Lateef Adedimeji: Adebimpe Oyebade kọ́ ni àfẹ́sọ́nà mi, ọ̀rẹ́ lásán la jẹ́

Oríṣun àwòrán, Instagram/adedimeji lateef
Gbajugbaja oṣerekunrin, Lateef Adedimeji ti papa sọrọ nipa ajọṣepọ to wa laarin oun ati akẹẹgbẹ rẹ obinrin ninu isẹ tiata, Adebimpe Oyebade.
Kii ṣe ẹẹkan, tabi ẹẹmeji ni iroyin ti jade nipa wọn pe awọn mejeeji n fẹ ara wọn.
Nibi oṣu melo kan ni awọn aworan kan jade sori ayelujara, eyi to ṣafihan rẹ pe awọn mejeeji sẹ igbeyawo.
- Ẹ wo nkan tí àwọn akẹẹgbẹ́ Lateef Adedimeji sọ nípa f'ọ́tò ìgbéyàwó òun àti Adebimpe tó jáde
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Adedimeji?
- Sinimá tí Lateef Adedimeji dá nikan jẹ́ òṣèré yóò jáde, Yemi Solade fi ọ̀pọ̀ fọ́tò "dẹngẹ pó" lọ́jọ́ ìbí rẹ̀
- Ọ̀pọ̀ nǹkan tí kò yé èmi àti Bàbá Wande, ló fa ìjà lórí sinimá Tolúwa Nilẹ̀ - Tunde Kelani
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Adedimeji?
- Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, tó bá rí nkan tó n wa lára obìnrin, yóò yí ìwà padà - Bimpe Oyebade
- Ẹ wo nkan tí àwọn akẹẹgbẹ́ Lateef Adedimeji sọ nípa f'ọ́tò ìgbéyàwó òun àti Adebimpe tó jáde
Sugbọn, Lateef Adedimeji lasiko to n sọrọ lori eto kan lori tẹlifisan TVC sọ pe, ileeṣẹ kan ni awọn fi awọn aworan naa polowo ọja fun.
Bakan naa ni Adebimpe naa sọrọ nipa ajọsepọ oun ati Lateef ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba laipẹ yii.
Awọn mejeeji sọ pe ọrẹ timọtimọ ni awọn, ti ko si si ọrọ ifẹ laarin awọn.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Adedimeji tẹsiwaju pe, lootọ ni oun ni afẹsọna, ati pe laipẹ yii ni ayẹyẹ igbeyawo oun yoo waye.
O ni o pẹ ki oun to fẹ iyawo sile nitori pe igbesẹ to gba ọgbọn ni, fun ẹni to ba jẹ oṣere, ko ma ba ṣe igbeyawo ti yoo pana ogo isẹ rẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa lo tun ti sọ pe, bi ere ṣise oun ati Odunlade Adekola ṣe jọ ara wọn jẹ iṣoro fun oun nigba ti oun ṣẹṣẹ bẹrẹ ere ṣiṣe.

Oríṣun àwòrán, Instagram/adedimejilateef
O ni tako nkan ti awọn eeyan ma n sọ pe oun ma n ṣere bi Odunlade Adekola, Adedimeji sọ pe eyi gan-an lo jẹ wahala fun oun nigba ti oun ṣẹṣẹ bẹrẹ ere ṣiṣe.
O ni "Nitori pe lọpọ igba ti wọn ba fẹ ẹ pe oun, Adekola ni wọn kọkọ ma n pe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn agbébọn tó ń gba ojúgbó wọlé máa ń tó 1000 lẹ́ẹ̀kan náà - Amotekun
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún míì tí kò bá ti sọ Nàíjíríà sínú ogun abẹ́lé kejì
- Ọlọ́pàá kò fẹ́ yìnbọn, kó má ba à ba aráàlú, l‘àwọn afurasí olóògùn olóró ba sá mọ́ wọn lọ́wọ́
- Ẹ má ṣùn àṣùnpiyè o! Àwọn àjèjì darandaran ń wọ ìpínlẹ̀ Oyo àti Ogun lọ́gọ́ọ̀rọ̀ - Amotekun
- Covid-19 pa Ọlọ́lá Akin Olugbade, ẹ wo dúkìá jaburata tó fisílẹ̀
- NCDC àti NYSC bẹ̀rẹ̀ ìpàdé lórí ṣíṣí ìpàgọ́ àwọn àgùnbánirọ̀
- Ìjọba ìpińlẹ̀ Kwara dá owó tí àwọn obìrin 25 fi kọ́ ilé Ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ wọ́n pada
- Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ kí ilé-ẹ̀kọ́ wọlé ní ọjọ́ 18, oṣù kíní ọdún.
Eyi lo mu mi tun ero ara mi pa. Ọpọ igba ni mo ma n wo Adekola, lati kiyesi bo ṣe n ṣere, ki emi le gba ọna mii ti ko jọ tiẹ yọ."

Oríṣun àwòrán, Instagram/adedimeji lateef
Ẹwẹ, nigba ti wọn beere lọwọ rẹ pe, bawo lo ṣe n mojuto iṣẹ, ti ko fi pa irinajo ifẹ rẹ lara, Lateef Adedimeji sọ pe, ko si ẹni kankan ti kii ṣe ẹlẹṣẹ. Ṣugbọn, eeyan gbọdọ kiyesara.
"Ko si oṣere to ma a sọ pe oun ko se aṣiṣe ri ."
O ni oun naa ti se aṣiṣe, ṣugbọn oun ati ololufẹ oun ma n bẹ ara awọn.
Lakotan, o sọ pe ẹni ti oun n fẹ kii ṣe oṣere, ṣugbọn o mọ pe ere ni oun n ṣe , kii ṣe pe oun n fẹ obinrin ti ọrọ ifẹ ba jọ dawọn pọ ninu ere.

















