Sunday Igboho: Bí Alaafin, Ooni, Olubadan ṣe tì mí lẹ́yìn fihàn pé ìrẹ́pọ̀ ti dé sáàrin Yorùbá

Eekan ọmọ ilẹ Yoruba to n lewaju ipe fun didẹkun wahala awọn darandaran nilẹ Yoruba, oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho tun ti sọrọ nipa isẹlẹ to waye naa.
Lọtẹ yii, Sunday Igboho ti kan sara si awọn lọbalọba ati agbaagba ilẹ Yoruba, ti wọn dide ṣi ọrọ wahala awọn darandaran Fulani nilẹ to n waye bayii.
O ni eyi fihan pe ilẹ Yoruba ti ṣetan lati kọ awọn igi aitọ tawọn ajeji n ki bọ ọ loju.
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Afurasí Fulani daran-daran fi ìbọn fọ́ ìka obìnrin kan lójú pópó
- Sunday Igboho sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí Igangan
- Ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Oduduwa ló mú kí Yorùbá wá kọlu Fulani ní Igangan - Ọmọ Seriki Fulani
- Báyìí ni àwa àti Sunday Igboho ṣe rìnrìn àjò láti Ibadan lọ sí Igangan"
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
- Wo ǹkan mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sunday Igboho tí orúkọ rẹ̀ gbẹnu aráyé kán
- Ó tó gẹ́! Ọ̀gá Ọlọ́pàá pàṣẹ pé kí Kọmísọ́nnà Oyo mú Igboho wà sí Abuja
Ninu ọrọ to sọ ninu fidio kan to jade, lẹyin aṣẹ ọga ọlọpaa ni Naijiria, pe ki wọn fi panpẹ ofin mu u nitori wahala to waye ni gaa awọn Fulani lagbegbe Ibarapa, ni Igboho sisọ loju ọrọ naa.
Sunday Igboho ṣalaye pe, iwuri nla lo fun oun pe awọn agba oriade bi Ooni ile Ife ki foonu mọlẹ, lati sọ fun aarẹ Buhari pe ina ti jo dori koko, ko saye mọ lati fi ọmọ Yoruba ṣe etutu Naijiria mọ.
Bakan naa lo ni Alaafin pẹlu ti kọ lẹta ikilọ lori ọrọ naa, ti Awujalẹ Ijẹbu, Olubadan tilẹ Ibadan ati Ataọja Oṣogbo naa ko si dakẹ lori isẹlẹ yii.
Igboho tun gbe oriyin fawọn eekan ọmọ bibi ilẹ Yoruba bii Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Ọjọgbọn Wọle Soyinka ati Femi Fani Kayọde.
Bakan naa lo yonbo gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose, Dele Momodu ati Aarẹ Ọna Kakanfo, Iba Gani Adams fun bi wọn ṣe dide si ọrọ naa.
O wa rọ awọn ọmọ Yoruba gbogbo lati bọwọ fawọn agbagba ilẹ Yoruba nibi ti ọrọ naa de duro bayii.
Igboho ni o ti han gbangba pe awọn agbaagba pẹlu ti ji giri lati sa ipa gbogbo to yẹ fun aabo ati idagbasoke ilẹ Yoruba.




















