Salami report on EFCC: Ààrẹ Buhari tẹ́wọ́ gba àbájáde ìwádìí lórí àjọ EFCC, ìròyìn kan ní wọ́n fẹ́ yọ Magu nípò

Ibrahim Magu

Oríṣun àwòrán, Ripples

Igbimọ oluwadii ti Onidajọ Ayo Salami gbe kalẹ lati wadii awọn ẹsun ti wọn fi kan Adele Alaga ajọ EFCC tẹlẹ, Ibrahim Magu, ti sọ pe ki wọn o da Magu duro.

Ọjọ Ẹti ni igbimọ naa gbe àbọ̀ iwadii rẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, to si gba aarẹ nimọran lati yan adele alaga ajọ EFCC tuntun, ti yoo wa nipo fun ọdun meji.

Bakan naa ni igbimọ naa gba Aarẹ nimọran lati yan adele alaga ajọ naa, lati ibomiran yatọ si ileesẹ ọlọpaa.

Saaju asiko yii, ileesẹ ọlọpaa ni wọn ti ma n yan gbogbo àwọn to ti ṣe alaga ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ naa,lati igba ti wọn ti da a silẹ.

Àwọn ẹsun bi kiko owo jẹ, ati aṣilo ipo ni wọn fi kan Magu, eyi to mu ki ijọba ni ko lọ rọọkun nile naa, titi iwadii yoo fi pari lori awọn ẹsun naa.