Inter-family marriage: Wo oríṣìí àrùn márùn ún tí ìgbéyàwó láàrin ìbátan máa ń fà

igbeyawo

Oríṣun àwòrán, others

Igbeyawo laarin ibatan si ibatan wọpọ laarin ẹya Hausa ati Fulani ju bi ọpọ ṣe ro lọ.

Amọ, bi o ti wu ki o ri, igbeyawo laarin ọmọ tẹgbọn taburo fun apẹẹrẹ maa n jẹ ki ibaṣepọ to dan mọran wa laarin ẹbi.

Ṣugbọn awọn dokita oniṣegun oyinbo sọ pe, ewu maa n wa ninu irufẹ igbeyawo bẹẹ nigba mii gẹgẹ bi iwadii tawọn onisayẹnsi ṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Dokita Ibrahim Musa ti ile iwosan ẹkọṣẹ ogun ni ilu kano to jẹ akọṣẹ-mọṣẹ nipa ṣisẹ iwadii lori ẹjẹ ati aarun inu ẹjẹ sọ pe, igbeyawo laarin ibatan ni ewu kiko arun lati ara awọn obi ninu.

Gẹgẹ bi iwadii ti awọn onimọ sayẹnsi ṣe, Dokita Musa ni wọnyii ni awọn arun ti igbeyawo laarin ibatan le fa.

Àkọlé fídíò, Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú

Arun foniku-fọlande:

Dokita Musa ni arun kan to wọ pọ ninu awọn arun ti igbeyawo laarin ẹbi maa n fa, ni arun foniku-fọlande, taa mọ si sickle cell.

O ni awọn obi maa n ṣaa ba ni iru iṣọri ẹjẹ kan naa tawọn oloyinbo n pe ni ''genotype.''

Dokita naa ṣalaye pe iru arun yii yoo maa ran lọ ni ti awọn ọmọ tẹgbọn taburo to ba ni iru ẹjẹ bẹẹ ba si n fẹ ara wọn.

Dokita fikun ọrọ rẹ pe, awọn arun ajogunba kan tiẹ wa ti igbeyawo laarin ibatan maa n fa, eleyi tawọn ẹbi gan an kii ṣaba mọ.

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ

Arun ajogunba:

Iwe iroyin Lancet Health Magazine lọdun 2013 ṣalaye pe, arun inu ẹjẹ obi le ṣakoba fun awọn ọmọ ti wọn ba bi.

Fun apẹẹrẹ, obinrin to fẹ ọkunrin ibatan rẹ, o ṣeeṣe ki awọn ọmọ to ba bi ni iru arun to wa lara awọn obi ọkunrin naa.

Iṣẹ iwadii awọn onimọ iṣegun fidi rẹ mulẹ pe, wahala arun maa n ṣẹlẹ nigba ti igbeyawo ba waye laarin ọmọ tẹgbọn taburo.

Iṣẹ iwadii naa ṣalaye pe, awọn ọmọ to ba jade lati inu igbeyawo ibatan si ibatan papaa julọ, tawọn obi wọn ba jogun arun kan tabi omiran lara awọn obi tiwọn naa.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

Bibi akanda ọmọ:

Ajọ eleto ilera NHS sọ pe, iṣoro arun ajogunba wa kaakiri ni gbogbo awujọ lagbaaye.

Ṣugbọn ajọ naa ni bibi akanda ọmọ ṣa baa wọ pọ laarin igbeyawo ibatan si ibatan.

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Iwadii ajọ NHS tun fihan pe, igbeyawo laarin ẹbi wọpọ laarin awọn ọmọ orilẹede Pakistan to n gbe ni UK.

Iṣẹ iwadii ọhun fidi rẹ mulẹ pe, ọpọ iru igbeyawo bẹẹ ni o ṣeeṣe ki wọn bi ọmọ to ni ipenija ara.

Dokita Musa ni niwọn igba ti arun kan tabi omiran ti wa ninu ẹbi, yoo maa ran lọ ni, tawọn ọmọ iru ẹbi bẹẹ ba n fẹ ara wọn.

Àkọlé fídíò, Kí ni "Present tense" lédè Yorùbá?

Arun ọpọlọ:

Arun mii ti igbeyawo laarin ẹbi maa n fa ni arun ọpọlọ, gẹgẹ bi iwadii awọn onimọ sayẹnsi ṣe sọ.

Dokita Musa tun sọ pe, awọn arun ajogunba lo maa ṣaa ba jẹ ki oyun bajẹ lara obinrin.

Àkọlé fídíò, Itaniji: Oluwo sọ ìtàn bí Orunmila ṣe jìyà nílùú Iwo àti ayọ̀ tó gbẹ̀yìn rẹ̀ torí sùúrù

Bakan naa lo ṣalaye pe aisan ẹjẹ ruru naa tun wọ pọ ninu igbeyawo laarin ẹbi.

''Iru rẹ ṣẹlẹ laipẹ yii nijọba ibilẹ Batsari nipinlẹ Katsina, nibi ti awọn ọkunrin ati obinrin kan ti wọn jẹ ọmọ ibeji ti fẹ ara wọn. Mẹrin ninu awọn ọmọ ti wọn bi lo ni ipenija ara,'' Dokita Musa lo sọ bẹẹ.

Dokita ni awọn ọmọ naa ni ipenija oju ati imu.

Àkọlé fídíò, Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn

Arun jẹjẹrẹ oju:

Dokita Ramatu Hassan to jẹ olulanilọyẹ nipa arun jẹjẹrẹ oju ni Naijiria tẹlẹ ṣalaye fun BBC pe, igbeyawo laarin ẹbi maa n fa arun jẹjẹrẹ oju.

Dokita Hassan ni ''arun yii maa n bẹrẹ nigba ti ọmọ ba wa ni ikoko, yoo si maa gbilẹ sii bi ọmọ ṣe n dagba, nigba to ba ya ọmọ naa le ma riran mọ.''

Igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ṣalaye pe iru arun yii wọ pọ lapa ariwa orilẹede Naijiria, nibi ti iru igbeyawo bẹẹ ti wọpọ.

''Irun arun jẹjẹrẹ oju yii ti maa n mu ọmọ ti wọn tiẹ to bi sile aye nitori arun ajogunba ni,'' Dokita Hassan lo sọ bẹẹ.