Omo Ghetto: Funke Akindele ṣàlàyé bí àwọn agbébọn ṣe kọlù wọn làsíkò tí wọ́n ń ya fíìmù

Funke Akindele

Oríṣun àwòrán, Instagram/Funke Akindele

Gbajugbaja oṣere Nollywood, Funke Akindele ti ṣalaye ohun ti awọn agbebọn fi oju rẹ ri lasiko ti wọn yabo ile itura to wa lasiko to n ṣe fiimu Ọmọ Ghetto.

Funke Akindele sọ ọrọ yii loju opo ikansiraẹni Instagram rẹ lasiko to n ba awọn eniyan sọrọ ni ojukoroju' Instagram Live' to waye laipẹ yii.

O ni iṣẹlẹ yii waye ni nkan bii ọdun mẹsan an sẹyin.

Àkọlé fídíò, Ọkùnrin tó fẹ́ fipábámilòpọ̀ fín ǹkan sí mi lójú ló ṣe rọ́nà wọlé sí mi lára

Lara awọn to kopa ninu fiimu naa ni orẹ timọtimọ Funke Akindele, Bimbo Thomas to kọ lati jẹ ki awọn ole naa ṣekupa Funke Akindele.

''O ti pẹ ti emi ati Bimbo ati Eniola Badmus ti jẹ ọrẹ timọtimọ. ''

''Nkan bii ọdun mẹsan an ṣẹyin lasiko ti a n ṣe fiimu apa keji Ọmọ Ghetto, to si yẹ ki Eniola wa darapọ mọ wa ninu yara ile itura ti mo wa, amọ o kọ.''

Bimbo Thomas, Funke Akindele, Eniola Badmus, Chioma Akpotha

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bimbo Thomas

''Émi ati Bimbo la wa papọ lalẹ ọjọ naa lẹyin ti mo bẹ ẹ wi pe mi o fẹ da sun, ki o wa sun pẹlu mi.''

''Awọn ole naa wọ inu ile itura naa, wọn si bẹrẹ si ni gba ilẹkun ibi ti mo wa, amọ Bimbo ni ki n lọ si abẹ ibusun lati sapamọ, tabi ki n lọ si ile iwẹ.''

''Ile iwẹ ni mo sa pamọ si nigba ti awọn agbebọn naa wọle, ti wọn si bẹrẹ si ni bere pe nibo ni Funke Akindele wa?''

''Bimbo kọ lati sọ fun wọn, nigba ti wọn bẹrẹ si ni na a ni mo sa jade wi pe ki wọn ma pa a, ti wọn si bẹrẹ si ni naa emi naa, amọ Bimbo n pariwo ki wọn fi mi silẹ.''

''Lẹyin ọjọ mẹta ti iṣẹlẹ naa waye ni mo bere lọwọ rẹ idi ti ko fi sọ ibi ti mo wa fun awọn adigunjale naa, Bimbo ni o dara ki oun ku ju ki Funke Akindele ku lọ.''

Fiimu Ọmọ Ghetto saga ti Funke Akindele ṣẹṣẹ ṣe jẹ apa keji akọkọ rẹ to ti ṣe jade tẹlẹ.

Saka ń wá ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan nítorí aṣọ kóòtù ọdún 34 sẹ́yìn

Afeez Oyetoro "Saka" ní 'toríi kóòtù àyálò ni òun fi ń wá ọ̀rẹ́ ọdún 34 sẹ́yìn.

Afeez Oyetoro Saka

Oríṣun àwòrán, Mpmania

Ṣe ẹ mọ Afeez Oyetoro ti orukọ inagijẹ rẹ ninu ere n jẹ Saka?

Dajudaju ọpọ eeyan lo mọ Saka gẹgẹ bi agba ọjẹ apanilẹrin ninu ere sinima lorilẹede Naijiria.

Amọṣa, alagba Saka ni ki iṣu oun to di iya, iya diẹ kọ lo jẹ lọwọ odo.

Saka sọ ọrọ yii ninu awọn ọrọ kan to kọ nigba to gbe fọto rẹ kan to fi soju opo Instagram rẹ sita.

Saka ni atapata dide loun atipe nibi to le de, ayawọ kootu ni oun fi ṣe ayẹyẹ igbaniwọle, Matriculation, nigba ti oun wọle gẹgẹ bii akẹkọọ ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, OAU ni ilu Ile Ifẹ lọdun 1986.

"Ariwo ayọ n lọ lọtun losi lọgba fasiti naa fun ayẹyẹ igbaniwọle awọn akẹkọọ ti emi ko si ni ireti lati bawọn darapọ ṣe nitori pe mi o ni kootu ti mo le wọ fun ayẹyẹ naa".

Saka ni eyi mu ki inu oun bajẹ gidigidi ti oun si ka jọ si ori ibusun oun ninu ibanujẹ ọkan.

Saka atawọn eeyan rẹ lọjọ ayẹyẹ igbaniwọleewe fasiti rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/simplysaka

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

Amọṣa, Saka ni ọrẹ oun kan lo gba oun kalẹ to si ya oun ni kootu rẹ ti oun fiṣe ayẹyẹ ayajọ naa.

O fi kun pe ọrẹ oun yii lo wa gba oun silẹ lọwọ ainikopa lọjọ naa lọhun.

O ni ohun to dun oun jọjọ bayii ni pe oun n wa akẹkọọ naa ti awọn jọ gbe nileewe titi di oni ti oun ko si rii.

"O wumi ki n ri akẹgbẹ mi naa lati dupẹ lọwọ rẹ. Ọlọrun yoo maa ba gbogbo wa pade lawọn ikorita aini wa".