Prophet Israel Oladele: Kilo gbe e de ijọ Celestial?

Oríṣun àwòrán, Genesis Global
Idile ẹlẹsin musulumi ni wọn bi Woli Israel Oladele si. Orukọ abisọ rẹ ni Wasiu.
O si jẹ ọmọ ilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun.
Awọn obi rẹ pada di ẹlẹsin Kristiẹni, ti wọn si n lọ sinu ijọ kan ni agbegbe Oshodi nipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi akọsilẹ itan igbesi aye rẹ to wa lori ayelujara itakun agbaye ijọ naa, genesisglobal.org, idile ti ko ri ọwọ rọri lo ti wa, nitori oju owo pọn awọn obi rẹ pupọ.

Oríṣun àwòrán, Genesis global/facebook
O kiri ọja bi mọin-mọin ati burẹdi, bakan naa lo sẹ awọn iṣẹ pẹẹpẹẹpẹ lati ran awọn obi rẹ lọwọ gẹgẹ bi akọbi.
Iṣẹ ati oṣi to ba awọn obi rẹ finra ko jẹ ko lọ si ileewe tayọ ileewe girama. Koda, ko kẹkọọ pari ti ko fi lọ mọ.
- Wo bi wọ́n ṣe n ṣe àmójútó ilé ìjọsìn Prophet Israel Oladele, CCC Genesis Global
- Kà nípa ibi tí wọ́n bí Àrẹ̀mọ tuntun Ọọ̀ni Ife sí, àti orúkọ tó ń jẹ́
- Ẹ̀tanú pé Olùṣọ́ Genesis kò fẹ́ Laide Williams-Oni ló ṣe rán an lọ́ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan - CCC Genesis Global
- Taribo West wọ gàu lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà lẹ́yìn tó sọtẹ́lẹ̀ pé Trump yóò wọlé ìbò ààrẹ Amerika
Kilo gbe e de ijọ Celestial?
Itan igbesi aye Wooli Oladele Ogundipe sọ pe idile rẹ ko fẹran ijọ alaṣọ funfun, nigba to wa ni kekere.
Igbagbọ wọn ni pe awọn to n lọ si awọn ijọ naa maa n ṣe oogun, ati awọn nkan ti ko tọ gẹgẹ bi Kristiẹni to jẹ atunbi.
Ijọ Aposteli Kristi, CAC, ni oun ati awọn obi rẹ n lọ. Iwaju ile wọn si ni ile ijọsin naa wa.
O sọ pe awọn kan riran si iya oun nigba to loyun pe ọmọ inu rẹ yoo ṣiṣẹ fun Ọlọrun, amọ iṣẹ alfa tabi imaamu ni awọn obi rẹ n fọkan si nitori ẹlẹsin Musulumi ti wọn jẹ lasiko naa.
Ṣugbọn iṣẹlẹ buruku kan waye ni ọjọ kan.
Iya Oladele jẹ ẹnikan lara awọn obinrin inu ijọ naa ni owo, ti ko si ri i san.
Ni obinrin naa ba wa sile wọn, to si pariwo le iya rẹ lori lati san owo naa.
Ibi ti ariwo ti n waye ni obinrin naa ti ya aṣọ kan ṣoṣo ti iya Oladele maa n wọ jade, mọ ọ lọrun.
Oladele sọ pe iṣẹlẹ naa mu itiju ati ibanujẹ ba oun. Eyi lo si mu ko pinnu lati ma lọ si ṣọọṣi naa mọ, nitori itiju.
Eyi lo mu ko darapọ mọ ijọ Cele kan ti ko jinna si ile wọn.
Gẹgẹ bi ẹni to mọ ilu lilu, Oladele bẹrẹ si ni ba wọn lu ilu ninu ijọ naa.
Kẹrẹ-kẹrẹ, lo ba di ọmọ ijọ Celestial. O ni kii ṣe idaamu, tabi aisan lo gbe oun de inu ijọ alaṣọ funfun.
Nibẹ lo ti bẹrẹ si ni 'gun oke ẹmi', ti ko si ni mọ nkan to n lọ ni ayika rẹ fun bi ọjọ meje, lai mu omi tabi jẹun, to si sọ n sọ asọtẹlẹ.
O si ti n ṣiṣẹ alufaa ijọ Cele fun ọdun mẹrinla gbako.
Afojusun rẹ si ni lati da yatọ si awọn ijọ Cele yooku, nipa iwaasu ati isẹsi wọn.

Oríṣun àwòrán, Genesis Global
Wòlíì Genesis kan yẹra díẹ̀ ni, ó máa tó wọlé padà bí olè lóru- Adelé pásítọ̀ Oladele
Adelé pásítò Oladele ní wòlíì Genesis kan yẹra díẹ̀ ni, ó máa tó wọlé padà bí olè lóru
Adaba o naa ni a n kungbẹ, ina n jo ẹyẹ oko n lọ ni ijọ Celestial Church of Christ Genesis Global fi ṣe lẹyin ti ileẹjọ dajọ ẹwọn ọdun meji fun alakoso ijọ naa, Woli Israel Oladele lori ẹsun gbajuẹ.
Niṣe ni ijọ naa kun fọfọ ni isin ọjọ isinmi akọkọ to waye ninu ijọ ọhun lẹyin ti woli naa rẹwọn he.
Adele oluṣọ woli Oladele, Samuel Oba sọ ninu iwaasu rẹ pe ohun to ṣẹlẹ ko le fa iwariri ninu ijọ naa.
- Báyìí ni ìsìn ṣe lọ lónìí nílé ìjọsìn CCC Genesis Global
- Wo àwọn èèkàn, ìlúmọ̀ọ́ka olórin tó ṣàbẹ̀wò sí ijọ Celestial Church ti Genesis Global
- Seyi Makinde fún olórin Fuji Taye Currency lẹ́bùn ọkọ̀ bọ̀kìnnì Toyota Prado 2020
- Ẹ jọwọ, ẹ ba mi bẹ ìyàwó mi kí ìgbéyàwó mi ma baà túká - 9ice
- Ọlọ́pàá fìyà jẹ mí lọ́dún 2014, mò wà lẹ́yìn àwọn ọ̀dọ́ lórí ìwọde EndSARS- Fayemi
O ni Woli Genesis kan yẹra diẹ ni, ''ti akoko ba to, yoo wọle pada bi ole loru.''
''Ṣugbọn awọn ọta lo kan n polongo ohun ti ko ṣẹlẹ kaakiri,'' Pasitọ Oba lo sọ bẹẹ ninu iwaasu rẹ.
Pasitọ Oba tun fi igboya sọrọ pe ''mo wa nibi ti ẹ ba fẹ gbe mi, ẹ wa gbemi.''
Alufaa ọhun tun sọ pe ko si ohun ti awọn fẹ ki ọlọrun ṣe fun Woli Genesis ti ko tii ṣe fun tẹlẹ.
O rọ gbogbo awọn ọmọ ijọ CCC Genesis Global wi pe ki wọn kun fun ayọ, ki wọn si maa ṣe bi ẹni ti ibanujẹ ba nitori ohun to ṣẹlẹ si alufaa Oladele.
Ǹkan mẹ́wàá tí ẹ ò gbọ́ rí nípa Israel Oladele, Woli ìjọ Genesis Global
Israel Oladele Ogundipe (GENESIS) ni oludari ati alakoso ijọ Celestial Church of Christ, Genesis Global, ọkan ninu awọn ẹni ifami ororo yan tawọn ololufẹ rẹ n warii fun gẹgẹ bí ajinrere fun ijọ CCC lagbaye.
Olusọaguntan ni pẹlu, ó jẹ olukọ ati onisesẹ Aposteli.
Ọmọ ilu Igboore ni ilu Abeokuta ipinlẹ Ogun ni woli Israel Oladele ṣugbọn ọmọ atapata dìde ni to si jẹ iya ki o to de ipo to wa.
Ẹni ọdun marundinlaadọta ni Israel Oladele Ogundipe.
Ṣaaju, awọn ọmọ ijọ rẹ ti ba BBC Yoruba sọrọ pe:
Ǹkan mẹ́wàá tí ó yẹ kí ó mọ̀ nípá Woli Genesis
- Wasiu ni orukọ abisọ rẹ nitori idile Musulumi ni a ti bi i, o fi aye rẹ fun Jesu Kristi o si n lọ ijọ Christ Gospel Apostolic Church nibi to ṣi n lọ di asiko yii, Diakoni ni baba ati iya rẹ ninu ijọ CGAC.
- L'owurọ ọjọ rẹ, o wu u lati lọ si fasiti ki o lọ gboye ẹkọ isiro owó, ṣugbọn ko wa si imuṣẹ nitori awọn obi rẹ ko lowo lati ran an lọ, o tun wọ Fasiti Obafemi Awolowo ṣugbọn ko ri owo ile iwe san mọ lo fi kuro ti ko ka a pari.
- Loni Oladele Ogundipe lo ń dari dari ìjọ Celestial to pọ julọ lagbaye pẹlu ọmọ ìjọ to to ẹgbẹrun mẹta ninu isin kan ṣoṣo.
- O ti dabi awokose fun ọpọ awọn alakoṣe ìjọ Celestial, ti ipinu ọpọ eniyan si ti yipada nipa iṣe ati ihuwasi awọn Celestial, o yi ilana iwaasu aye lailai padà nípa ẹbun ikọni, wooli, ajihinrere ati ẹbun ṣiṣe oju aanu fawọn eeyan to ni.
- O ti koju oniruuru ipenija paapaa julọ lasiko to n dagba ati irú idile to tí wa to fi mọ nipa ibaṣepọ ṣaaju igbeyawo.

Oríṣun àwòrán, Genesis Global
- Wo ìròyìn tuntun tó tún jáde laááàfin Oòduà nípa Àrẹ̀mọ tuntun Ọọ̀ni Ile Ifẹ̀
- N1M ní iléẹ́jọ́ béèrè fún béèlì olùwọ́de EndSARS, Eremosele Adene
- Ìtàn ayé Abiola Peller, ọlọ́wọ́ idán tó fi ọ̀bẹ gé ìyàwó rẹ̀ sí méjì
- Wo ìròyìn tuntun tó tún jáde laááàfin Oòduà nípa Àrẹ̀mọ tuntun Ọọ̀ni Ile Ifẹ̀
- Amotekun gbàràdá ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Èmi ni mo fẹ́ ṣíwájú ìwọ́de ọ̀dọ̀ tí yóò tún wáyé-Oluwo
- Wooli Oladele ti ṣe olootu oniruuru awọn eto lori mohunmaworan àti Redio jakejado orile-ede Naijiria.
- Ohun ni oludasile àti aarẹ Genesis Leadership Academy, nibi to tin kọ awọn ọdọ bi a ṣe n dipo adari mu. Ajọ ti kii ṣe ti jọba to dasilẹ kii ṣe lati pawo nitori pe o ni gbagbọ pe iṣoro ti o wa nilẹ niṣe pẹlu iru olori to wa niluu.
- Ọdun 2012 ni o da ileẹkọ imọ nipa adari silẹ, bakan naa lo ni ajọ ti kii ṣe ti ijọba miran to n jẹ Israel Oladele Ogundipe Foundation oun si ni aarẹ ajọ naa. O da a silẹ lati maa ran awọn alaini lọwọ nitori bi idile rẹ ṣe talaka nigba to wa ni kekere.
- O jẹ onkowe ati ontẹwe, alaga ile itẹwe ISOLAD.

Oríṣun àwòrán, Genesis Global





















