Bayelsa teacher rape: Olùkọ́ fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá lòpọ̀ títí dójú ikú ní Bayelsa

Oríṣun àwòrán, @pictocodc
Olukọ fipa ba akẹkọọ ọmọ ọdun mẹtala lopọ titi doju iku
Bayelsa: Olukọ fipa ba akẹkọọ ọmọ ọdun mẹtala lopọ titi doju iku
Arakunrin Promise Sylvanus Ogun to jẹ olukọ nile iwe Government Secondary School, Toroegbeni ni wọn ti fẹsun kan pe o fipa ba akẹkọọ rẹ lopọ titi to fi ku.
- Kílódé tí Ọọni Ife, Oba Ogunwusi kò fi gbọdọ̀ rí ọmọ rẹ̀ tuntun ti Olorì Naomi bí títí di bíi ẹ̀yìn oṣù mẹ́fà?
- Ọmọbìnrin tó tayọ nínú ìdànwó WAEC ọdún 2019 pẹ̀lú A1 méje ti kú
- Àwọn Olúkọ ìpínlẹ̀ Oyo fakọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà púpọ̀
- Toyin Abraham fi orin yẹ́ Iyabo Ojo sí níbi ìsìnkú ìyá rẹ̀, Falz di ẹni tí wọ́n fí òpópónà ṣọ orí rẹ̀
Olukọ to jẹ ọgbọn ọdun fipa ba ọṃbinrin naa lopọ ni agbegbe ijọba ibile Sagbamu ni ilu Bayelsa.
Awọn ẹbi ọmọdebinrin to ti doloogbe naa ati olori abule naa ni arakunrin Promise koko jẹwọ pe lootọ ni oun fipa ba ọmọ naa lopọ, ko to di wi pe o yi ohun pada.
Iwadii fihan pe nkan bii oṣu kẹta, ọdun 2020 ni olukọ rẹ ti dasi lọna ni ibi to ti lọ wẹ ni odo, to si fi ipabalopọ nigba meji ọtọọtọ.
Baba ọmọbinrin to doloogbe naa ni ọmọ naa ko dele sọ nkan to sẹlẹ sip e wọn ti fipabalopọ.
Amọ, sa deede ni wọn ri wi pe ẹjẹ n da lara rẹ diẹ diẹ, ti wọn sigbe lọ si ileewosan labẹle nibi ti wọn ti sọ fun awọn obi rẹ wi pe niṣe ni wọn fi ipa ba lopọ.
Iwe iroyin abẹle naa naa lẹyin naa ni wọn lọ koju olukọ naa, to si jẹwọ pe lootọ ni oun ṣe aṣemaṣe naa, o si gba lati ṣe itọju ọmọbinrin naa.
Awọn obi rẹ ni o gbe ọmọ naa lọ si ile iwosan nibi ti o ti n gba itọju fun ọsẹ kan.
Amọ, lẹyin ọsẹ kan ni olukọ naa gbe ọmọ naa wale pada pẹlu bi ẹjẹ ṣe n da ni ara rẹ.
Baba ọmọbinrin naa ni lẹyin ọjọ meji ti olukọ to fipaba ọmọ naa lọpọ naa da pada si ile awọn lo dagbere fun aye.
Amọ, olukọ yi ohun pada pe baba ọmọbinrin naa n lepa ẹmi oun ni oun ṣe salọ ati wi pe ọrọ ko ri bẹẹ mọ lori ẹsun ifipabanilopọ.
- Wo bí ilé ìwòsàn LUTH ṣe ń gba owó ibùsùn lọ́wọ́ àwọn aláìsàn, tí àwọn míràn sì ń sun ìta
- Ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí ní lù mí lẹ́yìn tí mo lòdì sí ibálọ̀pọ̀ láti ihò ìdí lẹ́yìn- Sabira
- Wo ohun tí Ọọ̀ni, Sultan Sokoto sọ nípa ọta ìbọn tó gbẹ̀mí Ọba Olúfọ́n
- Látilẹ̀ ni mo ti fẹ́ràn orin ìjọ Kérúbù àmọ́ ẹlẹ́sìn mùsùlùmí àti krìstẹ́nì ni mí- Qdot
Nibayii, ajọ to n gbogun ti iwa ifipabanilopọ lawujọ ati ajọ Girl Response Initiative Team ti iyawo gomina ipinlẹ Bayelsa, Abilekọ Gloria Diri gbekalẹ yoo bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Nitori ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa ti lọ fi panpẹ ọba mu baba ọmọbinrin naa lẹyin ti olukọ fi ẹsun kan baba pe o fẹ pa oun.
Ajọ ajafẹtọ ọmọbinrin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ nitori wọn ko ṣewadii ohun to ṣẹlẹ, ti wọn si n gbogun ti baba ọmọbinrin naa.
Wọn fikun pe ẹni to fi ipa ba ọmọbinrin naa lopọ ko ni lọ lai jiya ẹsẹ rẹ, nitori ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ ṣe awari rẹ, ki o si foju wina ofin nitori o jẹwo pe lootọ ni oun fi ipa ba ọmọbinrin naa lọpọ to si jasi iku rẹ.
- Ọkùnrin kan "lu ìyàwó rẹ̀ pa" nítorí ó lọ síbi ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ
- Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ASUU tí gbà láti fòpin sí ìyanṣẹ́lódí lẹ́yìn tí ìjọba gbà látí sàn N70bn ṣùgbọ́n...
- Ilé ẹjọ́ ní kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá san N50 mílíọ̀nù fún ẹbí 'Sleek' ní Port Harcourt
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọlọ́kadà àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ibadan


















