ENDSARS Tribunal: ọlọ́pàá àti olùjẹ́rìí tó gbá létí lẹ́ẹ̀mẹrin pàdé níwájú ìgbìmọ̀, ariwo sọ!

Oríṣun àwòrán, @LagosSarsPanel
O fẹ jọ ere sinima agbelewo lasiko ti olujẹri kan niwaju igbimọ to n gbẹjọ lori iwa ipa awọn ikọ ọlọpaa SARS ṣadede kọju si ọlọpaa kan to si ni o gba oun leti lẹmẹẹrin.
Ọlọpaa taa n wi yi wa lara awọn to tẹle awọn to n ṣoju ọlọpaa wa si ibi igbẹjọ igbimọ naa nilu Eko.
Arakunrin Okolieagu Abunike ṣẹṣẹ dahun ibeere tan lọwọ agbẹjọro ọlọpaa Emmanuel Eze ni.
Abunike to ni oun ni ọmọ marun un ṣalaye ninu ijẹri rẹ pe awọn ọlọpaa SARS fi oun si atimọle fọjọ mẹtadinlaadọta ni ọọfisi wọn to wa ni Ikeja lai gbe oun lọ si ile ẹjọ.
Kete to jẹri yi tan lo gba iyọnda lọdọ alaga igbimọ pe ọrọ ku ti oun fẹ sọ.

Oríṣun àwòrán, @LagosSarsPanel
Nigba ti alaga fun un laaye, lo ba kọju si ọkan lara awọn ọlọpaa to wa ni ijoko, Ọgbẹni Joseph Ebosereme pe o fiya jẹ oun lọna aitọ.
O ni ''Lọdun to kọja, agbẹjọro ọlọpaa to joko lati gbẹjọ mi loni fọ mi leti lẹẹmẹrin ni ile iṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ SCIID to wa ni Panti.
O si ni bi mo ba to bẹẹ, ki n gba temi pada''
Ninu esi rẹ, Ebosereme ni irọ gbaa ni Abunike n pa mọ oun.
''O fẹ ba mi lorukọ jẹ ni.Emi gba ọ leti?Mi o jẹ ta ara mi lọpọ''
- Olóyè Olu Falae kò tíì mú ẹjọ́ wá si àgọ́ ọlọ́pàá kankan- Agbenusọ ọlọ́pàá
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọlọ́kadà àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ibadan
- Omotara pàdánù isẹ́ olówó ńlá nítorí ó fi ọtí ẹlẹ́rìndòdò sódà lá ọmọ alágbe lójú
- Iṣu ata yáan yàan! Iṣẹ́ fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá tó gba N100k lọ́wọ́ awakọ̀ tó gba"One way" l'Eko

















