Jemila dáná sún ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin tó bá nílé

Jemila dáná sún ilẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin tó bá nílé

Oríṣun àwòrán, Lagos Police Command

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Eko tí mú obìnrin ẹni ọdún mọ́kàndílógún kan tó dána sun ilé ọ̀rẹ́kùnrin tó n fẹ́ tẹ́lẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tó bá nílé.

Ọmọbinrin náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jemila Ibrahim àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Fatima Mohammed ẹni ọdún mọ́kànlélógún lágbègbè Monkey village, Festac nílù Eko.

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀gá agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Eko Muyiwa Adejobi ṣe sọ, ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáye ni ọjọ́rú, ọjọ́kejìdínlogún, oṣù kọkànlá ọdún yìí.

Jemila dáná sún ilẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin tó bá nílé

Oríṣun àwòrán, Lagos Police Command

Ó sàlàyé pé ni kété ti Mohammed gbọ́ nípa ǹkan ti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ nígbà kan ri Jemila fẹ́ ṣe ló sáre lọ si ilé rẹ̀, sùgban ẹ̀pa kò bóró mọ́ nígbà ti yóò fi débẹ̀, ilé rẹ̀ ti múná.

Mohammed gbìyànjú láti dóòlà, ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, Rabi nínú iná náà tó sì gbe lọ si ilé ìwòsàn, nibi tó ti pada pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ sátide, ọjọ́kọkànlélógún, ọdún 2021.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Adejobi fi kún pé, kọ́mìsọ́nà ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ Eko, Hakeem Odumosu ti páá lásẹ̀ pé ki wan gbé ẹja náà lọ sí Panti fún ìwádìí tó dájú

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé