Akeugbagold Twins: Ilé ẹjọ́ fi afurasí méje pamọ́ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀ṣún ìjọmọ́gbe

Oríṣun àwòrán, Akeugbagold/Facebook
Ile ẹjọ Majisireti kan to kalẹ silu Ibadan ti paṣẹ pe, ki awọn afurasi mejeeje ti wọn fẹsun kan pe wọn ji ibeji Aafa Taofeek Akeugbagold gbe lọ fara pamọ sahamọ.
Adajọ ni ki wọn ko awọn afurasi mejeeje naa lọ si ọgba ikọ ọlọpaa to n tako iwa idigunjale, SARS nilu Ibadan.
Awọn mejeeje ni wọn fẹsun kan pe wọn ji awọn ọmọ naa ko ni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2020.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo kábàámọ̀ pé ń kò bẹ Baba Legba wò, nígbà tó pè mí - Foluke Daramola
- Aṣòfin méje yarí mọ́ Akeredolu lọ́wọ́ torí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí kò pín fún wọn
- Aya gómìnà Kwara gba ilé fún Risikat olójú búlúù àti ọkọ rẹ̀
- Risikat, ìyá àwọn ọmọ olójú búlù tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge
- Àwọn ọ̀daràn tó jí ìbejì ọmọ Akeugbagold kó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lòníì
- Àjọ ECOWAS yan Aàrẹ Ghana, Nana Akufo-Addo gẹgẹ bíi aàrẹ tuntun
Orukọ wọn ni Mohammed Bashir, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, Oyeleye Opeyemi ẹni ọdun mẹẹdọgbọn, Olumide Ajala ẹni ọdun mẹrindinlogoji ati Taiwo Rildwan ẹni ọgbọn ọdun.

Oríṣun àwòrán, Akewugbagola
Awọn yoku ni Rafiu Mutiu ẹni ọdun marundinlogoji, Fatai Akanji ẹni ọdun mọkandinlaadọta ati Rafiu Modinat ẹni ọdun mọkandinlọgbọn.
Ọga ọlọpaa Adegboye to ṣafihan awọn ọdaran naa nile ẹjọ majisireeti ọhun ni, wọn gba miliọnu mẹrin owo itanran lọwọ baba awọn ibeji naa, ki wọn to fi awọn ọmọ naa silẹ.
Ẹsun marun un ni wọn fi kan meji lara awọn afurasi naa, eyiun, Rafiu Mutiu ati Rafiu Modinat, ti wọn gba pe kawọn afurasi ọhun fi awọn ibeji ọhun pamọ sinu ile wọn.
Afurasi kẹfa, Fatai Akanji, nikan ni agbejọrọ wa ṣoju rẹ nilẹ ẹjọ naa, ti awọn to ku ko si ni agbẹjọrọ to n soju wọn.
Adajọ Emmanuel Idowu kọ lati gba oniduro fun gbogbo wọn.
Lẹyin ti ko gba pe wọn ko jẹbi lo ni ki wọn ko gbogbo wọn lọ si ọgba ẹwọn ọlọpaa SARS, ti o si sun igbẹjọ naa si ọjọ kejila, oṣu kẹwaa, ọdun yii.















