Coronavirus pandemic: Kàféèfì! ''Ice cream'' lùgbàdì kó àrùn covid-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati igba ti arun coronavirus ti bẹ silẹ kaakiri agbaye, ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan lo ti lugbadi arun naa.
Eeyan nikan ni a mọ pe arun naa n mu, a ko tii gbọ pe o mu ẹranko.
Ṣugbọn ohun to jẹ kayeefi ni pe iroyin kan lati orilẹede China sọ pe ''ice cream'' fun lila ti lugbadi coronavirus.
- Èèyàn 1444 ló tún kó coronavirus lórílẹ́èdè Nàijíríà lọ́jọ́ Àìkú
- Kíni ó ṣẹlẹ̀ ní '2020 Lekki shooting' gangan?
- Sunday Igboho fún Fulani Oyo ní gbèǹdéke, Seriki fulani yarí, ọlọ́pàá dá síi...
- Àbámọ̀ ni yóò gbẹ̀yin ẹgbẹ́ ''Association of Stingy Men'' tí kò fẹ́ náwó f'óbìnrin- Akeugbagold
- Ẹ ṣọ́ra o, ayédèrú abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19 gbòde ní Nàìjíríà, NAFDAC pariwo síta
- Dókítà 66 síṣẹ́ abẹ fún ìbejì tó lẹ̀pọ̀ nílé ìwòsàn fasiti Ilorin
Iroyin naa sọ pe ayẹwo ti wọn ṣe nigba mẹta fihan pe ''ice cream'' naa ni arun covid-19 lara.
Ajọ Tianjin to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede China ti bẹrẹ si ni wa awọn eeyan to ti fọwọ kan ''ice cream'' naa ti ileeṣẹ ounjẹ Tianjin Daqiaodao ṣe.
Gbogbo ounjẹ ti ileeṣẹ naa ṣe jade ni ijọba ti fi ote le bayii lati igba ti iroyin ''ice cream'' to lugbadi covid-19 ti jade.
Dokita Stephen Griffin to jẹ onimọ nipa awọn kokoro arun ni fasiti Leeds sọ fawọn akọroyin pe ko si ifoya lori bo ya covid-19 le maa gba ibẹ ran kaakiri.
Dokita Griffin ṣalaye pe o ṣeeṣe ko jẹ wi pe ara eeyan kan ni arun ọhun ti ran mọ ''ice cream.''
Onimọ nipa kokoro arun naa sọ pe bo ya nitori ibi to tutu ti wọn ko ''ice cream'' naa si lo jẹ ki kokoro coronavirus si wa laaye di igba ti wọn ṣe ayẹwo.
Amọ, o sọ pe ko si ewu lọri iṣẹlẹ naa, ati pe iti ọgẹdẹ lọrọ naa, ko too yọ ada si.
Ni bayii, 1,662 awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to ṣe ''ice cream'' naa sita ti wa ni iyasọtọ.
Ijọba China ṣalaye pe 4,836 ''ice cream'' naa ni ileeṣẹ ọhun ṣe sita, amọ 2,089 ninu rẹ ni wọn ti so pa bayii.
- Wo àwọn ìṣesí ojoojúmọ́ mẹ́wàá tó le ṣàkóbá fún ọpọlọ rẹ
- Opral Benson, ẹni ti oge ṣíṣe sọ di gbajúmọ̀ àti Yeye Oge ìlú Eko
- Ọjọ́ orí wo ló yẹ kí ikùn ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí tóbi?
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlà lọ́sẹ̀ tó kọjá tó fi mọ́ bí Covid-19 ṣe gbẹ̀mí èèyàn 23 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Àbámọ̀ ni yóò gbẹ̀yin ẹgbẹ́ ''Association of Stingy Men'' tí kò fẹ́ náwó f'óbìnrin- Akeugbagold















