Ikorodu student death: Ìròyìn sọ pé ìjọba, agbófinró ṣì ń wá olùkọ́ tó lu akẹ́kọ̀ọ́ pa ní Ikorodu nítorí ibéèrè ìṣirò

Oríṣun àwòrán, Ridwan Oyewumi
Nibo ni olukọni to lu akẹkọọ pa nileewe aladani kan ni ilu Ikorodu wa bayii?
Eyi ni ibeere to gba ẹnu ọpọ awọn eeyan to gbọ si iṣẹlẹ buruku naa eyi to waye lọjọbọ ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2020.
Iroyin ti a n gbọ ni pe olukọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọgbẹni Emma ti fi ẹsẹ fẹ, awọn alaṣẹ ipinlẹ Eko ṣi n wa a titi di bi a ṣe n sọrọ yii.
- 110 ni ìyè àwọn àgbẹ̀ tí Boko haram dúmbú ní Borno tí dì báyìí-UN
- N81m pọ̀ lóòtọ́ láti fi gé koríko Stadium, Ọ̀gá Mínísítà,èló lẹẹ́ san fáwa ọ̀dọ́ láti gè e?
- Bí mo bá leè rí ọmọ alágbe t'áyé fẹnu sí pé mo fi ẹlẹ́rìndòdò lá lójú, máa kúnlẹ bẹ ẹ - Motara
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọba tó kọ ifá sílẹ̀ gbé Bíbélì àti Kùránì
Ọgbẹni Emma ni iroyin sọ pe o lu Ọgbẹni Boluwatifẹ Omelaja nileewe aladani to n lọ nitori pe ko lee dahun ibeere iṣiro kan to bi i.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aburo Boluwatifẹ, Lateef ti oun pẹlu jẹ akẹkọọ nileewe naa lo wa ṣilẹkun ọrọ fun awọn obi rẹ pe olukọ rẹ lo lu u pa.
Ohun ti awọn alaṣẹ ileewe naa ṣe lalaye fun awọn obi rẹ gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni pe, o fo ṣanlẹ ku ni kilaasi rẹ ni.
Koda wọn ni olukọ to lu u pa naa wa lara awọn to gbe oku rẹ wa ba awọn obi rẹ nile, laimọ pe oun gan lo wa ni idi ọrọ naa.
Ohun ti a gbọ ni pe ẹka to n ri si imunadoko ati ijageere eto ẹkọ ni ipinlẹ Eko, Office of Education Quality Assurance ti bẹrẹ iwadii lori rẹ.
Amọṣa titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ọjọ mẹrin lẹyin ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ko si ẹni to tii kofiri olukọni to ṣiṣẹ laabi naa.
Kí ló ṣekú pa Bolu, akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó fò ṣánlẹ̀ kù nílé ẹ̀kọ́ ni Ikorodu?

Oríṣun àwòrán, Ridwan Oyewumi
Awọn mọlẹbi ti ọmọ wọn ṣadede fo sanlẹ ku nileewe rẹ,Elihans Schools,ni Iṣawo Agric, Ikorodu ti sọ fun BBC pe awọn ko ro pe amuwa Ọlọrun ni iku rẹ jẹ.
Boluwatife Omeleja akẹkọọ ọmọ ọdun merinla ni iroyin gbode loju opo ayelujara pe wọn gbe oku rẹ wale lati ileewe lỌjọbọ to kọja.
Ridwan Oyewumi to sọ fun BBC pe oun ni ẹgbọn Bola fidi ọrọ mulẹ pe lootọ ni wọn gbe oku Boluwatife wa lati ileewe rẹ, Elihans College Ikorodu lọjọbọ.
O ni ko pẹ si igba ti wọn gbe oku Bolu wa ni awọn ti sare lọ sin ni ibamu pẹlu ilana isinku musulumi.
Ridwan ṣalaye pe baba awọn sọ pe awọn ko ni ṣẹjọ lori iku Bolu ṣugbọn awọn ni lati mọ ohun to ṣeku pa Bolu.
Bawo ni Bolu ti ṣe ku?
Alaye ti BBC gbọ ninu ọrọ ti Ridwan kọ si oju opo rẹ ni Twitter ati eleyi to sọ fun wa ni pe ẹni to nileewe ti Bolu n lọ lo ṣadede pe baba oun lọjọbọ.
O ni wọn sọ fun wọn ki wọn tete maa bo wa nitori Bolu ti daku nileewe.
''Nigba ti Daddy wa gbọ, niṣe ni wọn gbera lati maa lọ si ileewe rẹ. Amọ loju ọna ni wọn ti pade olukọ ati ẹni to nileewe ti wọn gbe Bolu bọwa ninu ọkọ''
Ridwan ni Daddy awọn ri pe Bolu ko ṣọrọ ti wn si sare gbe lọ si bi ile iwosan meji ki o to di pe awọn dokita sọ pe Bolu ti ku.
Alaye ti Ridwan sọ pe ọrẹ Daddy awọn to ni ileewe sọ fawọn ni pe olukọ beere ibeere lọwọ Bolu to si ni ko wa ṣalaye niwaju patako fawọn iyoku rẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omelaja Boluwatife Taofeek
''O lọ siwaju kilasi ti wọn si fun ni ẹfun ko kọ alaye soju patako.Ibẹ ni Bolu ti daku.Nkan ti wọn sọ fun wa niyẹn''
O tun sọ pe ko pẹ si igba ti wọn ri pe Bolu ku ni ọrẹ Daddy(ẹni to ni ileewe) gba wa ni imọran lati wa ilẹ lọ sin Bolu si.
''Awọn ni wọn ra aṣọ, awọn ni wọn san owo fun awọn to gbẹ ilẹ.A pada sin oku rẹ si ilẹ Daddy wa ti o w ani toosi''
Ki lo wa mu awuyewuye wa lori iku Bolu
Ọrọ gbọna mii yọ gẹgẹ bi Ridwan ṣe sọ nigba ti ẹgbọn Bolu to wa ni ileẹkọ kan naa de lati ileewe ni irọlẹ.
Ridwan ni ẹgbọn rẹ, Lateef sọ pe olukọ kan(Mr Emma) lo lu Bolu ni kilasi to fi pada wa daku.
''Igba t i ẹgbọn rẹ sọ ọrọ yi fun wa lasiri pada wa tu pe ohun ti wọn sọ fun wa pe Bolu daku kii ṣe ootọ''
Ridwan ni awọn to jẹ ẹgbọn fun oun wa olukọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Mr Emma lọ si ile rẹ lọjọbọ ṣugbọn wọn ko ba ni ile.

Oríṣun àwòrán, elihanschools.com
O ni awọn tun wa lọ lọjọ Ẹti naa ti awọn ko si mọ ibi to gba lọ.
''Daddy wa lawọn ko ni ṣẹjọ lori ọrọ yi ṣugbọn wọn ni ti awọn akọroyin ba wa beere ọrọ nipa iku Bolu awọn yoo ṣalaye fun wọn''
''Nkan ti awa mọlẹbi kan fẹ ni pe ki a mọ Boya iku amuwa lati ọdọ Ọlọrun ni iku Bolu tabi eeyan lo wa nidi rẹ''
Ki ni ileewe Bolu sọ
BBC Yoruba pe nọmba ẹni to nileewe naa Oduwole GA ti awọn mọlẹbi Bolu fi ranṣẹ siwa.
Amọ ẹni to gbe ago naa ṣalaye pe agọ ọlọpaa lawọn wa nitori naa awọn ko ni le da wa lohun lasiko taa pe.
Bakan naa ni BBC pe ọga ọlọpaa(DPO) Ikorodu lori ago to si ni oun ko mọ nipa iṣẹlẹ naa.
Iku ọmọdekunrin yi jẹ eleyi ti a o maa tọ pinpin rẹ lati mọ ohun to ṣẹlẹ wa si eti igbọ yin.
Ṣugbọn bayi, mọlẹbi ti sin Bolu, ileewe ko ti fesi ti a ko si le sọ ni pato ibi ti olukọ ti wọn fẹsun kan pe o lu Bolu to fi daku wa.















