Makinde vs APC in Oyo: Makinde ní alátakò tó bá fẹ́ mọ iyì òun nígboro, APC fárígá pé ẹ̀tàn ló fi ń ṣe ìjọba rẹ̀

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi makinde

Ọrọ ti di gbas-gbos laarin gomina Seyi Makinde ati ẹgbẹ alatako to lamilaaka ju nipinlẹ Ọyọ, iyẹn ẹgbẹ oṣelu APC lori itẹwọgba rẹ laarin awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.

Gomina Makinde ṣalaye ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pe gbọgbọrọ bayii ni oun fi ju awọn alatako oun to n fi ẹnu ẹgan sọrọ oun.

Makinde ni oun to da oun loju pe lọwọ yii wọn n gbadun oun nigboro, koda oun ṣetan lati kọwọrin pẹlu awọn eeeyan to pe ni ẹlẹgan ati alatako oun ni igboro lati mọ ẹni ti araalu n fẹ ninu oun ati wọn.

"Laarin ọdun kan abọ ti mo ti fi wa lẹnu iṣejọba, mo mọ pe awọn ẹlẹnu ẹgan yoo wa,

Sugbọn mo gbọdọ gbe oju mi le afojusun mi.

Nitori naa mo ti pinnu lọkan mi pe emi ati awọn eeyan bẹl o ni jọ ṣere ẹlẹdẹ ninu ẹrẹ. Inu mi dun pe awọn eeyan n gba ti wa nigboro."

"Bi wọn ba lawọn o ni gbọ, mo fẹ ki wọn jẹ ka js kọwọrin ni igboro Oje ka wa wo awọlumatẹ ninu wa"

Àkọlé fídíò, BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020

Amọṣa, ẹgbẹ oṣelu APC ti da gomina Makinde lohun pe ko ye tan ara rẹ.

Ninu atẹjade kan to fi sita, APC si ti ko ba han si gomina Makinde, awọn eeyan ipinlẹ naa ko ri tirẹ ro mọ nitori ohun ti wọn pe ni aikun oju iwọn rẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí

Wọn ni: "Ohun to le buru jai ni ki gomina ti wọn ti dibo yan lọdun meji sẹyin ṣi maa jo ijo iṣẹgun kiri dipo ko joko ṣe iṣẹ ti ilu dibo yan an fun."

"APC ni idahun awọn si ipenija ta lo gbayi ju ti gomina Makinde n gbe kalẹ ni lati bii leere pe "ki lohun to ti gbe goke kuro nipo to baa lati ogun oṣu to ti wa nipo gomina."