Sunday Igboho: Àwọn olórí Fulani tọrọ àforíjìn, wọ̀n ń fẹ́ ibagbepọ̀ àlàáfíà ni Ibarapa

Ipade awọn Fulani ati ijọba pẹlu agbofinro nilu Igangan

Oríṣun àwòrán, GALAXY TV

Awọn olori Fulani to n gbe ni agbegbe Ibarapa ati Oke Ogun ni ipinlẹ Oyo ti tọrọ aforijin lori iwakiwa tawọn eeyan wọn hu eyi to fa gbọnmisi omi o to nibẹ.

Wọn ṣe ipinu bakan naa lati faye gba ibagbepọ alaafia laarin awọn ati awọn alabagbe wọn.

Ọrọ yii wa lara ababọ ikọ ti ijọba ipinlẹ Oyo gbe dide lati ṣabẹwo si Ibarapa ati awọn agbegbe mii ni Oke Ogun.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Gomina Oyo Taiwo Adisa fi sita, o ṣalaye pe igbimọ naa kan si Igangan, Tede and Ago Are ati ile Seriki Fulani ti wọn sọ ina si.

Ni Igangan ni awọn eeyan ilu ti tu kẹkẹ ọrọ silẹ nipa aburu ti wọn ni Seriki naa n hu ni iwa.

Awọn mọto Seriki Fulani ti wọn sọ ina si

Oríṣun àwòrán, GALAXY TV

Akọwe ẹgbẹ idagbasoke Igangan, Lawal Akeem ni ọrọ Seriki ,Alhaji Saliu Abdukadir, ti su awọn ara ilu pẹlu bi ọwọ rẹ ko ṣe mọ ninu awọn ẹsun iwa ọdaran lorisirisi.

O fi kun pe awọn ara ilu ti san owo idoola to to aadọta miliọnu naira lọwọ awọn ajinigbe Fulani.

Bẹẹ lo ni lemolemọ awọn Fulani nipa biba oko awọn eeyan wọn to jẹ agbẹ jẹ, ati fifi ipa ba awọn obinrin lo pọ kọja afarada.

Ọdọ kan naa ni Ilu Igangan, Taiwo Adeagbo, gẹgẹ bi Fatai Adisa ṣe sọ, ni o kere tan obinrin mẹẹdogun lawọn Fulani ti fipa ba lopọ.

Ipade awọn Fulani ati ijọba pẹlu agbofinro nilu Igangan

Oríṣun àwòrán, GALAXY TV

Gbogbo awọn ẹsun naa lo ṣeeṣe ko mu awọn Seriki Fulani Igbo Ora ati ti Eruwa, Alhaji Idris Abubakar, ati Alhaji Sule Mohammed, wa aforijin lọdọ ara ilu.

Wọn ni awọn ṣetan lati ṣiṣẹ pọ, ki alaafia le rinlẹ lagbegbe naa.

Ẹwẹ, awọn eeyan mii to sọrọ nibi ipade naa, bi oluranlọwọ pataki fun Gomina Makinde lori ọrọ aabo, Fatai Owoseni, parọwa sawọn olori ilu, awọn ọdọ Yoruba ati Fulani, lati yago fun iwa ipa, ki wọn si dijọ maa gbe pọ lalaafia.

Atẹjade naa ni Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Oyo ati awọn aṣoju mii ti ijọba yan, ni wọn jijọ kọwọrin ṣabẹwo sawọn ilu naa ni agbegbe Ibarapa ati Oke Ogun.

Ipade awọn Fulani ati ijọba pẹlu agbofinro nilu Igangan

Oríṣun àwòrán, GALAXY TV

Lakotan, o ni Kọmisana ọlọpaa ni orisirisi ọrọ lo ti n tankalẹ nipa iṣẹlẹ to n waye lawọn agbegbe yii ṣugbọn kii ṣe ootọ pe ijọba ko ṣe nkan si iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan to n waye nibẹ.

Atẹjade naa fikun pe ''awọn ti mu to afurasi ọdaran mọkanlelaadọta to lọwọ si awọn iwa aburu yii ati pe, awọn yoo ṣe iwadi to peye lori ẹsun ti wọn fi kan Seriki pe o n lẹdi apo pọ pẹlu awọn aṣebi''