Burna Boy Twice as Tall: Ǹkan tí ó yẹ ki o mọ̀ nípa Damini Ebunoluwa Ogulu Rex (Burna Boy) ti orin rẹ̀ lu ìgboro pa báyìí

Ǹkan tí ó yẹ ki o mọ̀ nípa Damini Ebunoluwa Ogulu Rex (Burna Boy) ti orin rẹ̀ lu ìgboro pa báyìí

Oríṣun àwòrán, Burna Boygram

Bí ilẹ̀ ṣe mọ́ lónì ni òkìkí kan lórí ayélujára pé Burna Boy bi ọmọ tuntun.

Ayọ̀ abara tíntín, àwo orin tuntun ni ọmọ ti Burna Boy bí, bí àwọn olólùfẹ́ rẹ ṣe ń ki náà ni àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ náà ń kíi kú oríire.

Sùgbọ́n, Tani Burna Boy?

Damini Ebunoluwa Ogulu Rex tí gbogbo ènìyàn mọ si Burna Boy ni a bí ni ìlú Port Harcourt ni ọjọ́ kejì, oṣù keje, ọdún 1991.

Bàbá rẹ̀ jẹ́ òṣìṣẹ ilé iṣẹ́ jórin-jórín, nígbà ti ìyá rẹ̀ Bose Ogulu jẹ́ ń ṣe iṣẹ́ ògbífọ̀.

Burna Boy dàgbà sí ìhà ìlà-oorun Gúúsù Nàìjíríà tí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin ti o pè ni Fruity Loops.

Ìyá rẹ̀ ló dúro gẹ́gẹ́ bí olùdàrí iṣẹ́ orin to yàn láàyò.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Ó lọ sí ilé ìwé girama Corona ní Agbara, láti ibẹ̀ ló gbà lọ sí ìlú ọba níbi tó ti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Ebunoluwa lọ́ si fásitì Sussex láti kan Media Technology, lẹ́yìn náà ló tú lọ sí fásitì Oxford Brooks nibi tó ti ka Media Communication àti Culture.

Àkójọpọ̀ orin àkọ́kọ́ tí Burna Boy gbé jáde ní ilé ìporin pọ̀ ni o pe àkọ́lé rẹ̀ ni L.I.F.E , ó jáde ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹjọ, ọdún 2013, sùgbọ́n o ti kọ́kọ́ gbé àwo kan jáde to pe àkọle rẹ̀ ni Mixtape Burn Identity.

Àkọ́jọpọ̀ to gbé jade náà ta ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì lọ́jọ ti ó kọ́kọ́ jáde.

Nínú agbo olórín lórílẹ̀ -èdè Nàìjíríà lọ́nìí àkjọ́jọpọ orin náà ni ó wà ní ipò kẹwàá tí o si pe àwọn olórin bi 2face Idibia, M.I Timaya, Olamide, Reminisce àti Wizkid.

Orin Fela Kuti ló pọ̀ nínú àkojọpọ̀ orin Burna Boy tí wọ́n si dibo pé ki o gba àmì ẹ̀yẹ lọ́dun 2014

Ti se akójọpọ̀ awo orin to le ni mẹ́jọ, yàtọ̀ sí àwọn orín ẹlẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, àti àwọn eyi to darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn láti kọ.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí

Àwọn àmìn ẹ̀yẹ ti Burna Boy ti gbà

Burna Boy ti gba àmì ẹ̀yẹ tó le ni ogún ti wọ́n sì ti yàn-án fún ọ̀kẹ́ àìmọye omíràn ti kò kẹ́sẹjárí.

Ayẹyẹ Àmì ẹ̀yẹ tó jẹ́

Àkọlé fídíò, jkkkkk