Kwara: Dókítà 66 ló síṣẹ́ abẹ fún àwọn ìbejì tó lẹ̀pọ̀ ní ilé ìwòsàn fasiti Ilorin

Kwara: Dókítà 66 ló síṣẹ́ abẹ fún àwọn ìbejì tó lẹ̀pọ̀ ní ilé ìwòdan fasiti Ilorin

Oríṣun àwòrán, UITH

Fásitì ìkọni nílùú Ilorin (UITH) ti kede fún gbogbo àye ni Ọjọ́bọ bi wọ́n ṣe ṣe aṣeyọri iṣẹ́ abẹ fún àwọn ibejì tí wọ́n lẹpọ wá sáyé.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ Gíwá ilé ìwosan náà ọjọ̀gbọ́n Abdaullah Yussuf fí aṣeyọri náà sọri ìṣẹ́ takuntakun àti ìfarajì àwọn dókítà mẹ́rìndíláádọ́rin tó péjú ṣe iṣẹ abẹ náà.

Ó ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, irinṣẹ́ tó wà nínú ilé ìwòsan náà ko kójú òsùwọn tó síbẹ̀ wọ́n ṣe aṣeyọri.

Ọjọ̀gbọ́n náà ní ìdí tí ọ̀pọ̀ fi má a ń sá lọ si òkè okun fún ìtọ́ju àti àwọn iṣk abẹ́ báyìí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn irinṣẹ tó wà ni Nàìjíríà ló ti gbó.

Giwa UITH fi kún pé, oníruuru ẹ̀ka ìṣègùn mẹ́rìndílógún ni àwọn ti sa àwọn dókítà tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà jọ láti ṣe aṣeyọri

" Nígbà tí wọ́n gbé àwọn ọmọ náà dé, à kò tilẹ̀ kọ́kọ́ mọ ibi ti wan ti lẹ̀pọ̀ ni pàtó, A kàn gbiyanju láti ṣeranwọ ní, nítori ko si irinṣẹ́ tó yẹ."

Bákan náà ni wọ́n dúpẹ lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ṣe ìrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ náà ṣeese pàápà'jùlọ nípa pípèsè owó tí sì fún ọ̀pọ̀ ní ìwúrí láti ṣe iṣẹ́ abẹ náà

Kwara: Dókítà 66 ló síṣẹ́ abẹ fún àwọn ìbejì tó lẹ̀pọ̀ ní ilé ìwòdan fasiti Ilorin

Oríṣun àwòrán, UITH