Femi Gbajabiamila: DSS ti fi ẹ̀sọ́ àbò Gbajabiamila tó pa fẹ́ndọ̀ l'Abuja sátìmọ́lé

DSS ti fi ẹ̀sọ́ àbò abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asofin tó pa fẹ́ndọ̀ l'Abuja sátìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Femi Gbajabiamila

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin l'Abuja, Femi Gbajabiamila ti ṣèlérí pé òun ṣetan láti tọ́ àwọn ọmọ fẹ́ndọ Ifeanyi Okereke ti ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yìnbọ̀n pa titi ti wan yóò fi dàgbà.

Gbajabiamila sọ èyí lásìkò tó lọ ṣe ẹkú ọrọ èèyàn si àwọn ẹbi olóògbé lágbègbè Kwata ní Madalla-Suleja.

Abẹnugan ni òun yóò tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì ní ilé ìwé titi wọ́n yóò fi tójúú bọ́, bákan náà ni òun yóò fún ìyàwó rẹ̀ ni owó ti yóò maa fi ṣòwò.

" Àwọn ọmọ yìí ti di tèmi, mo si ti pé agbẹjọ́rò mi láti ṣi àpò owó fún wọ́n títí ti wọ́n yóò fi tójuubọ́" ọ̀rọ̀ Femi Gbajabiamila rèé

Ẹ̀sọ́ abẹnugan ilé, to jẹ́ ọkan lára àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ (DSS) Nàìjíríà, Abdullahi M. Hassan ló yìbọ̀n pa Ifeanyi nítori wan ń sá tẹ̀lé mọ́to Femi Gbajabiamila ti wọn si n kíi.

Ó ti le ni ọdún méje ti Ifeanyi ti n ta ìwé ìròyìn lágbègbè Federal Secretariat tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ló mọ̀ọ́.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà

Bí abẹnugan ilé ṣe ń kọja ló fún Ifeanyi ni ẹgbẹrun mẹ́sán náírà pé kí ó pin pẹ̀lú àwọn tó kù rẹ̀, kí a tí wí ká tó fọ̀, ní Abdullahi yìn ni ìbọ̀n lórí ni ìgbà mẹ̀rin.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ Ifeanyi ló sàlàyé pé kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé ti Abdullahi ti maa n yìnbọn ni gbogbo ìgbà ti abẹnugan ba ti n kọjá.

Wọ́n ni ǹkan ti ó dun àwọn jùlọ ni pé, Ifeanyi ti rí iṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ Labour & Productivity to si ti n múra láti lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kí ó tó kú

DSS ti fi ẹ̀sọ́ àbò abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asofin tó pa fẹ́ndọ̀ l'Abuja sátìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Gbajabiamila

Níbo ni SSS tó pa Ifeanyi wà?

Àjọ DSS ti fi Abdullahi si àtìmọ́le títí di àsìkò tí wọn yóò parí ìwádìí wọ̀n.

Agbẹnusọ àjọ náà Peter Afunaya tó fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ sàlàyé pé Abdullahi lo yìnbọ, ọmọ àjọ àwọn sì ni, àti pé àwọn ti ṣetan láti dá sẹríà tó tọ́ fún.

Ó fi kun pé, àjọ ọ̀hún ti yọọ́ kúrò lára àwọn tó ń tèlé mótò abẹnugan, àjọ náà fi kun pé kedere ni àwọn yóò ṣe gbogbo ìwádìí àti ìdája ọ̀rọ̀ náà.

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé

Ìdája òdodo ni Ifeanyi yóò rí gbà

Ẹ̀wẹ̀, Gbajabiamila ti fi ọkàn gbogbo àwọn fẹ́ndọ̀ tó kù balẹ̀ lónìí ọjọ́ àìkú pé òun yóò rí dájú pé Ifeanyi kò kú lásán.

Abénugan to sàbẹ̀wò sí ilé iṣé wọ́n, ó sàlàyé fún wan pé, bí ìjọkó ilé yóò ṣe bẹ̀rl lọ́ja ìṣẹ́gun, àwọn yóò yẹ́ Ifeanyi sí nínú ìjókó àwọn

Bákan náà ló sọ pé òun ti wọ́gilé gbogbo ètò tí òun ní nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ láti ríi dájú pé, òun se ìdárò Ifeanyi dáadáa.

DSS ti fi ẹ̀sọ́ àbò abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asofin tó pa fẹ́ndọ̀ l'Abuja sátìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Gbajabiamila

Àjọ agbófinró DSS ń àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwadìí ẹ̀ṣọ́ olórí ilé aṣòfin-ṣojú, Femi Gbajabiamila tó yìnbọn pa Fẹndọ l'Abuja

Ileeṣẹ agbofinro ọtẹlẹmuyẹ DSS lorilẹede Naijiria ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ibọn yinyin to ṣekupa fẹndọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Ifeanyi Okeke latọwọ ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ agbofinro naa.

Alukoro ileeṣẹ agbofin ọtẹlẹmuyẹ DSS, Ọmọwe Peter Afunaya ṣalaye ninu atẹjade kan pe lootọ oṣiṣẹ ileeṣẹ agbofinro DSS ni arakunrin ti wọn funrasi pe o yin ibọn naa, ati pe ara awọn ẹṣọ alaabo ti wọn yan ti olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin orilẹede Naijiria, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila ni.

Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Twitter/gbajabiamila

O ni wọn ti yọ ọgbẹni naa kuro lara awọn ẹṣọ olori ile aṣojuṣofin naa ati wi pe, ni ibamu pẹlu ilana ibawi lẹnu iṣẹ, wọn ti fi si ahamọ, ileeṣẹ agbofinro DSS si ti bẹrẹ iwadii pẹlu ileri pe ko ni si kọnu n kọhọ ninu iwadii lori bi afunrasi naa ṣe lo ibọn rẹ.

Wo orúkọ ẹ̀ṣọ́ Gbajabiamila tó yìnbọn pa fẹ́ńdọ̀ nílùú Abuja, pẹ̀lú ibi tó ti ń ṣiṣẹ́

Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin lorilẹede Naijiria, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila ti ṣiṣọ loju ẹṣọ alaabo rẹ to yinbọn pa fẹndọ kan ni ilu Abuja l'Ọjọbọ

Họnọrebu Gbajabiamila darukọ ẹṣọ alaabo naa gẹgẹ bii Abdulahi Hassan.

O ni oṣiṣẹ ileeṣẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ DSS ni atipe wọn ti faa le awọn ileeṣẹ to yẹ lọwọ fun iwadii ati igbesẹ ibaniwi to rọ mọ iṣẹ rẹ ati ẹṣẹ ti o ṣẹ.

Ni Ọjọbọ ni awọn ẹṣọ alaabo to wa pẹlu Họnọrebu Gbajabiamila 'yinbọn soke'lati tu awọn eeyan kan ti wọn ni wọn dabu ọkọ olori ile aṣojuṣofin naa ka.

Amọṣa lẹyin o rẹyin ni iroyin jade pe ibọn ba Ifeanyi Okereke, ọkan lara awọn fẹndọ to n ta iwe iroyin ni sẹkitariati ijọba apapọ ni lu Abuja ti o si jade laye.

Ẹ̀ṣọ Gbajabiamila yìnbọn pa fẹ́ńdọ̀ kan l'Abuja, àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ fẹ ṣe iwọde

Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Twitter

Olori ile asojusofin Naijiria Femi Gbajabiamila ti ni ki ọlọpaa kan lara awọn ẹsọ rẹ lọ rọọkun nile nitori pe o yinbọn pa arakunrin kan to n ta iwe iroyin Ifeanyichukwu Elechi nilu Abuja.

Gbajabiamila ni yoo bẹrẹ lilọ rọọkun nile naa titi ti ileesẹ ọlọpaa yoo fi pari iwadii.

Agbegbe Secretariat niluu Abuja ni nkan bi ago mẹta ni ọlọpaa naa yinbọn lu Ifeanyi.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Isẹlẹ yii waye nigba ti olori ileasojusofin kuro ni ọfisi rẹ.

Wọn sare gbe e lọ si ile iwosan agba nilu Abuja sugbọn ẹpa ko boro mọ.

Bi Isẹlẹ naa se waye

Gbajabiamila to sapejuwe iku fẹndọ naa gẹgẹ bi ohun to fọwọ kan ni lẹmi sọ pe awọn kuro ni ọfisi bi ise awọn ni tawọn si duro lati ki awọn to n ta iwe iroyin .

Gẹgẹ bi ohun to sọ, o ni oun ati awọn to n ta iwe iroyin wọnyi ti mọra tipẹ nitori ọdọ wọn loun ti n ra iwe iroyin lati igba ti oun ti de si Abuja.

O ni nitori eyi, oun a si tun maa fun wọn lowo nigbakigba toun ba kọja.

Nitori eyi, o ni Ifeanyi ati awọn akẹgbẹ rẹ rọ yika ọkọ oun nitori wọn mọ pe a maa fun awọn lowo.

Sadede lo ni awọn gbọ iro ibọn.

Olori ile sọ pe awọn arakunrin kan tawọn ko mọ ri darapọ mọ wọn lati yi ọkọ oun ka eyi lo si mu ki awọn ẹsọ yin ibọn soke.

O ni awọn agbofinro yi sọ pe ọgbọn lawọn agbofinro yi lo lati fi yin ibọn yi sugbọn nigba ti yoo fi ya lawọn gbọ pe asiyin ibọn ba arakunrin kan iyẹn Ifeanyi.

Gbajabiamila sọ pe oun ba awọn mọlẹbi Ifeanyi kẹdun lori isẹlẹ naa.

Awọn fẹndọ fẹ se iwọde ifẹhonu han

Ẹwẹ awọn fẹ́ndọ to n ta iwe iroyin lAbuja sọ pe awọn yoo bọ si igboro lati se iwọde lori iku ọkan lara wọn yi.

Wọn ni iwọde yi se pataki lati fi pe akiyesi ọga agba ọlọpaa si isẹlẹ yi.

Wọn tun sọ pe awọn ko ni ta iwe iroyin kankan titi di ago mẹwaa aarọ ati pe bi ẹnikẹni ba tapa si aṣẹ yi awọn yoo foju rẹ jofin.

Iwọde naa yóò gberasọ lati Area 1.