Philip Shekwo: Aága ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Nasarawa tí àwọn agbébọn jí gbé ti kú

Philip Shekwo

Oríṣun àwòrán, Other

Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC, nipinlẹ Nasarawa, Philip Shekwo ti ku.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Nasarawa ti fidirẹmulẹ fun BBC pe o ku lẹyin ti awọn agbebọn ji i gbe lọjọ Satide.

Agbẹnusọ fun awọn ọlọpaa nipinlẹ naa, ASP Rahman Nansel sọ pe wọn ti gbe oku rẹ lọ si ileewosan, nitori iwadii ṣi n tẹsiwaju.

Owurọ ọjọ Aiku ni BBC gbọ iroyin pe awọn agbebọn kan ji alaga ẹgbẹ osẹlu APC gbe.

Awọn ọlọpaa sọ pe ni nkan bi aago mọkanla, alẹ Satide ni wọn wọ inu ile rẹ, ti wọn si gbe e salọ.

Ati pe ni kiakia ni awọn lọ si ile naa, ti awọn ati awọn agbebọn naa si jọ doju ija kọ ara wọn, amọ wọn papa ri gbe lọ.

Ọjọ Aiku si ni wọn ri oku rẹ nibi ti ko jina si ile rẹ.

ASP Nansel sọ pe bi awọn ṣe jọ doju ibọn kọ ara awọn fihan pe awọn agbebọn naa pọ gan-an.

Iṣẹlẹ ijinigbe ko ṣẹṣẹ ma a waye ni apa Ariwa Naijiria, ati awọn ibomii.

Àkọlé fídíò, The New Pandemic: Kíni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì ń sọ nípa rẹ̀?