Sunday Igboho: Báwọn ọmọ Wakili tó pa èèyàn mẹ́rin sá wọ ihò ilẹ̀, màá rí wọn mú

Igboho

Oríṣun àwòrán, @marketdigestng

Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti bẹrẹ iṣẹ ijijagbara rẹ pada, lati le awọn ọdaran Fulani kuro nilẹ Yoruba.

Agbegbe ti Igboho dojukọ lọtẹ yii ni ilu Idere to wa nipinlẹ Oyo.

Idi ree ti Sunday Igboho ṣe ṣabẹwo si Onidere ti ilu Idere, Ọba Kingsley Onikola Oyelami, lati fi to ori ade naa leti nipa igbesẹ to fẹ gbe nilu naa.

Ninu fidio kan to n ja rain lori ayelujara ni Igboho ti sọ fun ori ade ọhun atawọn eeyan to wa ni aafin rẹ pe, inu oun ko dun si iroyin tuntun ti oun gbọ pe awọn ọdaran Fulani darandaran pa eeyan mẹrin niluu naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn afurasi apaayan ọhun jẹ ọmọlẹyin Iskilu Wakili, ti awọn ọmọ ikọ OPC fi ṣinkun ofin mu ṣaaju lori oniruru ẹsun ijinigbe ati ipaniyan lagbegbe Ibarapa.

O ni "nigba ti mo gbọ ọrọ yẹn pe awọn ọmọlẹyin ọgbẹni Wakili yẹn tun paayan lagbegbe yii, o jẹ nnkan iyalẹnu fun mi."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ko yẹ ki a wa lori ilẹ wa ki awọn Fulani maa wa pa wa lori ilẹ wa, ko yẹ ka ma le sun lori ilẹ wa."

Igboho tẹsiwaju pe, oun gbọ nipa agbegbe kan ti awọn afurasi naa ti n wa kusa ni ilu naa ati pe, oun ti ṣetan lati le wọn kuro lagbegbe ọhun.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

O tẹsiwaju pe "a fẹ ṣewadii awọn Fulani to pa eeyan mẹrin, bi wọn ba wọ inu iho ilẹ, n o wa wọn kan."

Ajijagbara naa ni oun atawọn eeyan oun ti ṣetan lati fun awọn to n wa kusa lagbegbe ọhun ni gbedeke akoko ti wọn yoo fi ibẹ silẹ.

Igboho pari ọrọ rẹ pe "a o de ibi kusa yẹn, a o si ri pe a le gbogbo bororo ati Fulani to n wa kusa kuro nibẹ patapata laṣẹ ẹyin baba wa ti ẹ bi wa."

"Ti ọmọ Yoruba ba nifẹ si ati maa wa kusa a o fi wọn sibẹ, awa ni a ni ilẹ ṣugbọn Fulani lo n wa kusa nibẹ, ko dẹ yẹ ko ri bẹẹ."

Àkọlé fídíò, Prophet Shittu Adeniyi: Ẹni tó bá ń tọrọ agbe, kìí jẹ́ èèyàn ní mo ṣe tẹ́pa mọ́ṣẹ́

Ṣaaju ni Igboho ti kọkọ lọ si ilu Igangan, ni Ibarapa yii kan naa lati le awọn Fulani darandaran kan kuro lagbegbe ọhun lẹyin iku Ọmọwe Faborode, ti wọn fẹsun kan pe awọn darandaran naa ṣekupa.

Igbesẹ ọhun mu ki ọpọ eeyan kan sara si Igboho kaakiri ni Naijiria ati loke okun, ti awọn kan si n woo gẹgẹ bii Mesaya iran Yoruba lakoko yii.