Free Pad: Scotland ti di orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ tó bẹ́rẹ̀ pínpín páàdì ǹkan osu fún gbogbo obìnrin lọ́fẹ̀ẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orílẹ̀-èdè Scotland ti di orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ to n pin ìlédìí ìkàn oṣù lọ́fẹ̀ẹ́ fún gbogbo obìnrin.
Lọ́jọ́ Iṣẹ́gun ọsẹ̀ yìí ni àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin dìbò láti gba àbá náà wọle kí ó le di òfin tí ará ìlú yóò tẹ̀lé (Free Provison Scotland)
Èyí túmọ̀ sí pé, ojúṣe ìjọba ìbílẹ̀ ni láti máa pèsè àwọn páàdì yiìí fún gbogbo ẹni to ba nílò rẹ̀."
- Ìyàwó wọ sòkòtò fún ayẹyẹ ìgbéyéwò rẹ̀, ní wáhálà bá bẹ́ sílẹ̀
- Kílódé tí Ọọni Ife, Oba Ogunwusi kò fi gbọdọ̀ rí ọmọ rẹ̀ tuntun ti Olorì Naomi bí títí di bíi ẹ̀yìn oṣù mẹ́fà?
- Ìdí rèé tí ìjọba fi ń gbèrò pé kí àwọn tó ń gba 'minimum wage' má san owó orí mọ́
- Ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè UK n gbèrò fífí ìyà jẹ àwọn adarí Naijiria tó lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn ENDSARS
Ọmọ ilé asofin lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Monica Lennon to ti jàjàjà lóri òṣì lásìkò ǹkan oṣù yìí lati ọdun 2016 sàlàyé pé àjàkálẹ̀ ààrùn Corornavirus ti sọ ọ dí dandan báyìí.
Òṣì lásìkò ǹkan oṣù máa n wáye ti àwọn ènìyàn kò bá níṣẹ́ tó n mówó jáde láti ra àwọn páàdì ǹkan oṣù tó jẹ́ ojúlówó.
Ìwádìí kan ti Young Scot ṣe fáwọ̀n akẹ́kọ̀ọ́ fi idí rẹ̀ múlẹ̀ ọkan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìn ń tiraka lati ra ìléèdí ǹkan oṣù ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọ́n ń pinnu láti máa pín àwọn ìledìí yìí, bi wọ́n ṣe máá n pín kọndọọmu fáwọn ọkùnrin nílé iwé gírámà àti ni fásitì, ilé ìwòsàn ti wọ́n bá ti ṣíṣẹ́ abẹ, àti ni àwọn ibi ti wọ́n ti n ta oogun, yálà ki wọn lọ bèrè fún tàbi ki wọ́n kọọ síwèé.
Gbogbo àgbáyé ni olúkúlùkù tí n wá ọ̀nà láti fòpin si òṣì lágbègbè wọ́n.
Ní ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì, wọ́n fun àwọn ọmọ ilé iwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ni inú oṣù kíní ọdún.
Àwọn ìpińlẹ̀ kan ni Amẹrika, naa ti sọọ di ofin pe ki wọ́n maa fun awọn akẹ́kọ̀ọ́ ni iléèdi nkan oṣù lọ́fẹ̀ẹ́.
Kódà, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti darapọ̀ mọ́ àwọn kan lágbàyé, bi wọn ṣe yọ owó orí kúrò nínú àwọn èròjà ǹkan osu.
Orílẹ̀-èdè bí Kenya, Canada, Australia, India, Colombia, Malayhsia, Nicaragua, Jamaica, Uganda, Lebanon àti Trinidad & Tobego náà ti yọwó orí nínú ìléèdí obìnrin


















