Past week events: Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlà lọ́sẹ̀ tó kọjá tó fi mọ́ bí Covid-19 ṣe gbẹ̀mí èèyàn 23 lọ́jọ́ kan ṣoṣo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
A o ni rin arin fẹsẹ ṣi lagbara Edumare. Idi abajọi adura yii ni pe awọn iṣẹlẹ to lami laaka kan ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii ni Naijiria.
Wọnyii ni diẹ lara awọn iṣẹlẹ ọhun to waye kaakiri orilẹede Naijiria.
Lara awọn iṣẹlẹ ọhun ni ijinigbe awọn oniṣowo ohun ti ẹnu n jẹ loju ọna wọn si ilu Aba nipinlẹ Abia.
- Ẹ ṣọ́ra o, ayédèrú abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19 gbòde ní Nàìjíríà, NAFDAC pariwo síta
- Dókítà 66 síṣẹ́ abẹ fún ìbejì tó lẹ̀pọ̀ nílé ìwòsàn fasiti Ilorin
- Àwọn agbébọn tó ń gba ojúgbó wọlé máa ń tó 1000 lẹ́ẹ̀kan náà - Amotekun
- Mo ti ní ìyàwó àfẹ́sọ́nà, ayẹyẹ ìgbeyàwó mi ń bọ̀ láìpẹ́ - Lateef Adedimeji
- Gomina Sanwo-Olu sún ọjọ "ṣiṣẹ lati ile" síwájú fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba
- Èèyàn 1,598 míì tún ti lùgbàdì covid-19 ní Nàijíríà, 1,420 ló ti kú báyìí
Awọn ajinigbe agbebọn ji awọn oniṣowo 27 lọna ajo wọn lati Kano si Aba
Lati ilu Kano lawọn oniṣowo naa ti n bọ ki awọn agbebọn ajinigbe naa to dawọn lọna.

Oríṣun àwòrán, OTHER
Lorun ọjọ Aiku ọsẹ to lọ lawọn oniṣowo naa fi ilu Kano silẹ lọ Aba ni ireti lati pada si kano lẹyin ti wọn ba ra ọja tan.
Ẹgbẹ awọn ọdọ oniṣowo ninu ọja aringbungbun Kano ṣalaye pe taya ọkọ tawọn eeyan naa wa ninu rẹ lawọn ajinigbe ọhun dabọn bo.
Lẹyin naa lawọn agbebọn ọhun ji gbogbo wọn gbe lọ.

Oríṣun àwòrán, TWITTER/@CHIKWE_I
Coronavirus ṣekupa eeyan mẹtalelogun(23) lọjọ kan ṣoṣo ni Naijiria
Ajọ NCDC to n gbogun ti ajakalẹ arun ni naijiria kede l'Ọjọbọ ọjọ kẹrinla oṣu kinni ọdun yii pe eeyan mẹtalelogun ni arun covid-19 gbẹmi wọn lọjọ naa.
Ajọ NCDC fi lede loju opo Twitter rẹ pe eeyan 1,479 lo ko arun ọhun l'Ọjọbọ kan naa.
Eeyan 1,275 lo jajabọ lọwọ coronavirus lọjọ naa ti wọn si gba ile wọn lọ.
Eeyan 697 ninu awọn to ko arun covid-19 lọjọ naa lo wa lati ipinlẹ Eko nikan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iranti ọjọ tawọn ologun pa Olootu ijọba Naijiria akọkọ Tafawa Balewa ati Sardauna ilu Sokoto
Ọjọ Ẹti ọjọ kẹẹdogun oṣu kinni ọdun 2021 yii lo pe ọdun marunlelaadọta ti awọn ologun ṣekupa Olootu ijọba Naijiria akọkọ, Alhaji Tafawa Balewa ati Sardauna ilu Sokoto, Ahmadu Bello.
Awọn mejeeji wa lara awọn ajijagbara fun ominira orilẹede Naijiria.
Balewa ni o jẹ olootu ijọba Naijiria lẹyin ti Naijiria gba ominiran tan lọdun 1960 nigba ti Bello si jẹ olori ijọba apa Ariwa Naijiria ki wọn to pa wọn lọjọ kẹẹdogun, oṣu kinni, ọdun 1966.
Awọn Naijiria si n ṣe iranti iṣẹ ribi ribi ti wọn ṣe fun ilọsiwaju orilẹede yii.

Oríṣun àwòrán, @NGRPRESIDENT
Buhari kede ṣiṣi ibode ori ilẹ Naijiria pada
Lọsẹ to lọ yii naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari kede ṣiṣi ibode oriilẹ Naijiria pada lẹyin to ti wa ni titi pa fun ọdun kan.
Laarin oṣu to lọ ni Aarẹ Buhari paṣẹ ṣiṣi ibode mẹrin ki gbogbo ibode to di ṣiṣi pada bayii.
Ninu oṣu kẹjọ ọdun 2019 ni ijọba gbe awọn ibode Naijiria ti pa lati dẹkun ṣisẹ fayawọ ireṣi ati ohun elo ijagun wọ Naijiria.
Ọga agba ajọ aṣọbode, Muhammad Babandede lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC pe Buhari ti paṣẹ ṣiṣi ibode oriilẹ pada.














