America, Biden inauguration: Ohun kókó mẹ́fà tí yòó ṣẹlẹ̀ níbi ìbúra ìjọba tuntun Biden àti Harris

Joe Biden ati kamala Harris

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ori ti yoo jọba ko ni ṣai jọba. Ọni ogunjọ oṣu kinni ọdun 2021 ni wọn yoo ṣe ibura fun Joe Biden gẹgẹ tuntun orilẹede Amerika.

Oun ati igbakeji rẹ, Kamala Harris to jẹ obinrin akọkọ ninu itan ilẹ Amerika ti wọle ibo gẹgẹ bi igbakeji aarẹ Amerika ni wọn yoo bura fun un.

Biden ni yoo jẹ aarẹ ẹlẹẹkẹrindinlaadọta ti ilẹ Amerika yoo dibo yan.

Biden la Donald Trump mọle ninu idibo aarẹ orilẹede Amerika to waye laipẹ yii.

Wọnyii lawọn nkan marun un to yẹ ki o mọ nipa ayẹyẹ ifilọlẹ ijọba Biden lorilẹede Amerika:

''Iṣọkan Amerika'' lakori ayẹyẹ ifilọlẹ ijọba Biden

Iṣọkan orilẹede Amerika ni akori ayẹyẹ ibura ati ifilọlẹ ijọba Biden, eleyi n sọ nipa irinajo mii lati mu ilẹ Amerika pada sipo fun ọjọ iwaju to adara.

Igbimọ to n ri si ayẹyẹ ifilọlẹ ijọba Biden ati Harris lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Àkọlé fídíò, US Vice President:Ẹ wo ìtàn obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ igbákejì Ààrẹ ilẹ́ Amẹrika?

Niwaju igba asia Amerika ni ayẹyẹ ibura Biden yoo ti waye

Ko ni si ero nibi ayẹyẹ ifilọlẹ aarẹ tuntun orililẹede Amerika l'Ọjọru.

Igbimọ to n ri si ayẹyẹ ifilọlẹ ijọba aarẹ tuntun l'Amerika ti ri asia to din diẹ ni igba mọlẹ nibi ti ibura Biden ati Harris yoo ti waye.

Awọn asia yii ni yoo duro fawọn ẹgbẹẹdbẹrun un ọmọ ilẹ Amẹrika ti ko lanfaani lati wa nibi ayẹyẹ naa.

Àkọlé fídíò, America Inauguration Joe: Wo àwọn eré orí ìtàgé tí Donald Trump ṣe kó tó fi ipò aàrẹ sílẹ̀

Lady Gaga ni yoo kọrin ogo ilẹ Amerika

Olorin takasufe Lady Gaga ni yoo kọ orin ogo ilẹ Amerika nibi ifilọlẹ ijọba aarẹ tuntun, Biden.

Gbajugbaja olorin Jennifer Lopez ati Garth Brooks naa yoo kọrin nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ijọba Aarẹ Biden.

Akọrin ewi, Amanda Gorman, ọmọ ọdun mejilelogun yoo ka ewi sawọn eeyan leti nibi ayẹyẹ ọhun.

Biden yoo gbe ododo lọ si iboji ọmogun Amerika

Aarẹ Biden, igbakeji rẹ, Harris, aarẹ Amerika tẹlẹ, barack Obama, George W. Bush ati Bill Clinton pẹlu awọn iyawo wọn yoo gbe ododo lọ si iboji ọmogun Amerika gẹgẹ bi aṣa.

Ibi igboku si to wa ni Arlington ni wọn yoo gbe ododo ọhun lọ.

Nibẹ ni awọn ẹṣọ ologun yoo ti bẹrẹ si ni tẹle Biden.

Àkọlé fídíò, BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020

Mike Pence ni yoo wa nibi ayẹyẹ ibura kii ṣe Donald Trump

Igbakeji Aarẹ Trump ni yoo wa nibi ayẹyẹ idagbere dipo Aarẹ Trump.

Pence ni yoo gba iṣe Trump ṣe nibi ayẹyẹ ti yoo waye ọfiisi awọn ologun lolu ilu Amerika, Washington DC.

Burna boy

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orin Burna Boy wa lara orin ti wọn maa kọ nibẹ lonii:

Orin ọmọ Naijiria ni, Burna boy wa lara rin ti wọn ti to kalẹ lati lo nibi ayẹyẹ ifilọlẹ iṣejọba aarẹ tuntun ilẹ America.

Destiny ni orukọ akọle orin Burna boy naa pẹlu awọn olorin agba ọjẹ agbaye.

Orin mẹrindinlaadọta ni wọn ti ṣeto lati lo bnibẹ lonii.

Eyi ni wọn lo ṣafihan iyatọ ninu iṣọkan eyi ti ilẹ America gbagbọ ninu rẹ pe onikaluku le yatọ ninu ifẹ.

Awọn olorin b=miran ti wọn yoo lo ni Beyoncé's Find Your Way Back, Kendrick Lamar ati Mary J. Blige's Now Or Never, Bob Marley ati Di Wailers' Could You Be Loved ati Dua Lipa's Levitating.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí

Awọn orin naa ni kikun ni:

KOTA the Friend- Lupita's interlude

The Beatles - Come together

Jason Derulo - Pick up the pieces

Bruce Springsteen - We take care of our won

Daryl Hall and John Oates- You make my dreams come true

The Weeknd- What you need

Mac Miller- Blue World

Heatwave- The Groove line

A Tribe Called Quest -Award Tour

MF Doom - Coffin Nails

Free Nationals- Eternal light

Burna Boy- Destiny

Led Zeppelin- Fool in the rain

Bob Marley & The Wailers - Could You Be Loved

Curtis Mayfield -Move on Up

Jill Scott- Golden

The Impressions -We're a Winner

Dua Lipa - Levitating

The Doobie Brothers- What a Fool Believes

Bill Withers- Lovely Day

Chris Brown- Mirage

Shania Twain- Still the One

Oddisee- That's Love

Anitta, Major Lazer- Make It Hot

Whitney Houston, Kygo- Higher Love

Earth, Wind & Fire- That's the Way of the World

Vampire Weekend- Unbelievers

Beyonce- FIND YOUR WAY BACK

Jackie Wilson - (Your Love Keeps Lifting Me) Higher & Higher

SZA- Good Days

Vampire Weekend- Step