati ile iwosan kan to wa nibẹ.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Premium Times ti salaye, abule Katarko jinna si Damaturu to jẹ olu ilu ipinlẹ Yobe ni iwọn kilomita marundinlọgbọn.
Igbimọ to n sakoso asunwọn owo iranwọ fawọn to kagbako Boko Haram ti ijọba gbe kalẹ, Victims Support Fund, lo tun ileewe ti wọn pada sun lẹẹkeji yii kọ, lọdun 2013.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Agbébọn pa èèyàn 58 tó ń ti ọjà bọ̀, jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀, fi oúnjẹ ṣòfò
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí márùn ún míràn lórí ikú ọmọ Fasoranti
- Wakili àtàwọn méjì míì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn, ìjínigbé àti olè kàn wọ́n
- Àwọn agbébọn jí èèyàn méjì gbé ní ibùdó tí wọ́n tí ń fọ́ òkúta ní Ibadan
- Agbẹnusọ Sunday Igboho ná N2.5m bíí owó oúnjẹ́ lásán, gbas gbos bẹ̀rẹ̀
- "Torí ₦20, ọlọ́pàá yìnbọn fún mi lọ́rùn, n kò sì le b'óbìnrin lòpọ̀ mọ́ tàbí bímọ''
- Bí Buhari kò bá ṣọ́ra, àwọn ọba alayé ni yóò ṣaájú ìjìjàgbara fún Yorùbá - Sunday Igboho
- Èèyàn mẹ̀rin kú, 189 wà nílé ìwòsàn torí ayédèrú ohun mímu tí wọn mu
Iroyin kan ni awọn agbesunmọmi ọhun ko ọpọ ounjẹ tijọba fẹ pin fawọn araalu, ti wọn ko pamọ sinu ileewe naa, idi si niyi ti wọn fi se ikọlu sileewe ọhun.

Oríṣun àwòrán, Premium Times
Bakan naa lawọn araalu sọ pe wọn tun dana sun ile iwosan to wa labule naa, lẹyin ti wọn ji awọn oogun to wa nibẹ ko.
Araalu kan to ba awọn akọroyin sọrọ, Modu Katarko sọ pe, ni nkan bii aago marun un abọ owurọ ọjọ Isẹgun ni wọn wa sibẹ ati pe, ko si ẹnikankan to koju wọn laarin wakati kan ti wọn fi sọsẹ.
O ni lasiko to yẹ kawọn lọ kirun ni wọn de sagbegbe naa, ti gbogbo araalu si tilẹkun mọri.
O ni lẹyin igba ti wọn setan ni wọn lọ si ibudo awọn ọmọ ologun to wa nitosi ibẹ, ti wọn si n yinbọn soke laibikita.
Ileesẹ ologun ko tii fesi si isẹlẹ yii lasiko ta fi n se akojọ iroyin, ikọlu sawọn ileẹkọ ati ijinigbe awọn akẹkọọ si ti n peleke si.
Yatọ si eleyi tawọn ikọ Boko Haram n se, awọn janduku agbebọn miran ti sọ ijinigbe di isẹ lawọn ipinlẹ bii Kaduna, Katsina ati apa ibomiran ni Naijiria.
Àlàyé rèé lórí bí wọn ṣe pa bàbá mi àti mọ̀lẹ́bí mi màrùn-ún l'Osun - Ọmọ olóògbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ oloogbe ti salaye bi ọrọ se ri nibi iṣẹlẹ bi awọn agbebọn to yinbọn pa eeyan mẹfa ninu ẹbi kan naa lọjọ Aiku lagbegbe Wasimi, lopopona Ife-Ibadan, nipinlẹ Osun.
Gẹgẹ bi ohun ti ọmọ olori ẹbi naa, Yahaya Samu, se sọ fun awọn akọroyin nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, o ni awọn agbebọn naa gbe alupupu meji wa si ibi ti wọn ti ṣe akọlu si wọn.
Bakan naa lo fikun pe awọn agbebọn naa n beere owo lọwọ olori ẹbi naa, ki wọn to yinbọn pa oun atawọn ọmọ rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari fẹ́ yá ₦895m owó aráàlú ti wọn ko lo ní báǹkì, Serap fọnmu dele ẹjọ
- Ògo àgbáyé wọ Nàíjíríà, Burna Boy àti WizKid gbàmì ẹyẹ Grammy
- Mò ń lọ ibùdó tí Fulani ti ń wa kùsà ní Idere, màá lé wọn dànù pátápátá - Sunday Igboho
- Oloolu lọ ṣètùtù kí òjò rọ̀ n‘Ibadan, áwọn jàǹdùkú kọ lù ú, ọ̀pọ̀ ṣèṣe, ẹ̀mí sì bọ́
- Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá làwọn ọkùnrin ti ń fipá bá mi lòpọ̀ nígbà márùn-ún - Iyabo Ojo
- Àwọn agbébọn láti Òkè Ọya ń wa góòlù ní Ilesa, Owo àti Igangan láì sí ìdíwọ́ - Gani Adams
- Ẹ fi ilẹ̀ tí a kò lò hááyà fáwọn darandaran bíi ibùdó ọ̀sìn màálù - Tinubu
- Ondo ló lékè nínú ìpínlẹ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus júlọ ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá tún wa sílẹ̀, àwọn àjínigbe yìí le ṣe ohunkóhun fún wa
- Ìhòhò ọmọlúàbí ní òṣèrébìnrin yìí fi lọ sí àmi ẹ̀yẹ tí wọ́n pè é sí
Samu ni ọpọlọpọ ile lo wa ni ileto naa to jẹ nnkan bii kilomita marun un si marosẹ Ife-Ibadan, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe ẹbi naa nikan ni awọn eeyan naa dojukọ.
Yahaya sọ pe "awọn agbebọn naa gbe alupupu meji wa ni nnkan bii aago mẹwa alẹ, wọn si bẹrẹ si n wa inu gbogbo awọn ile to wa ninu ileto naa, wọn mu iyawo mejeji oloogbe naa jade pẹlu mẹta ninu awọn ọmọ ọmọ rẹ."
"Wọn beere Alhaji, lẹyin ti wọn mu wọn lọ si ọdọ baba mi ninu Mọṣalaṣi to ti n gbadura, wọn beere owo lọwọ rẹ, o ni oun ko ni owo kankan lọwọ, lẹyin naa ni wọn ni ko dide ti wọn si yin-in nibọn."
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun, alaga ana ni ijọba ibilẹ Irewole, Remi Abbas sọ pe, ni kete ti oun gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni oun ko awọn eeyan oun sodi lati yọju sibẹ.
O ṣalaye pe "nigba ti a fi maa de ibẹ, wọn ti yinbọn pa eeyan mẹfa, lẹyin naa ni a gbe ẹni keje ti ẹmi ṣi wa lara rẹ digbadigba lọ ile iwosan, nibi to to ti n gba itọju lọwọ."
Abbas sọ siwaju si pe, pupọ ninu awọn to n gbe ileto naa lo sa asala fun ẹmi wọn nigba ti awọn agbebọn ọhun n ṣọṣẹ lọwọ, ti wọn ko si tii ri bayii.
Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹni to le sọ irufẹ eeyan ti awọn agbebọn naa jẹ, iroyin ni awọn agbofinro atawọn ọmọ ikọ OPC ti kan lu igbẹ lati ṣawari awọn afurasi naa.
Agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe, mọlẹbi kan naa ni gbogbo awọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ìpinlẹ̀ Osun kò níṣe pẹ̀lú wàhálà làárìn darandaran àti àgbẹ̀-Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Osun ti tan ìmọ̀lẹ̀ sí ìṣèlẹ̀ tó wáyé ni àbúlé kan ni ẹ̀gbẹ́ Wasinmi pé ko níṣe pẹ̀lú làásìgbò tó ń wáyé láàrín àgbẹ̀ àti darandaran.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ èyí nínú àtẹ̀jáde kan to fi síta ti agbẹnusọ ọlọ́pàá Yemisi Opalola sì fọwọ́sí tí pẹ̀lú àkọlé "Ìṣẹ̀lẹ̀ Ikire, Osun kòníṣe pèlú ọ̀rọ̀ darandaran ati àgbẹ̀.
- Ṣé lóòtọ́ ni Alaafin Ọyọ ti fẹ́ olorì tuntun láti ẹ̀yà Igbo? Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa rẹ̀
- Ọpẹ́lọpẹ́ àjẹsára, ó yẹ kí n ti kú lẹ́yìn tí àwọn jàǹdúkú ṣá mi ní àdá - Oyinkansola Elebuibon
- Ayé àkámarà! Liverpool laná ní Anfield, Chelsea pa òkúta sí gaàrí wọn
- Wo ìtàn Orunmila, Babaláwo àkọ́kọ́ àti ohun tó fi sílẹ̀ lọ níbí
Àtẹ̀jáde náà kà pé: "Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Osun ń fi àsìkò sọ pe ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó wáyé ni agbègbè Wasinmi mi Ikire, ìpínlẹ̀ Osun ní ọjọ́ kẹrinlà oṣù kẹta, ọdun 2021 kò níṣe pẹ̀lú wàhálà àwọn Fulani àti darandaran."
"Kọmísọ́nà ọlọ́pàá Olawale Olokode tó sàbẹ̀wò síbẹ̀ sàlàyé pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí, àwọn sì tí wá àwọn ọdaran to ṣíṣẹ́ náà.
Osun Massacre: Àwọn agbébọn pa èèyàn mẹfa ni abúlé kan nìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, Osun
Lónìí ọjọ́ Ìsinmi ni ìròyìn tan kálẹ̀ pé àwọn agbébọn lọ ká àwọn èèyàn kan mọ́lé, ti wọ́n si pa wọ́n ni abúlé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Wasinmi, lópòpónà márosẹ̀ Ife si Ibadan.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tó mọ ẹni to ṣe iṣẹ́ ibi náà, sùgbọ́n àwọn ọlọ́paàá àti ọmọ ikọ̀ OPC to fi mọ́ àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ lo ti wọ inú igbó to wà ni àyíká abúlé náà lọ, láti lọ ṣàwárí àwọn tó ṣe irú iṣẹ́ ibi rẹ̀.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mò ń lọ ibùdó tí Fulani ti ń wa kùsà ní Idere, màá lé wọn dànù pátápátá - Sunday Igboho
- Mo ti gbé Wakili lọ sílé ẹjọ́ rí, adájọ́ ní ká lọ yanjú ọ̀rọ̀ láàrin wa - Baálẹ̀ Itamofin Ayete
- Àwọn agbébọn láti Òkè Ọya ń wa góòlù ní Ilesa, Owo àti Igangan láì sí ìdíwọ́ - Gani Adams
- Oloolu lọ ṣètùtù kí òjò rọ̀ n‘Ibadan, áwọn jàǹdùkú kọ lù ú, ọ̀pọ̀ ṣèṣe, ẹ̀mí sì bọ́
- Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá làwọn ọkùnrin ti ń fipá bá mi lòpọ̀ nígbà márùn-ún - Iyabo Ojo
- Ẹ fi ilẹ̀ tí a kò lò hááyà fáwọn darandaran bíi ibùdó ọ̀sìn màálù - Tinubu
- Ondo ló lékè nínú ìpínlẹ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus júlọ ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ wá tún wa sílẹ̀, àwọn àjínigbe yìí le ṣe ohunkóhun fún wa
Ìròyìn sọ pé sàdédé ni àwọn agbébọn wọ ìlú náà, ti wọ́n si bẹ̀rẹ̀ si ni yìnbọn láìbíkítà.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Osun, Yemisi Opalola fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé, ẹbí kan náà ni àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ẹ̀wẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, mínísítà fún ètò ìrìnà ojú òfurufú tẹ́lẹ̀ rí, Femi Fani-Kayode ti kọ si ojú òpó twitter rẹ̀ pé, àwọn Yorùbá kan lo lọ pa ẹbi Fulani kan ni abule naa.

Oríṣun àwòrán, Fani Kayode















