Lagos-Ibadan: Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ pé kí gbogbo ọkọ̀ agbépo kúrò ní òpòpónà márosẹ̀ Eko si Ibadan- Fasola

ọkọ agbepo

Oríṣun àwòrán, @2020pics

Babatunde Raji Fasola to jẹ minista fun ọrọ iṣẹ ati ile gbigbe ni Naijiria ati gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiodun ni wọn jọ kọwọrin lọ si opopona marosẹ Eko si Ibadan.

Nibi abẹwo ti Babatunde Fasola ṣe yii lo ti paṣẹ pe o to gẹẹ fun awọn ọkọ agbepo ati ọkọ akẹru to n duro si opopona marosẹ yii ni eyi to n fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.

Ijọba Naijiria ni bi wọn ṣe n da awọn ohun eelo epo rọbi si titi yii n ṣakoba to pọ nibẹ ni.

Lọjọ Abamẹta ni Fasola paṣẹ pe ki wọn kuro lopopona yii nibi ipade itagbangba to waye nilu Ogere ti o jẹ aarin gbungbunmarosẹ Eko si Ibadan.

Fasola ṣalaye pe sisọ opopona di ibudo igbe ọkọ si yii ti ṣakoba to pọ fun eto ọrọ aje Naijiria lapapọ.

Gomina Dapọ Abiodun so pe lọdun 1974 ni wọn bẹrẹ opopona marosẹ Eko si Ibadan naa nigba ti wọn si pari rẹ ni ọdun 1978.

O ni pataki kikọ marosẹ naa ni lati mu idagbasoke ba okowo ariwa si guusu Naijiria lapapọ.

Fasola wa paṣẹ fun awọn ẹṣọ oju popo ti a mọ si Federal Road Safety Corps lati rii pe wọn mu aṣẹ ijọba ṣẹ.

O ni ajọ FRSC gbodọ rii pe awọn awakọ to n kọja loju opopona yii mu aṣẹ ijọba naa ṣẹ ni kiakia.

O ni ihuwasi awọn awakọ agbepo ati ọkọ akeru lopopona yii ko kọja pe aitete pari atunṣe si ọna marosẹ naa.

O ni kete ti iṣẹ akanṣẹ to n lọwọ nibẹ ba ti pari ni ohun gbogbo ti wa si ipari nibẹ.

Àkọlé fídíò, AbdulQudus Bello ṣàlàyé bí òun ṣe dí aláàbọ̀ ara nítorí pọpọ́ọ̀fù àti ìbínú jàǹdùkù àdúgbò

Minista fun ọrọ iṣẹ tun tẹpẹlẹ mo pe ẹnikẹni to ba fẹ ṣiṣẹ awakọ gbọdọ ronu ibi ti yoo maa gbe ọkọ rẹ si ko to bẹrẹ.

O ni iṣẹ wiwa ọkọ agbepo ati ọkọ akẹru jẹ iṣẹ to dara ṣugbọn to ga ero.

Ninu eyi ti o gbọdọ ronu ibi ti oo maa gbe awọn ọkọ naa si.

O ni o yẹ ki awọn awakọ yii mọ riri ijọab to n pese iranwlọwọ fun wọn ni kii ṣe pe ki wọn tun maa fi iṣẹ oojọ ti wọn ni awọn ara ilu miran lara nipa fifa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà

Fasọla ni o bani ninujẹ pe owo ko si nita lasiko yii, ati pe ninu iwọnba ti ijọba n gbiyanju lati satunṣe si naa ni awọn kọlọransi kan tun n bajẹ.

O ni dida epo disu si oju popo yii maa ba iṣẹ akanṣe to n lọ lọwọ naa jẹ ni.

Bakan naa lo parọwa fun gbogbo awọn to kopa nibi ipade itagbangba naa pe ki wọn dẹkun ṣiṣe eyi lati ẹyin ipade naa lọ.

Àkọlé fídíò, Bose Okeowo: Àárẹ̀ kékeré ló sọ mi dí aláàbọ̀ ara yìí ṣùgbọ́n...

Fasola so pe gbigbe ọkọ agbepo rẹ soju titi to jẹ maroṣẹ tako ofin irinna ajọ FRSC Naijiria.

O ni fun idi eyi, ẹnikẹni ko gbọdọ fi ọkọ rẹ silẹ lori popo mọ lati igba naa lọ.

O ni ki awọn ti ọrọ kan fi ọwọ so ọwọ pọ pẹlu awọn Ọba alade, ijọba ipinlẹ Ogun, ati awọn agbofinro lori iṣoro yii ki awọn agbaṣẹṣe le tete pari iṣẹ akanṣe atunṣe opopona naa to n lọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé