Nigeria Tax Exemption: Ìjọba àpapọ̀ kéde pé òun ń fẹ́ fi òpin sí bí àwọn tó ń gba owó oṣù tó kéré jùlọ ṣe ń san owó orí

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency Nigeria/twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Iroyin ayọ lo jẹ fun awọn oṣiṣẹ to n gba owo oṣu to kere julọ ni Naijiria, pẹlu bi ijọba apapọ ṣe kede pe, wọn ko ni ma a san owo ori lori owo oṣu wọn mọ.

Ọjọ Aje ni ileeṣẹ aarẹ kede iroyin yii loju opo ibaraẹnidọrẹ Twitter rẹ.

Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pe igbesẹ naa jẹ ọkan lara ọna ti ijọba fẹ ẹ fi mu ọrọ aje Naijiria pada bọ sipo.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ni "erongba yii jẹ ọkan lara awọn aba ofin eto ẹnawo to wa niwaju ile igbimọ aṣofin".

Buhari sọ pe "ilana tuntun naa jẹ ọna lati pari eto itura to sẹ fun awọn olokoowo kekeeke, to bẹrẹ ni ọdun to kọja.

"Eyi jẹ ọna lati fi ẹsẹ eto ọrọ aje mulẹ, nipa mimu adinku ba inira owo ọkọ, ati ọwọn gogo , ni lara awọn ọmọ Naijiria."

Ati pe eredi ti ijọba fi mu adinku ba owo ori ọkọ, ati awọn ọkọ eero, ni lati mu ki owo ti awọn awakọ n gba lọwọ ero dinku.

O ṣalaye pe bi ijọba ṣe fi opin si sisan owo iranwọ ori eporọbi 'subsidy', ati bi iye ti wọn n ta lita epo ṣe lọ soke si, n ni ipa lara iye ti araalu n ra ounjẹ.

Àkọlé fídíò, Waste to Wealth: Ẹ̀gbin tìrẹ ni èròjà táwọn èèyàn míràn fi n ṣiṣẹ́ ajé, okoòwò ńlá ni

Yatọ si eyi, ileeṣẹ aarẹ sọ pe ijọba n ṣiṣẹ pọ pẹlu banki apapọ, ati ileeṣẹ to n mojuto awọn idokowo ijọba, NSIA, to fi mọ awọn ijọba ipinlẹ, lati ṣeto bilisnu mẹẹdogun Naira.

Miliọnu mẹẹdogun Naira naa "yoo ṣe iranlọwọ lori ipese awọn nkan amayedẹrun.

"Yoo si tun duro gẹgẹ bi ipilẹ to dara fun idagbasoke ọrọ aje Naijiria."

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí