New Nigeria Ambassadors: Wo orílẹ̀-èdè tí ìkọ̀ọ́kan àwọn aṣojú Naijiria yóò ti ṣiṣẹ́ jákèjádò àgbáyé

Ambsasadọ

Oríṣun àwòrán, others

Lẹyin ọpọlọpọ oṣu ti idiwọ ti ba, Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu pipin isẹ fun awọn ti yoo ṣoju Naijiria ni awọn orilẹ-ede agbaye.

Lara awọn aṣoju tuntun naa lati ri:

Ademola Rasaq Seriki (Spain)

Ọmo bibi ilu Eko ni Ademola Razak Seriki, ti wọn bi ni oṣu Kọkanla, ọdun 1959.

O ti sisẹ gẹgẹ bi olukọ, oníṣòwò, oluṣiro owo, alamojuto ilu, ati oloṣelu.

O kawe gboye ninu iṣiro owó, eto inawo ati isakoso nilu New York lorilẹ-ede America.

Ko to o darapọ mọ ileesẹ eto ẹkọ ilu naa, gẹgẹ bi olukọ iṣiro.

Oriṣiriṣi ileesẹ lo ba sisẹ nilẹ okeere ko to o pada si orilẹ-ede Naijiria.

Wọn yan-an sipo Alaga igbimọ ere idaraya nipinlẹ Eko laarin ọdun 1992 si 1994.

Bakan naa ni wọn run yàn án gẹgẹ bi Minisita fun ọrọ abẹle laarin ọdun 2009 si 2010, lẹyin to jẹ Minisita eto aabo lọdun 2008 si 2009.

Oun kan naa ni Minisita fun iwakusa laarin oṣu Kẹwaa, ọdun 2008 si oṣu Kejila, ọdun 2008 bakan naa.

Àkọlé fídíò, Joe Biden Innauguration: Tani ìyàwó Joe Biden tí yóò jẹ obìnrin akọ̀kọ nílẹ̀ Amẹrika?

Sarafadeen Tunji Isola (United Kingdom):

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 1960 ni wọn bi Alhaji Sarafadeen Tunji Isola.

O kawe gboye Diploma nile ẹ̀kọ́ Chartered Institute of Marketing, London.

O bẹrẹ olukọ ni ile ẹkọ Federal College of Education, nipinlẹ Katsina lọdun 1983.

Lọdun 1997 si 1998, o jẹ alaga ijọba ibilẹ Ariwa Abeokuta nipinlẹ Ogun.

O tun sisẹ gẹgẹ bi oluranlọwọ pataki fún Minisita kejì fun eto inawo lọdun 1999 si 2003.

Lẹyin naa lo di Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun lọdun 2003 si 2007.

Àkọlé fídíò, America Inauguration Joe: Wo àwọn eré orí ìtàgé tí Donald Trump ṣe kó tó fi ipò aàrẹ sílẹ̀

Debo Adesina (Togo):

Oniroyin ni Debo Adesina, o si ti sisẹ gẹgẹ bi Olootu iroyin ni ipele oriṣiriṣi nileesẹ iwe iroyin The Guardian.

Ọdun 1988 lo darapọ mọ ileesẹ naa gẹgẹ bi akọroyin.

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé

Kayode Laro (France)

Ọga Agba ni ọfiisi Minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni Kayode Laro saaju iyansipo rẹ gẹgẹ bi Asoju Naijiria ni Atlanta lọdun 2017.

O kawe gboye nipa agbegbe ati eto ilu ni Fasiti Ahmadu Bello nilu Zaria, nipinlẹ Kaduna lọdun 1980, ati United Nations Institute for Development, Senegal.

Oun ni aṣoju orilẹ-ede Naijiria ni Atlanta lọdun 2017. Ṣugbọn ṣaaju asiko yii, ipo Oludari lo wa ni ọfiisi Minisita Naijiria fun ilẹ okeere.

Adejare Bello (Mexico)

Adejare Bello ti fi igba kan jẹ olori ile aṣofin ipinlẹ Osun.

Wọn bi ni ọdun 1961 nilu Ẹdẹ nipinlẹ naa.

Ẹ̀kọ́ imọ nipa ofin ni Bello kọ ni Fasiti Obafemi Awolowo, Ile-Ife lọdun 1994.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

Awọn to ku ni:

Dr Uzoma Emenike (United States)

Ambassador Tijani Muhammmad-Bande (UN)

Adeyinka Asekun (Canada)

Yahaya Lawal (Saudi Arabia)

Ibrahim Kayode Laaro (France)

Modupe Irele (Hungary)

Adejare Bello

Oríṣun àwòrán, @Adejare Bello

Eniola Ajayi (The Hague, Netherlands)

Julius Adebowale Adeshina (Togo)

Oma Djebah (Thailand)

Ademola Seriki (Spain)

Umar Sulieman (DRC)

Kevin Peter (Czech Republic)

John Usanga (Guinea Bissau)

Elejah Onyeagba (Burundi)

Philip Ikurusi (Argentina)

Tarzoor Terhemen (Namibia)

Paul Adikwu (The Vatican, Italy)

Al-Bishir Al-Hussain (Morocco)

Monique Ekpong (Angola)

Ominyi Eze (Zambia)

Yamah Musa (Mozambique)

C. O Ugwu (Poland)

Hajara Salim (Malaysia)

Obiezu Chinyerem (Ireland)

Ali Magashi (South Korea)

M. A Markarfi (Brazil)

Hamisu Takalmawa (Tanzania)

Sarafa Ishola

Oríṣun àwòrán, @Sarafa

Jazuli Gadalanci (Kuwait)

Sadiya Nuhu (Romania)

Olorundare Sunday Awoniyi (Venezuela)

Abioye Bello (Pakistan)

Zara Umar (Malawi)

Henry Omaku (Sierra Leone)

Àkọlé fídíò, Akomolede BBC: Onírurú gbólóhùn léde Yorùbá àti irúfẹ́ gbolóhùn tó wà nínú èdè Yorùbá

Sarafa Isola (United Kingdom)

Opunimi Akinkube (Greece)

Adejaba Bello (Mexico)

Adeshina Alege (Ukraine)

Folakemi Akinyele (Philippines)

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí

Abdullahi Yibaikwal Shehu (Russia)

Maureen Tamuno (Jamaica)

Faruk Yabo (Jordan)

Adamu Hassan (Vietnam)

Abubakar Moriki (Japan)