Akeugbagold Twins: Iléẹjọ́ mú ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kọkànlá fún ìgbẹ́jọ́ àwọn tó jí ìbejì Àáfà Akewugbagold ní Ibadan

Ilé ẹjọ gíga Oyo state High court ni Ibadan kéde pe ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2020 lati gbọ igbẹjọ gbigba oniduro awọn ti ọwọ tẹ lori ọrọ ọmọ Akewugbagold.
Ileeṣẹ iroyin Naijiria, News Agency ni awọn afurasi naa: Muhammed Bashir to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn; Oyeleye Opeyem,i ẹni ọdun mẹẹdọgbọn; Olamide Ajala, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, Taiwo Ridwan, ẹni ọgbọn ọdu; Rafiu Mufutau, ẹni ọdun mẹrindinlogoji ati Fatai Akanji ni ọrọ naa kan.
Esun mẹta ni wọn fi kan awọn afurasi naa pe wọn ditẹ papọ huwa ibi, ijinigbe ati nini awọn ibọn lọwọ lọna aitọ.
- Àwọn afurasí lórí ẹ̀ṣùn jíjí ìbejì Akeugbagold gbé yọnú sílé ẹjọ́ láì ní agbẹjọ́rò
- Iṣẹ́ àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ lọ́gán nílé ìtajà aya Ajimobi tó jóná
- Ọlọ́pàá dóòlà ẹ̀mí èèyàn 10 nínú àwọn 16 tí ajínigbépawó jí gbé l'Óǹdó
- Agọ ọlọpàá Sanyo ni wọn dari ọkọ̀ akero to kó awọn Fulani tọ wọ ilu Ibadan si náà lọ - OPC
- Báwo ni Joe Biden yóò ṣe mú ìyípadà bá òfin tí Trump fi de orílẹ̀èdè àgbáyé?
- Ọmọ Nàìjíríà mẹ́fa tó n fi owó ránṣẹ́ sí Boko Haram rẹ́wọ̀n he ní Dubai
NAN ni wọn ti kọkọ ṣafihan awọn afurasi naa ni Iyaganku ni ọjọ keje, oṣu kẹsan an ki wọn to ko wọn lọ sile ẹjọ giga.
Awọn agbẹjọrọ ọtọọtọ lo n ṣoju wọn nile ẹjọ.
Saaju ni wọn ti n beere pe ki Adajọ jẹ ki wọn gab oniduro awọn lẹyin ti awọn ọlọpaa ti safihan wọn.
Agbẹjọrọ fun ijọba, Ojo Magrete beere fun asiko diẹ si lati fi to ẹjọ naa papọ bayii.
Lẹyin naa ni Adajọ Mashud Abass sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kejidinlogun, oṣu yii
Bi ẹ ko ba gbagbe, awọn Ibeji ọmọ ọdun meji ti aafa Akewugbagold bi ni Ibadan ni won ji gbe lọjọ keedọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun yii nile obi wọn ni agbegbe Sasa ki wọn to ri wọn.















