Ondo Assembly Crisis: Akeredolu kọ̀ láti pín ọkọ̀ fún àṣòfin méje tó ń ti igbákejì rẹ̀ lẹ́yìn

Akeredolu n fa ọkọ le awọ̀n asofin lọwọ

Oríṣun àwòrán, Others

Eto oselu ti n gba ọna miran yọ nile asofin ipinlẹ Ondo nitori bi awọn asofin meje kan se n fapa janu lori ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn ko ri gba.

Idi ni pe gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu lo pin ọkọ ayọkẹlẹ SUV KIA Sportage fawọn asofin amọ ti ko fun awọn asofin meje to n se atilẹyin fun igbakeji rẹ, Agboola Ajayi.

Bẹẹ ba gbagbe, Ajayi lo ti kuro lẹyin Akeredolu ninu ẹgbẹ oselu APC lọ si PDP, eyi to mu ki omi eto oselu nipinlẹ naa maa daru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti ile asofin si n gbe igbesẹ lati yọ nipo, asofin meje yii lo tako iyọnipo naa, ti ile si pasẹ pe ki wọn lọ rọọkun nile.

Akeredolu n fa ọkọ le awọ̀n asofin lọwọ

Oríṣun àwòrán, Others

Nigba ti wọn n fi ero wọn han lori igbesẹ ti Akeredolu gbe yii, awọn asofin naa koro oju pupọ si iwa yii, ti wọn si ni gomina n si agbara lo le awọn lori ni.

Igbakeji olori ile asofin l'Ondo, to wa lara awọn asofin meje naa ni, ile asofin ọhun ati ijọba Ondo tun kọ lati gba awọn pada sile, lẹyin tile ẹjọ wọgile asẹ lọ rọọkun nile naa.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Mọ̀ si nípa oríṣìí ẹ̀ka ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ àti ìwúlò wọn

Wọn ni ọna lati fiya jẹ awọn nitori pe awọn ko se atilẹyin fun iyọnipo igbakeji gomina lo bi iwa ọhun.

Bakan naa ni wọn kede pe ẹtọ awọn ti ofin fọwọsi ni ọkọ ayọkẹlẹ naa, gomina Akeredolu ko si gbọdọ maa tọwọ oselu bọ ọ.

Akeredolu n fa ọkọ le awọ̀n asofin lọwọ

Oríṣun àwòrán, Others

Aṣòfin méjìdínlógún sá àsálà kúrò nípínlẹ̀ Ondo

Awọn aṣofin mejidinlogun ti wọn yọ olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo ati igbakeji rẹ, ti sa fi ipinlẹ naa silẹ.

Ohun ti awọn aṣofin naa ni o faa ti awsn fi sa kuro ni ilu Akurẹ ko ṣẹyin bi wọn ṣe ni abo to peye ko si fun ẹmi awọn lati igba ti wọn ti yọ olori ile naa tẹtẹ nipo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin ti awọn aṣofin naa ys Bamidele Ọlẹyẹloogun ati igbakeji rẹ Ogundeji Iroju nipo ni awọn janduku ti iroyin sọ pe wọn jẹ ọms ẹgbẹ awakọ ero NURTW nilu Akurẹ ya bo ile aṣofin naa ti wọn si lu awọn awọn aṣofin ati oṣiṣẹ ti ọwọ wọn ba.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, olori tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan fun ile naa, Ọlamide George ni ilu Ibadan ni awọn sare wa fi ara sinko si nitori abo ẹmi wọn.

"A ni lati sa kuro nilu nitori ko si abo fun ẹmi wa mọ. Ẹmi mi, ẹbi mi ati awọn aṣofin ẹgbẹ mi lo wa ninu ewu, idi si niyi ti a fi fi ilu silẹ wa fi ara pamọ si ilu Ibadan."

"A si ti fi asiko yii kigbe iranwọ si aarẹ Buhari ati ọga ọlọpa lorilẹede yii lati wa gba wa silẹ."ni ọjọ ẹti ti o kọja ni awọn aṣofin mejidinlogun ninu mẹrindinlọgbọn to wa ni ile naa dibo yọ olori ile naa ati igbakeji rẹ lori ẹsun iwa aitọ, ṣiṣe owo baṣubaṣu, ṣiṣi agbara lo ati aikun oju iwọn lẹnu iṣẹ.