Sunday Igboho vs Fulani: Wo ohun tí BBC rí nílé Seriki Fulani ní Igangan

Igangan

Gbendeke ọjọ meje ti Sunday Igboho fun awọn Fulanai lati ko ẹru wọn kuro ni Igangan ni ẹkun Oke Ogun ni ipinlẹ Oyo pe ni ana ọjọ Ẹti.

Nibẹ dẹ ni Sunday Igboho lọ ti o si ba awọn ara ilu sọrọ loriṣiriṣi.

Oriṣiriṣi nkan lo ti kọkọ ṣẹlẹ ṣaaju asiko yii pe:Gbèǹdéke ku àsìkò díẹ̀, Seriki Fulani fohùn ránṣẹ́ sí Sunday Igboho

Lẹyin ti Sunday Igboho lọ kuro ni Igangan ni ẹkun Ibarapa tan lana ni Serki Fulani, Alhaji Saliu Abdulkadir pariwo sita pe wọn ti sọ ina sile oun.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Nigba ti BBC kan si Seriki naa, o ni awọn afurasi ti oun gab pe wọn jọ ọmọ lẹyin Sunday Igboho lo ṣe iṣẹ naa.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Igboho Ultimatum to Fulani: Ẹni bá mọ Sunday Igboho kó bá wa bẹ̀ẹ́ o,

Nigba ti BBC Yoruba kan si ikọ Sunday Igboho, wọn ni Sunday Igboho ko tilẹ de adugbo Gaa Fulani rara lanaa.

Ati pe omi suuru lo fun awọn eniyan Igangan mu lori ọrọ naa lanaa.

Igangan
Igangan
Igangan

Awọn Ikọ Sunday Igboho ṣalaye fun BBC pe: O ṣeeṣe ko jẹ pe lẹyin ti Sunday Igboho kuro ni Igangan tan lanaa ni eyi ṣẹlẹ ni eyi ti awọn ko si mọ sii rara.

Igangan
Igangan
Igangan
Igangan
Igangan
Igangan
Àkọlé fídíò, Lawal Ayankemi Oluwatoyin: Mo kọ̀ láti máa tọrọ owó nítorí ojú mi tó fọ́, iṣẹ́ ló wù mí