Charly Boy: Nítorí ọ̀rọ̀ tí Charly boy kọ́ nípa bi ọmọ rẹ̀ ṣe jẹ́ ẹni tó n ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin ẹgbẹ́ rẹ̀, Dewy Oputa ti fárígá fún bàbá rẹ̀ pé kó yé fi òun wá ojú rere

Oríṣun àwòrán, Twitter/charly boy
Ọmọbinrin agba olorin, Charly boy, Dewy Oputa ko foju rere wo baba rẹ bayii o fun ohun to kọ soju opo ayelujara nipa rẹ, o si ti fesi fun baba rẹ pe ko fi tirẹ ṣe tirẹ o.
Ni ọjọ Ẹti ni Charly boy ti ọpọ tun mọ si area fada bọ soju opo Instagram rẹ nibi to ti sọ pe ohun sunmọ awọn ọmọ oun o, oun si ni ifẹ wọn, nitorina nigba ti ọmọ oun obinrin jade lati sọ fun oun pe abobinrin bii toun lopọ loun jẹ, iyẹn Lesbian, nṣe loun gbaa tọwọ tẹsẹ o.
- Èyí ni bí wọ́n ṣe pín fásitì LAUTECH láàrín ìpínlẹ̀ Oyo àti Osun
- Wo àwọn èèkàn, ìlúmọ̀ọ́ka olórin tó ṣàbẹ̀wò sí ijọ Celestial Church ti Genesis Global
- A kò tíì lè sọ pé ọmọ Ọba tuntun ni yóò jẹ Ooni lọ́jọ́ iwájú - Elebuibọn
- Saka ń wá ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan nítorí aṣọ kóòtù ọdún 34 sẹ́yìn
- Ọkùnrin tó pe ìyàwó rẹ̀ lájẹ̀ẹ́ tì í mọ́lé fọ́dún mẹ́rin, fún un lóyún nígbà mẹ́ta!
Amọṣa ọmọ rẹ obinrin tọrọ ọhun kan ti lọ fesi fun baba rẹ lori atẹjade to gbe soju opo Instagram rẹ naa.
Dewy ni ṣe ni baba oun fẹ maa fi oun gba irawọ kawọn eeyan lee maa ka ọrs rẹ loju opo ayelujara rẹ.
Esi ti area fada fun naa ni pe ọmọ mi, maa ṣe bayii. O mọ pe mo nifẹ rẹ gidi gan ni.
Inú mi dùn pé mo ní ọmọ obìnrin tó jẹ́ abẹ́yàkan lò pọ̀ 'lesbian' - Charly Boy
Gbajugbaja oludanilaraya, Charly Boy 'Area Fada', ti sọ ni gbangba bi inu rẹ ṣe dun sí pe oun ni ọmọ to jẹ ololufẹ ibalopọ obìnrin si obìnrin ẹgbẹ rẹ.
Ori ayelujara ibaraẹni dọrẹẹ ni Area Fada ti sọ nipa oriṣiriṣi èrò inu rẹ nigba ti ọmọ rẹ abigbẹhin l'obinrin, Dewy Oputa sọ fun pe 'Lesbian' ni oun.
O ni "nigba ti ọmọ mi sọ fun mi pe oun ma n ni ibalopọ obìnrin si obìnrin 'lesbian', oriṣiriṣi nkan lo wa si ọkan mi bi a ṣe jọ n ṣorọ lori foonu.
- Wo àwọn èèkàn, ìlúmọ̀ọ́ka olórin tó ṣàbẹ̀wò sí ijọ Celestial Church ti Genesis Global
- Saka ń wá ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan nítorí aṣọ kóòtù ọdún 34 sẹ́yìn
- Wo orúkọ ẹ̀ṣọ́ Gbajabiamila tó yìnbọn pa fẹ́ńdọ̀ nílùú Abuja, pẹ̀lú ibi tó ti ń ṣiṣẹ́
- CCC Genesis Global: Ǹkan mẹ́wàá tí ẹ ò gbọ́ rí nípa Israel Oladele, Woli ìjọ Genesis Global
" Mo ṣa n ro oriṣiriṣi nkan. Koda, mo da ara mi ni ẹbi. Ọkan mi daru.
Mo tun ro ọrọ ẹ̀sìn pe ṣe ọrun àpáàdì kọ ni ọmọ mi yoo lọ bayii?"
Gẹgẹ bi gbajumọ naa ṣe sọ, o ni oun ti n gbaradi fun oṣu diẹ lati ja fun ẹtọ àwọn to n ni ibalopọ ọkunrin sọkunrin, ati obinrin si obinrin, saaju ki ọmọ oun to o sọ ọrọ naa fun oun.
Lẹyin ọpọlọpọ idaru-dapọ ati ero lorisirisi, Charly Boy sọ pe ko si ohunkohun to le fa ipinya laarin oun ati eyikeyi ninu ọmọ òun.
Yatọ si eyi, o tun kọ ọ sibẹ pe iwa omugọ ni ki òbí ro pe oun kuna ninu ojuṣe oun ti ọmọ ba jẹ iru eeyan bẹ ẹ. Ati pe, gbogbo òbí jẹ àwọn ọmọ wọn ni ifẹ ti ko ni ìdí.
Bo tilẹ jẹ pe Charly Boy pari gbogbo ọrọ rẹ pẹlu "mo nífẹ̀ẹ́ ọmọ mi to jẹ lesbian", o dabi ẹni pe iroyin to fi sita naa ko dun mọ ọmọ rẹ Dewy ninu, nitori esi to kọ si abẹ ọrọ naa lori ayelujara pe baba oun n kọ nkan sori ayelujara nitori awọn ololufẹ rẹ.
















