Delta Assault: Ọkùnrin tó pe ìyàwó rẹ̀ lájẹ̀ẹ́ tì í mọ́lé fọ́dún mẹ́rin, fún un lóyún nígbà mẹ́ta

Iyawo Ame Edjeke

Oríṣun àwòrán, HARRISON GWAMNISHU

Eemọ lukutu pẹbẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti mu ọkunrin kan, Ame Edjeke lori ẹsun pe o ti iyawo rẹ inu yara kan fun ọdun níbi ti o ti fi iya oriṣiiriṣii jẹ ẹ.

Afurasi naa Edjeket, ẹni ọdun mọkanlelogoji ni a gbọ pe o fun obinrin ọhun loyun lẹẹmẹta lera nigba to wa ni igbekun nile wọn to wa ni Orerokpe nipinlẹ Delta.

Ọkùnrin ti iyawo rẹ yii ti bi ọmọ mẹjọ fún ni iroyin sọ pe burẹdi nikan lo fun obinrin naa jẹ nigba to fi ti i mọle.

Àkọlé fídíò, Tí mo ba ti múra bí ọkùnrin fi kọrin, kò sí ọ̀dọ̀ ààrẹ́ tí mi ò lè wọ̀- Erelu, ọmọ Elemure Ekiti

Bakan naa ni a tun gbọ pe ọkunrin naa ko jẹ ki iyawo rẹ wẹ tabi lo ile igbọnsẹ lasiko to fi wa ni igbekun.

Ṣugbọn aṣiri tu lẹyin tawọn ẹlẹyinju aanu kan fi ọrọ naa to ẹgbẹ ajafẹtọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Behind Bars Defenders leti.

Ẹgbẹ yìí gan an lo gbe ọrọ naa dọdọ awọn ọlọ́pàá.

Oludari ẹgbẹ ọhún, Harrison Gwamnishu sọ fawọn akọroyin pe ọkunrin naa ni iyawo oun lo wa nidi bi oun ko ṣe lowo lọwọ.

Iyawo Ame Edjeke

Oríṣun àwòrán, HARRISON GWAMNISHU

Afurasi naa ti wa ni akolo awọn ọlọpaa bayii nigba ti iyawo rẹ si n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Nigba ti o n fidi ọrọ naa múlẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, Onome Onovwakpoyeya ṣalaye pe Ọgbẹni Edkepek ni ajẹ ni iyawo oun, o si larun ọpọlọ loun fi tii mọle tori ko sí ẹni to fẹ ran an lọwọ.

O tun sọ fawọn ọlọpaa pe oun gbiyanju lati da obinrin pada fawọn ẹbi rẹ, ṣugbọn wọn kọ ọ.

Bakan naa lo tun sọ fawọn ọlọpaa pe oun ti gbe iyawo oun kaakiri ile babalawo ki oun to da pada sini ile.