Vitamin D and your body: Èròjà Fáítámì D ṣe pàtàkì fún ara nípa dídáàbò bo àgọ́ ara

Fitami D

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Báwo ni èròjà Fáítámì D ṣe ń dáàbò bo àgọ́ arawa?

Agọ ara eniyan ni orisirisi eroja to fi n ṣe ẹṣọ.

Lara awọn eroja yiini eroja faitami (Vitamins) D wa.

Ki ni a n pe ni faitami (Vitamin) D gan?

Eroja faitami (Vitamin) D jẹ ọkan gbogi lara awon eroja aṣaralore ti agọ ara nilo lati ṣiṣẹ emi daradara.

Gẹgẹ bi orukọ, o yatọ si faitamin (vitami) A tabi awọn akẹgbẹ rẹ nitoripe oun gan an lo ma n ran aralọeọ lati peelo awọn eroja ti a mọ si 'homones' lara eniyan.

Fitami D

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nibo ni ati lee ri eroja faitami (Vitamin) D yii gba?

Oniwadi ijinlẹ kan, Chris Ohakpolamugwo ṣalaye pe awọn eeyan kan a maa woye pe oorun ni i funni ni eroja vitamin D ṣugbọn rara o ko ri bẹẹ.

O ni ooru to ba n ti ara nnkan gbogbo to ba n mu ooru ina jade lo lee fun eeyan ni eroja naa

Fitami D

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ ijinlẹ naa tun salaye siwaju si i pe "ohun to daju ni pe oorun kii fun eniyan ni eeoja vitamin yii. O ni ọna kan pataki lati rii vitamin yii ni nipa sisun daadaa, paapaajulọ ni owurọ.

Ona miran tun ni jijẹ awọn ounjẹ toṣe ara loore, ni pataki julọ awọn ounjẹ to ni"calcium' ninu.

Àkọlé fídíò, BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020

Fun Apẹẹrẹ:

*Ẹja to ni ọra lara bii ẹja salumọni, alaran ati Kote

*Ẹdọ ẹran

*Ora cheese

*Ero

*Wara miliki.

Anfani eroja Vitamins D fun agọ ara:

Ipa pataki ni eroja Vitamin D n ko ni agọ ara; ninu eyi ti a ti ri mimu ki egungun ati eyin ẹnu o gbopọn sii, didaabo bo ara lọwọ awọn kokoro arun at'awọn ohun miran to lewu fun ara.

O maa n ran ara lọwọ fun ipese egungun ati eyin ẹnu to ji pepe.

Eroja Vitamin D lo n ṣe akoso kaliṣiọmu (Calcium) ati fosiforọọsi (phosphorus) ninu ẹjẹ.

Eleyi to n fun egungun ati eyin ẹnu ni agbara.

O n dena aisan Kokoro arun oriṣiriṣi.

Apẹẹrẹ ni korona fairọọsi (Coronavirus) jẹ.

Fitami D

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iwadii kan to waye lọdun meji sẹyin (2018) fidi rẹ mulẹ pe Vitamin D n ṣe iranwọ fun ara lati gbogun ti awọn aisan bi otutu ofinkin (influenza).

Iwadii miran to tun waye laipẹ yii tun fidirẹ mulẹ pe ọpọ aisan to so rọ mọ ajakalẹ arun koronafairọọsi (Coronavirus) lo waye tori aisi alekun eroja vitamin D to kun iwọn lara.

Eyi fihan pe lona kan, Vitamin D a maa se iranwọ fun agọ ara lati gbogun ti ajakalẹ arun naa atawon arun miran to rọ mọ eemi ẹda.

Àkọlé fídíò, 'Bí aya bá kọ ọkọ rẹ̀ silẹ̀, kó wà láì lọ́kọ̀'

Iwadii ijinlẹ miran ṣi n lọ labẹnu lati lee mọ bi awọn eroja Vitamins ṣe n gbogun ti arun koronafairọọsi (Coronavirus), ṣugbọn awọn eleto ilera ti gbe imọran kalẹ pe igba otutu ni ki wọn maa lo o

Eroja vitamin D a tun maa ran ilera awọn ọmọ ikoko lọwọ nipa mimu ki wọn dagba ni ibamu pẹlu ilana to yẹ gẹgẹ bi ẹka ẹkọ nipa aboyun ati ọmọ wẹwẹ ni fasiti John'sHopkins ṣe sọ,

Riro alaboyun lagbara:

Abajade iwadii kan lati ọdọ ajọ ilera agbaye, WHO sọ pe o dara ki alaboyun maa ni ẹkunrẹrẹ gbogbo awọn fitamin gbogbo laagọ ara wọn.

Wọn ni eyi maa n mu ki ọmọ ti wọn yoo bi otobi ko si lagbara, ati pe o n dena ọmọ bibi laitoṣu.

Amoṣa wọn sekilọ pe alaboyun gbọdọ ṣọraṣe to ba n lo ogun eroja fitamin (Vitamin) D.

Fitami D

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aisi eroja fitamin (Vitamin) D ni agọ ara lee fa aisan

Iwadi ijinlẹ ti fihan pe ọpọ eeyan to laarin koronafairọọsi (Coronavirus) lara ni odinwọn eeoja faitami (Vitamins) ago ara wọn ko to nnkan.

Lootọ ni pe agọ ara a maa seto eroja gaitamin (Vitamin) D funraẹ, ṣugbọn l'ọpọigba, kiito.

Lara awọn ohun tosi lee fa eyi ni iwo ni, kikori bọ oorun l'ọpọigba ju bo ṣe yẹ lọ, ati ibi ti ẹni bẹẹ va wa ati bi wọn ṣe tọju ọmọ ikoko bẹ́ẹ

Aisi faitamin (Vitamin) D lagọ ara a maa fa aisan

*Aisan nigba gbogbo, foniku fọla dide.

Àkọlé fídíò, Divorcee: Ó sàn kí wọ́n yàgò fúnra wọn ju ki wọ́n ṣe ara wọn léṣe- Fisayo

*Irẹwẹsi, Irora inu eegun ati ẹyin riro

"Aitete san oju egbo.

*Irun rirejẹ.

*Irora inu iṣan.

Ṣe awon agba bọ wọn ni ohun gbogbo lo ni iwọntunwọnsi, bẹẹ l'awọnonimọ iṣegun naa n wi pe faitami (Vitamin) D ṣe pataki fun ara, amọṣa apọju rẹ ko sunwọn nitori a maa fa idiwọ fun lilọ bibọ ẹjẹ lologeere.

Fitami D

Oríṣun àwòrán, Getty Images